Ẹ̀jẹ́ NáàÀpẹrẹ

The Vow

Ọjọ́ 5 nínú 6

Májẹ̀mú Ìpara-ẹni-mọ́

Nígbàtí James pàdé Mandy, ó mọ̀ pé òun ni. Mandy … kò fi gbogbo ara mọ̀. Ṣùgbọ́n, ìdọ̀rẹ́ ọdún dí ẹ di ìgbéyàwó tó yani lenu. Lẹ́yìn ọdún kan ìgbéyàwó, wọ́n gbèrò wípé ìpara-ẹni mọ́ jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú they àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe.

Mandy:

Mo dàgbà lá yíká ilẹ̀ ìjọsìn, fún ìdí èyí gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, gbogbo àwon ọ̀rẹ́ mi máa sọ̀rọ̀ nípa pipa ara ẹni mọ́. Òrùka Ìpara-ẹni-m gbòde. Mo ti lérò pé ìpara-ẹni-mọ́ túmọ̀ sí pé ki n ma ṣe fi ara mi fún ọkùnrin. Sí mi, èyí túmọ̀ sí pé kò gbọdọ̀ sí ìfẹnukonu tàbí ohunkóhun míràn títí di àkókò ìgbéyàwó. Mo lérò pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló wòye ìpara-ẹni-mọ́ báyìí. O túmọ̀ sí yí yẹra fún àjọṣepọ̀ kankan pẹ̀lú ara sí ara. Ṣùgbọ́n láti ẹ̀yìn ìgbàyẹn, mo ti gbọn wípé o jù bẹ́ẹ̀ lọ gedegbe. ìpara-ẹni-mó nípa bí ọkàn ṣe rí ni. 

Ìpara-ẹni-mọ́ dà lórí ṣíṣe ju àìmáṣe lo. Nígbàtí èmi àti James fẹ́ ara wa, dípò kí a kàn ma yàgò lati ma ṣe àìdà, a pinu láti ma tẹle Kristi ṣáájú oun gbogbo. Tí ènìyàn bá ń fi ọkàn òtítọ́ wá Ọlọ́run, o má ń ran ni lọ́wọ́ láti wa ní mímọ́. Báyìí ti a ti ṣe ìgbéyàwó, síbẹ̀ a ṣì wà ní mímọ́. Ṣùgbọ́n kò túmọ̀ sí pé à ń sẹ́ ara wa! Mi ò le gbàgbé àkókò kan nígbà tí a ń ṣe ìyàwó-dùn-lọ sìngín. O kún fún oríṣiríṣi ìmọ̀lára, mo rí dájú bí ìgbéyàwó mímọ́ ṣe rí gan. Mo kọjú sí James, mo sì wípé, “Ó ti yé mi báyìí, ju tẹ́lẹ̀ lọ. Yíyàn para-ẹni-mó ní iye lórí púpọ̀.” Kódà, bí o bá ti ṣe àṣìṣe, síbẹ̀ o le è yan láti gbé ní ìwà ìpara-ẹni mó, nítorípé lílé pa Kristi pẹ̀lú gbogbo ọkàn ẹni ni ìpara-ẹni mó. Mò ń fi dá ọ lójú—ó lérè. 

James:

Ni àìláfiwé Mandy, nkò dàgbà àrọwọ́tó ìjọ. Ìpara-ẹni mó jẹ́ ìpèníjà ńlá fún mi. Lásìkò tí mo jẹ́ àgùnbánirọ, mo dàgbà sí ìwòye tí kò dára nípa obìnrin àti pẹ̀lú ìfẹ́kùfẹẹ sí ìran àwọn tí oun bá ara wọn ni ìbálò pọ̀. Lẹ́yìn tí mo jáde ilẹ̀ ẹ̀kọ́ giga, mo fi ayé mi fún Kristi. Ó jẹ́ ìmọ̀ lọ́kàn mi láti fẹ́ ẹnití ó fi lépa Jésù pẹ̀lú gbogbo oun tí ó ní. Mo tún mọ̀ bákan náà pé láti ní irú ọmọbìnrin bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí pé èmi náà gbọdọ̀ lépa Jésù pẹ̀lú ìgbọràn. Fún ìdí èyí, mo yí ètò ìlànà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi ki o má lè rí ju oju ewé ayélujára tí mo nílò fún ìṣe. Bákan náà, mo ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí o má n béèrè bí mo ṣe ń ṣe, lóòrèkóòrè. Olùṣọ́-àgùntàn mi, Craig Groeschel, ṣe àgbékalẹ̀ yi dára dára nígbàtí ó wípé, “Àbọ̀rọ̀ kọjú ìjà si ìdánwò ọjọ́ ọ̀la nígbàtí o le mu kúrò lọ́nà lónìí?” Lẹ́yìn ọdún kìíní nínú ìgbéyàwó, o hàn sí èmi àti Mandy pe májẹ̀mú ìpara-ẹni mọ́ sì jẹ oun tó ṣe pàtàkì lónìí gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà kí á pàdé ara wa. Àti pẹ̀lú bí Mandy ti ṣe sọ, ó níye lórí. 

So fún ẹnìkan: tí o bá ń já ìjàkadì pẹ̀lú pípa ara rẹ mọ́, bóyá o ti gbéyàwó tàbí o kò tíì gbéyàwó, òní ni ọjọ́ pé láti jẹ́ wọ́ fún àwọn ará tí o fẹ́ràn tí o sì tẹrí ba fún. Ìtìjú máa ń dàgbà nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n a ti tú ọ sílẹ̀ nípasẹ̀ Ìmọlẹ ayé!
 

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

The Vow

Nínú Ètò Bíbélì Life.Church yí, àwọn l'ọkọ l'áya (tọkọtaya) mẹ́fà kọ nípa májẹ̀mú ìgbéyàwó tí wọn kò ní àǹfààní láti kà níwájú pẹpẹ. Àwọn májẹ̀mú ìpalémọ, oun-tó-ṣe-pàtàkì, ìlépa, àjọṣepọ̀, àìlábàwón, àdúrà ni májẹ̀mú tí ó máa ń mú ìgbéyàwó lọ létòletò kọjá àkókò adùn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Bóyá o ti gbéyàwó tàbí o kò ì tí gbéyàwó, àkókò ti tó láti dá májẹ̀mú

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/