Rírìn Ní Ọ̀nà NáàÀpẹrẹ

Practicing the Way

Ọjọ́ 2 nínú 5

ÀFOJÚSÙN #1: WÀ PẸ̀LÚ JÉSÚ

Kò ya'ni l'ẹ́nu pé Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ nípa pípè wọ́n pé kí wọ́n “wá, ẹ máa tọ̀ mí l'ẹ́yìn”—láti kàn bá òun rìn ní ẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní ojú Ọ̀nà.

Ó ní kí Andrew àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá wo ibi tí ó ti ń gbé. “Nítorí náà, wọ́n wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì dúró lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ náà” (Jòhánù 1:39).

Nínú Lúùkù 10:39, a kà nípa ọmọ ẹ̀yìn kan tí ó ń jẹ́ Màríà, tí ó jókòó l'ẹ́yìn Jésù tí ó ń fi etí sí ohun tí ó ń sọ.

Gẹ́gẹ́ bí Máàkù 3:13 ti wí, Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Àwọn tí ó ń tẹ̀ lé Jésù yìí lè jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún tàbí ọgọ́rọ̀ọ̀rún tí wọ́n lo àkókò pípẹ́ pẹ̀lú Jésù. Nínú àwùjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ó pọ̀ jù lọ yìí, Jésù yan méjìlá (12) fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe "kí wọ́n lè wà pẹ̀lú rẹ̀".

Èyí ni ohun àkọ́kọ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí èèyàn lè ṣe láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù: kí èèyàn wà pẹ̀lú rẹ̀, kí èèyàn máa lo gbogbo àkókò mọ ìwàláàyè rẹ̀ kí a sì máa fi etí sí ohùn rẹ̀. Kí o lè ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú Jésù, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó máa gbé ìgbésí ayé rẹ lé e lórí.

Láti tẹ̀lé Jésù kì í ṣe àgbekàlẹ́ ìgbésẹ̀ mẹ́ta, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìpele. Kì í ṣe ètò kan, bí kò ṣe ohun ìṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

A yíó máa wo bí ìyípadà yìí ṣe ń tẹ̀ sí iwájú nínú ìfọkànsìn wa ní òní yìí àti nínú ọjọ́ méjì tí ó tẹ̀ lé e. Àpilẹ̀kọ yìí ni: Àkọ́kọ́, o wá bá Jésù láti wà pẹ̀lú rẹ̀; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, o bẹ̀rẹ̀ sí í dà bíi rẹ̀; ní ìkẹyìn, ó dà bíi pé o kò lè dáwọ́ dúró o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe irú àwọn nǹkan tí òun ṣe ní ayé.

A rí ayípadà yìí nínú ìtàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́: Wọ́n lo oṣù tàbí bóyá ọ̀pọ̀ ọdún kàn l'ẹ́yìn rẹ̀ yípo Ísírẹ́lì tí wọ́n sì jókòó ní ẹ̀bàá ẹsẹ̀ rẹ̀. Ní díẹ̀díẹ̀ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà, ní ìgbà tí ó sì yá, ó “rán wọn jáde” láti lọ wàásù (Lúùkù 9:2).

Ó ṣeé ṣe kí o ṣẹ̀ṣẹ̀ máa tẹ̀ lé Jésù, kí o sì máa ro'nú pé, Ibo ni mo tiẹ̀ ti lè bẹ̀rẹ̀? Bẹ̀rẹ̀, ní ibí, pẹ̀lú àfojúsùn #1: Wà pèlú Jésù.

Ní ìgbà tí o bá ń ro'nú nípa fífi ara rẹ fún Jésù, kí ni ó máa ń wá sí ọ ní ọkàn? Ṣé ìwọ á fẹ́ dúró fún ìṣẹ́jú díẹ̀ ní àkọ́kọ̀ kan, kí o sì mú èrò inú àti ọkàn rẹ padà sí ọ̀dọ̀ Jésù? Báwo ni o ṣe lè ṣe é?

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Practicing the Way

Irú ènìyàn wo ni ò ń dà? Tí o bá ń fi ojú inú wo ara rẹ ní ìgbà tí o bá wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin, ọgọ́rin tàbí ọgọ́rùn-ún, irú ẹni wo ni o máa ń rí? Ǹjẹ́ ohun tí ò ń rò nínú ọkàn rẹ ń mú kí o ní ìrètí? Àbí ìbẹ̀rù? Nínú ìfọkànsìn yìí, John Mark Comer fihàn wá bí a ṣe lè ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú Ọlọ́run kí a lè túnbọ̀ dà bíi Jésù ní ojoojúmọ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ John Mark Comer Teachings Practicing the Way fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://practicingtheway.org