Ohun Méje Ti Bíbélì So Nípa ÀníyànÀpẹrẹ

7 Things The Bible Says About Anxiety

Ọjọ́ 7 nínú 7

Gbigbé ní àsìkò lè le. O ṣòro láti wulẹ̀ gbádùn òní, ohun tí a ní lòní, àti ènì ti a máa ní ìrírí rè pèlú lòní. A ní ọ̀pọ̀ àwon ibéèrè fún àfiyèsí wa, ibéèrè lori síṣètò àkókò wa, àti àwon ibéèrè lori agbára opolo wa. Nígbà mìíràn à nímọ̀lára bí òní kò seése láti kojú mó nítorí óla ti jìjàkadì lori wa tẹ́lẹ̀.

Jésù so nǹkan kan fún wa tegbòtigàgá—Ó so fún wa kì a ma dààmú nípa óla. Ó so fún wa ní Mátíù 6:34 pé Óun yóò sàtimúra wa sile láti yanjú pèlú wàhálà tòní nìkan—kì í se tóla, ọ̀sẹ̀ tón bo, àbi osù tón bo.

Láwọn o̩jó̩ mìíràn èyí le jú àwon mìíràn lo. O rọrùn fún mi kì í ma dààmú nípa óla nígbà tí“óla” o ye kọ jé ìsinmi Sátidé kúrò nibise. Àmó o di túbò le si gan-an nígbà tí “óla” ní o̩jó̩ to jé pé mo ní ìpàdé ńlá kan (tàbí ládèéhùn pèlú dókítà eleyín!).

 

Bí a ba dààmú nípa óla àti ohun yòó wù ti a ró pé ó lè mú wa, à ń gbígbìyànjú láti darí ohun to jé pé pàápàá mbe labé isàkóso , àtipe kí ì se tàwa. Bí à ba jẹ́ olóòótọ́ pèlú aràwa, à kò ní èrò gan-an nípa ohun to le ṣẹlẹ̀ lóla. À kò tilẹ̀ mọ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tóba yá lòní! Àmọ́ ṣá o, à lè mò ènì kan tón darí òní. Àti óla. Àti títí ayé.

Wá ìgbà die lòní láti sinmi nínú òkodoro òtítọ́ yen. Jé ìgbádùn àsìkò yìí, lòní, ní mímò pé Olórun ní òní àti óla ní owó Rè. Jé kí àlàáfíà mú “òní” nítumọ̀.

Casey Case
YouVersion Support Leader

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

7 Things The Bible Says About Anxiety

Gbogbo ojó lo ṣeé ṣe fún láti gbé oríṣiríṣi ìpèníjà titun sínú ayé wá. Àmó o dọ́gba pẹ̀lú bí pé ojó titun kòòkan màa bùn wá pèlú àwon àǹfààní to yá gágá. Ní ojó-méje onífọkànsìn èyí, ọmọ-ẹgbẹ́ agbo òṣìṣẹ́ ni YouVersion ràn è lówó láti sílò òtítọ́ láti ínú òrò Olórun si ohun yòó wù ti ọ́ ń dojúko lòní. ífọkànsìn ojó kòòkan kún un ni Esẹ Bíbélì alàwòrán láti ràn è lówó láti ba o pín ohun ti Olórun n sọ̀rọ̀ sí o.

More

A se kikò àti ipèsè ètò yìí láti ọwọ àjọṣepọ̀ ní YouVersion. Sabẹ̀wò youversion.com fun àlàyé síwájú sí.