Ẹ̀jẹ́ NáàÀpẹrẹ
Májẹ̀mú Ìpalémọ
Fún ọjọ́ mẹ́fà tó ń bọ̀, o máa gbọ́ látẹnu tọkọtaya mẹ́fà tí wọ́n dá májẹ̀mú ìgbéyàwó—ṣùgbọ́n kìí ṣe irú májẹ̀mú tí ó wọ́pọ̀. Àwọn májẹ̀mú ìpalémọ, oun-tó-ṣe-pàtàkì, ìlépa, àjọṣepọ̀, àìlábàwón, àdúrà ni májẹ̀mú tí ó máa ń mú ìgbéyàwó lọ létòletò kọjá àkókò adùn ayẹyẹ ìgbéyàwó.
TyleràtiBeth ò palẹ̀ mọ láti pàdé láti ipa ẹsẹ̀ ọ̀rọ̀ títẹ̀ lórí ẹ̀rọ, ṣùgbọ́n wọ́n ti palemọ fún ìgbéyàwó. Nígbàtí wọ́n gbèyín ríra lójú kojú, ọ̀rọ̀ tó kù di ìtàn!
Beth:
Nígbàtí ọkàn méjì bá di ọkan, oun tí ó rẹwà ni—ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo rẹ̀ ló rẹwà. Àjọṣepọ̀ tíó ni àlàáfíà pè fún ìsòdodo, pàápàá àwọn bí àdìmó ẹrù. Àwọn àdìmó tèmi fi ara jọ ogbé ọkàn láti ìgbéyàwó tẹ́lẹ̀. Ìgbẹ́kẹ̀lé mi fi orí sàn lè bẹẹni ìpayà mi wá ga sókè bí fèrè tí a fọn. Síbè, nínú Isaiah 43:19, Ọlọ́run sọ fún àwọn ènìyàn Rẹ pé kí wọ́n má ṣe dúró lórí oun àtijó ṣùgbọ́n kí wọn kíyèsí pé Òun ṣe oun titun. Mo fura pé Ọlọ́run ni oun ọtun nípa mó fún èmi náà. Nítorí ìdí èyí, èmi na ṣe ìpinnu láti mọ̀ọ́mọ̀ palẹ̀ mọ́.
Mo gbàdúrà. Mo ńka Bíbélì déédéé. Mo n gbọ́ ọ̀rọ̀ sí àwọn ọ̀rẹ́ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu. Mo ba a gbani níyànjú sọ̀rọ̀. Mo kọ́ ẹ̀kọ́ nínú ìwé nípa ìwòsàn. Mo sì dúró nínú sùúrù de àkókò Ọlọ́run.
Nínú gbogbo ìlàkọjá yìí, Ọlọ́run lo àwọn ìrírí mi tí kò dára àti ìwòsàn mi láti tún mi mọ. Lẹ́yìn náà, nígbàtí ọkàn àti ti Tyler pàdé, méjèèjì ṣe rẹ́gí. Bí Ọlọ́run ṣe sẹ́yì dùn mọ́mi. Nísinsìnyí, tí ẹ̀rù àtijọ́ bá fẹ́ yọ wọlé, moní ifọkanbalẹ láti sọ nípa rẹ̀ mo sì ní agbára láti kọjú ìjà sí wọn.
Tyler:
Mo tíń gbàdúrà fún ìyàwó mi láti ìgbàtí mo ti wà ní àgùnbánirọ. Níwọ̀n ọdún dí ẹ sẹ́yìn, mo ní ìmò lára pé Ọlọ́run fún mi ni àwọn ọ̀rọ̀ gbógì làti tẹjú mọ: “ìfọkànse,” “sùúrù,” àti “itẹpẹlẹmọ.”
Nígbàtí mo pàdé Beth, mo mọ̀ ni ẹsẹ̀ kaná pè òun ni ẹni náà tí mo ti ń gbàdúrà fún. Kò fi ohunkóhun pamọ́ tàbí oun tí oun bá ja ìjàkadì bò nígbà kan èyí sì ràn mí lọ́wọ́ láti má fi ohunkóhun tí ó jẹ́ ọgbé fún mi láti ọjọ́ pípé pamọ. A má rán ara wa létí òtítọ́ nínú Psalm 147:3 wípé Ọlọ́run A ma wo ọkàn tó bà jẹ́ sàn. Bi a ti ń fẹ́ ara wa, bẹ ní a ngbé ìgbé ayé tó dúró lórí àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta tí Ọlọ́run fún mi. A fẹ́ràn ara wa pẹ̀lú ìfọkànse, sùúrù, àti, itẹpẹlẹmọ.
Oun àgbàyanu ni làti kà bí Ọlọ́run Ṣe pale wa mọ fún ìgbéyàwó àti pàápàá fún ara wa. Ní òtító, ọwọ mi tẹ ọmọbìnrin tí mo gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n mo ń tẹ síwájú lati máa gbàdúrà nítorí ìpalémọ ò pin síwájú pẹpẹ ìgbéyàwó. Mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tu bò má a pale wa mọ kí Ó sì tún wa se fun àwọn oun ọtun tí Ó nṣe.
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú Ètò Bíbélì Life.Church yí, àwọn l'ọkọ l'áya (tọkọtaya) mẹ́fà kọ nípa májẹ̀mú ìgbéyàwó tí wọn kò ní àǹfààní láti kà níwájú pẹpẹ. Àwọn májẹ̀mú ìpalémọ, oun-tó-ṣe-pàtàkì, ìlépa, àjọṣepọ̀, àìlábàwón, àdúrà ni májẹ̀mú tí ó máa ń mú ìgbéyàwó lọ létòletò kọjá àkókò adùn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Bóyá o ti gbéyàwó tàbí o kò ì tí gbéyàwó, àkókò ti tó láti dá májẹ̀mú
More