Ẹ̀jẹ́ NáàÀpẹrẹ

The Vow

Ọjọ́ 4 nínú 6

Ẹ̀jẹ́ Àjọṣepọ

Ìyàwó ọdún mẹ́tàdínlógún, Michael àti Shelley ṣiṣẹ papọ, ṣeré papọ, jẹun papọ, nífẹ papọ, àti ṣe òbí àwọn ọmọbìnrin mẹta papọ. Wọn wo igbeyawo bi ajọṣepọ ti “ara kan”. Ṣugbọn kii ṣe nigbagbogbo lorí bé.

Shelley:

Ni kutukutu igbeyawo wa, mo bẹru akoko bọọlu. Michael yoo fẹ lati gbadun ọjọ bọọlu nigba ti emi rii Satidee bi ọjọ "faaji olufe". Lẹhin ọpọlọpọ awọn akoko bọọlu nnu ibanujẹ, mo pinnu lati gbadura. Mo kan fẹ ki ọkọ mi ṣe awọn nkan ti mo fẹ ṣe (imotaraeninikan, mo mọ). Ọlọrun ṣe iranlọwọ fun mi pẹlu érò bii eyi, “Ṣe o le nifẹ ohun ti ó nfẹ bi?” Bọọlu afẹsẹgba Satidee di ohun “wa”. Sé amoro ohun to sele leyin naa? Michael bẹrẹ sii da ere nàá duro lati ranmilọwọ pẹlu awọn iṣẹ akanṣe mi. Ọlọrun ranmilọwọ lati rí pé nko tọju ọkọ mi bi alabaṣepọ mi. Ni otitọ, emi ko paapa loye oùn tí ajọṣepọ jẹ. Loni, igbeyawo wa lagbara ju bí tí téle lo. A jẹ ara kan - okun ìkó mẹta ti ko lé rọọrun ja. Ati pe eyi jé be nitori a ti kọ bí atí n nifẹ ara wa nipa fífẹ oùn enikeji nfẹ.

Michael:

Emi ati Shelley ti jẹ alabaṣiṣẹpọ fun igba diẹ, nitorinaa o rọrun lati mu u ṣíre. Nigba miiran mo lero bi emi ni ẹni ti n ṣe gbogbo iṣẹ nigba ti o kan máà pèté lori gbogbo ipa mi. (Mo mọ, Mo mọ.) Atí nigba mo ba to be, mó mò tẹtẹ pe bakan na ni o nna lero nipa mi. Laipẹ yi, Shelley jade kuro ni ilu fun odidi ọsẹ kan, atí eyikeyi awọn akiyesi pe mo n ṣẹda ipa si ló pẹlu rẹ. A kàn gbiyanju lati ṣe irun, dí ounjẹ ọsán, ṣe kọfi, ati fi awọn ọmọ lori ọkọ akero - oun ti a nṣe papọ lojoojumọ - jẹ ohun ti o lagbara. O ti jẹ ọdun metadinlogun, mo sì tun nkékọ pe a ni awọn agbara alailẹgbẹ otooto ninu ajọṣepọ yii. Awọn agbara rẹ ni ibamu pẹlu awọn ailagbara mi, ati tirẹ bakanna. A báramù. Àwa méjèèjì ń di “ara kan.” Kii ṣe pe o mumi dara tan. Ọlọrun nikan ni o ṣe iyẹn. Ṣugbọn, pẹlu Rẹ a jẹ ẹni pipe meji ti a fi ina ifẹkufẹ ati ipọnju yipada wa si nkan titun patapata. Ati pé, gba mi gbọ, ajose wa dara pupọ.

Gbadura: Ọlọrun, ranmilọwọ lati rí igbeyawo gegé bi ajọṣepọ ti ifẹ, meji to di ọkan. Ran mi lọwọ lati ma wo ifẹ ti ara mi tabi woju enikeji mi fun imuse mi, ṣugbọn si Ọ. Ran mi lọwọ lati wá sinu igbeyawo lodindi, ki n díra fun ajọṣepọ.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

The Vow

Nínú Ètò Bíbélì Life.Church yí, àwọn l'ọkọ l'áya (tọkọtaya) mẹ́fà kọ nípa májẹ̀mú ìgbéyàwó tí wọn kò ní àǹfààní láti kà níwájú pẹpẹ. Àwọn májẹ̀mú ìpalémọ, oun-tó-ṣe-pàtàkì, ìlépa, àjọṣepọ̀, àìlábàwón, àdúrà ni májẹ̀mú tí ó máa ń mú ìgbéyàwó lọ létòletò kọjá àkókò adùn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Bóyá o ti gbéyàwó tàbí o kò ì tí gbéyàwó, àkókò ti tó láti dá májẹ̀mú

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/