Ẹ̀jẹ́ NáàÀpẹrẹ

The Vow

Ọjọ́ 3 nínú 6

Ileri Ilepa

Ryan ati Ashia jẹ ololufẹ lati Ile-iwe giga. Lẹhin ibaṣepọ ọdun mẹta, wọn papa ṣe igbeyawo ni oṣu marun ṣaaju kikọ eko asaro Bibeli yi nipa ilepa ajọṣepọ!

Ryan:

Ryan:

Ohun akọkọ ti mo ni lati kọ ninu igbeyawo ni pe ilepa ko pari ni pẹpẹ. Nigbagbogbo mo sọ fun ara mi bi mo sé ndagba pe bò pé emi kii yoo jẹ oṣiṣẹ ti ko lo akoko pẹlu ẹbi rẹ. N'ko mọ bi o ti rọrun to lati ṣubu sinu ẹgẹ yẹn. Awọn ọsẹ diẹ si igbeyawo wa, mo ni lati kọ ẹkọ lati ma mu wa si ilé nigbagbogbo, awọn ibanujẹ iṣẹ mi, atokọ lati ṣe, tabi paapaa kọnputa mi. Mo ti bèrẹ si gbadura ni ọna ile fun iranlọwọ Ọlọrun lati farabale ati mòómo yi ọkan pada kuro ni iṣẹ mi si iyawo mi. Atí dá iyawo ati iṣẹ pò-kan ko ṣiṣẹ. O rọrun pupọ lati sọ fun ararẹ pé, “Iyawo mi yoo wa nibi nigbagbogbo. Mo ni lati kobiara siṣẹ diẹ sii nisinyi ki n le gbadun rẹ nigbamii.” Ṣugbọn ohun ti o jẹ iṣura fun o ti o lepa lówó bayi ni ibiti iwọ yoo ba ará ré. Jesu kọ wa ni Matiu 6:21 pe nibiti iṣura rẹ ba wa ni aaye kanna ti ọkan rẹ wa. Ileri Ifojusi jẹ nipa mimọ ibi ti iṣura rẹ wa ati láti maṣe fi wiwa rẹ silẹ.

Ashia:

Fun Ryan ati emi, igbeyawo sokunfa abaṣepọ tó ni iṣiro gbóingbóin lati jẹ ki ọkan wa lepa Ọlọrun, nigbagbogbo. A n pe ara wa nija deede lati sé idagbasoke ifẹ wa ati ifẹ fun Ọlọrun pèlu ọrọ Rẹ. Abajade re nipé ifẹ mi sí Ryan túnbo pọ si. Lése kanna, mo ri pé ọkan rẹ ṣi si itọju ati ifẹ fun mi. Ileri yii lati lepa Ọlọrun, lẹhinna ara wa, ti jẹ ki ibaṣepọ wa dara ati igbeyawo wa túnbo lagbara si.

O gún régé, abi? O dara, ko jú oṣu diẹ lo tí a sé igbeyawo tí a fi mọ pe a wé gán nnu orò yii. Mo rii pé mo n lepa ati fa Ryan mora nipa akitiyan lati te lorun nnu ohun gbógbó funrarami. Lẹhinna, mo yipada, mo bèrẹ si gbiyanju lati tọju ara mi nikan. Isé siwaju séhin yii le lo títí kó si jẹ ipalara, titi emi o fi ranti ileri ipenija wa lati kọkọ lepa Ọlọrun. Ṣe o rii, nigbati mo ba ranpa tèle Ọlọrun, Oun ni ọna ti o ṣẹda ifẹ ninu mi lati sin ati lepa Ryan. Ati wipé nigbati mo gbẹkẹle Ọlọrun ati Ryan, mo rii pe awọn aini mi ti dopin. O jẹ ilepa tó duro légbè ará won. Lati ṣe atunkọ Aposteli Paulu lati Filippi 1:27, emi ati Ryan duro ṣinṣin ninu Ẹmi kan, pẹlu ọkan kan ti n tiraka ni ẹgbẹ ará wa fun igbagbọ ihinrere. Bawo ni gbogbo ilepa yii ṣe n ṣiṣẹ daradara? Nitori Ọlọrun kọkọ rànpa tèle wa.

Gbero Nkan: Ti o ba ti wa ninú igbeyawo, gbero ọjọ ijade kan, ounjẹ ọsan, tabi paapaa ibaraẹnisọrọ kan lati tun sé ilepa. Ti o ko ba ì ti se igbeyawo, sé akọsilè bí o ti fẹ kí ilepa Ọlọrun ati arin ara yin se ri ninu igbeyawo rẹ.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

The Vow

Nínú Ètò Bíbélì Life.Church yí, àwọn l'ọkọ l'áya (tọkọtaya) mẹ́fà kọ nípa májẹ̀mú ìgbéyàwó tí wọn kò ní àǹfààní láti kà níwájú pẹpẹ. Àwọn májẹ̀mú ìpalémọ, oun-tó-ṣe-pàtàkì, ìlépa, àjọṣepọ̀, àìlábàwón, àdúrà ni májẹ̀mú tí ó máa ń mú ìgbéyàwó lọ létòletò kọjá àkókò adùn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Bóyá o ti gbéyàwó tàbí o kò ì tí gbéyàwó, àkókò ti tó láti dá májẹ̀mú

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/