Ẹ̀jẹ́ NáàÀpẹrẹ

The Vow

Ọjọ́ 6 nínú 6

Ẹ̀jẹ́ Ádùrá

Jason àti Kristyjẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí wọ́n ti fẹ́ ara wọn láti bíi ọdún mẹ́wàá séyìn. Wọ́n sábà máa ń rin pẹ̀lú ajá wọn àwọn ọmọ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọn bí, rínrìn lọ sí ẹ̀bá odò, orí òkè ńlá, tàbí lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹbí.

Kristy:

"Ẹ̀mí Mímọ́ a pè Ẹ́ wa sínú ìgbéyàwó yìí. A nílò Rẹ nínú ìgbéyàwó yìí. A pè Ọ́ wá sínú ayẹyẹ ìgbéyàwó wa, sínú ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì ẹ̀yìn ìgbéyàwó wa, àti ayé wa nígbà tí a bá pàdà sí ilé." A tí ṣètò gbogbo nńkan fún ọjọ ìgbéyàwó wa. Nígbà náà ní ọkọ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣe ohun tí n kò lérò tẹ́lẹ̀. O gbàdúrà lóhùn kẹ́lẹ́ níbi pẹpẹ. N kò mọ bí ádùrá yìí ti máa ṣe lòdì si àkókò àti ipò láti ní ipa lórí òmìnira àti ìbùkún wa jù bí a n tí retí. Ní irú àwọn àkókò yìí, nígbà tí o bá ṣàwarí àgbàrá ádùrá, ní ìwọ yóò ní ìmísí láti kojú àwọn ohun tó ṣe kókó ni ayéè rẹ pẹ̀lú ìdúpẹ́, gbogbo rẹ̀ ní ìtẹríba sí Ọlọ́run.

Bí mo ṣe ń tẹ̀síwájú nínú àdúrà, ni mò ń wòye wípé Ọlọ́run kìí sábà dárí ayé wa sí ipasẹ̀ àwọn àdúrà tí a gbà. Àmọ́ ṣá, bí o ti ń gbàdúrà síi, ni ìwọ yóò máa ní ìdánilójú wípé Ó ńṣe ohun gbogbo láti yọrí sí rere fún ọ, nípasẹ̀ gbogbo ìṣísẹ̀ Rẹ̀ nínú ayé rẹ. Ṣíṣe ìpinnu láti gbàdúrà—ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tàbí ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀—kò d'ífá fún ìrọ̀rùn tàbí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìgbéyàwó yín, àmọ́ yóò ṣeé ní òṣùṣù ọwọ̀. Lẹ́yìn bíi ọdún mẹ́wàá, àdúrà wa a máa lọ báyìí, “Ọlọ́run, kiní isẹ́-àkànṣe Yín fún ìgbéyàwó wa?”

Jason:

Bí Kristy ti sọ ṣáájú, ní àti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti mú àdúrà máa lọ lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ nínú ìgbéyàwó wa. Àmọ́ púpọ̀ nínú àdúrà mi ló kún fún atótónu sí Ọlọ́run. “Ọlọ́run ò, ó kù díẹ̀ kí Kristy pin mí l'ẹ́mìí lónìí,” tàbí, “Ní ṣeni mo kàn ń kùn kiri lónìí. Ǹjẹ́ o lè ràn mí lọ́wọ́?” Tàbí, “Ọ̀dọ́mọkùnrin wa tún ti dé pẹ̀lú ikọ́-ife rẹ̀, ilè yìí ń fẹ́ àtúnṣe, ọkò akẹ́rù wa nílò mékaniki, àti wípé owó fẹ́ sáfẹ́rẹ́ báyìí, Ọlọ́run. Ǹjẹ́ Ẹ mọ àwọn ǹkan wọ̀nyí?” Má ṣì mí gbọ́ o, mo ma ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ fún onírúurú ǹkan, àmọ́ ìdúpẹ́ mi a máa kún fún àròyé. “Olórun, kíni yìí, iṣẹ́ yẹn, àti ìbásépò yí ń ṣiṣẹ́ dáadáa—Ẹ ṣeun fún èyí.” Ǹjẹ́ o tilẹ̀ mọ ǹkan tí a mú wá sí òye mi láìpẹ́ yìí? Ádùrá kìí ṣe nípa pípe àkíyèsí Ọlọ́run sí ayé rẹ, bí kò ṣe nípa mímú ayé tìrẹ wá sí àkíyèsí nípa ìwàláàyè Rẹ̀. Torí náà, àdúrà mi ní báyìí dá lórí mímú àkíyèsí nípa Ọlọ́run dé bá ìgbéyàwó, ẹbí, iṣẹ́, àti àwọn ǹkan mìíràn nínú ayé mi. Mo sì ma ń sọfún Ọlọ́run nípa bí ayé mi ti ń lọ, nítorí a ṣì súnmọ ara wa síbẹ̀ àti wípé mo ma ń fi bí ayé mi ti ń lọ hàn Án lóòrè-kóòrè. Àmó nígbà tí mo bá gbàdúrà lẹ́nu ijọ́ mẹ́ta yìí, mo ma ń gba òtítọ́, ìwáláàyè, àti ìfẹ́ Rẹ̀ láàyè láti kọ sí ayé mi nípa irúfẹ́ Aṣẹ̀dá tí ó jẹ́. Lọ́nà wo? Nípa títẹ́tí sílẹ̀. Nígbà míràn tí o bá gbàdúrà, fi àkókò sílẹ̀ láti fetí sílẹ̀, ìyẹn pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo atótónu rẹ. Kí o sì lo onírúurú ọ̀rọ̀ láti bu ọlá fún Un, ju gbogbo ìfisùn tí o ma ńṣe lọ.

Ádùrá: Tí o bá tí ṣègbéyàwó, gbàdúrà pèlú ọkọ tàbí aya rẹ lónìí pẹ̀lú ohùn tí etí ń gbọ́ kí ẹ sì ṣe ìpinnu ìgbà tí è máa tún parapọ̀ gbàdúrà. Tí o kò bá tíì ségbéyàwó, àkókò yí ló sàn jù láti mú àdúrà ní ọ̀kúnkúndùn.

Kà àwọn ìrísí tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run nínú nípa ìgbéyàwó, ìbálòpò, ìbáraẹníjáde, àti ìgbà ọ̀dọ́.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

The Vow

Nínú Ètò Bíbélì Life.Church yí, àwọn l'ọkọ l'áya (tọkọtaya) mẹ́fà kọ nípa májẹ̀mú ìgbéyàwó tí wọn kò ní àǹfààní láti kà níwájú pẹpẹ. Àwọn májẹ̀mú ìpalémọ, oun-tó-ṣe-pàtàkì, ìlépa, àjọṣepọ̀, àìlábàwón, àdúrà ni májẹ̀mú tí ó máa ń mú ìgbéyàwó lọ létòletò kọjá àkókò adùn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Bóyá o ti gbéyàwó tàbí o kò ì tí gbéyàwó, àkókò ti tó láti dá májẹ̀mú

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/