Ẹ̀jẹ́ NáàÀpẹrẹ

The Vow

Ọjọ́ 2 nínú 6

È̩jẹ́ tó ṣe Pàtàkì Jùlọ

Jonathan àti Michelle ti jẹ́ tọkọ taya fún ọdún mẹ́wàá, èrò wọn sì ni pé àsìkò tí inú àwọn máa ń dùn jù ni ìgbàtì àwọn bá ń ṣe iṣẹ́ ìránńṣẹ́, tí àwọ́n sì ń rẹ́rìnín pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí àwọn jọ jókòó yí tábìlì ká.

Jonathan:

:

"Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn ṣíwájúù mi."

Ó dàbí nkan tí ó rọrùn. Èmi kìí sin ọlọ́run ẹ̀sìn míràn. Dájúdájú, èmi kìí tẹríba fún agbára èké tàbí kíi ń máa tẹ̀lé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn míràn. Mo lè fi dá ọ lójú pé èmi kò ní tàpá sí òfin yẹn. Ṣùgbọ́n kínni èyí níí ṣe pẹ̀lú ìgbéyàwó?

Ṣe sùúrù. Gbìyànjú kí o kàá báyì, "máṣe ohun kan tàbí ẹni kankan ṣíwájú mi." Àwọn nkan tí mo lè kà sí jù Krístì lọ: ìgbéyàwó mi, iṣẹ́ mi, àwọn ọmọ mi, ìlera mi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo nkan tí ó dára. Ìgbà tí wọ́n bá sún Ọlọ́run kúrò ní ipò àkọ́kọ́, ìgbà yí ni wọ́n di ọlọ́run. Òye tí mo ti ní ni pé: ìgbàkígbà tí ó bá dàbí pe wàhálà ayé fẹ̀ pọ̀ jù fún mi, ó máa ń sábà já sí pé mo ti fi nkan míran tàbí ẹlòmíràn ṣíwájú Ọlọ́run ni.

Kí á má fi ohunkóhun ṣíwájú Ọlórun ko rọrùn, sùgbọ́n fún ànfàní wa ni. Nígbà tí a bá fi ohun tó ṣe pàtàkì ṣíwájú - tí a bá fi Ọlọ́run ṣíwájú - tí ìgbéyàwó tẹ̀le, kìí ṣe ìṣọ̀kan nìkan ni yóò wà nínú ìgbéyàwó rẹ, ṣùgbọ́n ìfọ̀kànbalẹ̀, ìtùnú àti ìgboyà nínú Olúwa tí kò ní se fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn.

Michelle:

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ri pé mo ti ṣeèṣì fi nkan míràn ṣíwájú Ọlọ́run tó yẹ kó wà ní ipò àkọ́kọ́, kí Jònátànì sì wà ní ipò kejì nítorí pé n kò fi làákàyè ṣe ètò bí ó ti yẹ. Ìgbà míràn mo tilẹ̀ ti fi àkókò tí mo fi ń ṣe ohun afẹ́ ṣíwájú ohun gbogbo!

Fífi Ọlọ́run ṣíwájú túmọ̀ sí kí á mọ̀ọ́mọ̀ fi àkókò sílẹ̀ fún un, láti ka ọ̀rọ̀ Rẹ̀, kí á sì ṣe àfẹ́rí rẹ̀ ṣíwájú ohun gbogbo. Ohun gbogbo! Èmi nìkan kọ́ ni eléyi máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Nígbà tí n kò bá fi ohun tí ó yẹ ṣíwájú, mo máa ń ṣe aláìní, èyí tó o sì máa ń jẹ́ kíi n ma wo ojú Jònátànì láti bá àìní mi pàdé. Eléyi kò tọ̀nà. Ọlọrun nìkan ni ó lè bá gbogbo àìní mi pàdé. Mo dúpẹ́ wípé òye ń yé mi sí nígbà gbogbo, wípé bí ìdúró mi pẹ̀lú Ọlọ́run bá ṣe fẹsẹ̀ múlẹ̀ sí ni ìgbéyàwó mi náà yó ṣe fẹsẹ múlẹ̀ tó. Fífi Ọlọ́run ṣíwájú nìkan ni ọ̀nà àbáyọ!

Gbàdúrà: Ọlọ́run, kínni ohun tí mo fi ṣe èkínní, èkejì àti ẹ̀kẹta? Nje E fún mi ní agbára láti bá ara mi sọ̀rọ̀ kí n sì ṣe ìpinnu tó yẹ láti lè fi ohun tí ó ṣe pàtàkì ṣíwájú. Amin.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

The Vow

Nínú Ètò Bíbélì Life.Church yí, àwọn l'ọkọ l'áya (tọkọtaya) mẹ́fà kọ nípa májẹ̀mú ìgbéyàwó tí wọn kò ní àǹfààní láti kà níwájú pẹpẹ. Àwọn májẹ̀mú ìpalémọ, oun-tó-ṣe-pàtàkì, ìlépa, àjọṣepọ̀, àìlábàwón, àdúrà ni májẹ̀mú tí ó máa ń mú ìgbéyàwó lọ létòletò kọjá àkókò adùn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Bóyá o ti gbéyàwó tàbí o kò ì tí gbéyàwó, àkókò ti tó láti dá májẹ̀mú

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/