Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si kuro nibẹ̀ lọ si eti okun: ijọ enia pipọ lati Galili ati Judea wá si tọ̀ ọ lẹhin,
Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá.
O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u.
Nitoriti o mu ọ̀pọ enia larada; tobẹ̃ ti nwọn mbì ara wọn lù u lati fi ọwọ́ kàn a, iye awọn ti o li arùn.
Ati awọn ẹmi aimọ́, nigbàkugba ti nwọn ba ri i, nwọn a wolẹ niwaju rẹ̀, nwọn a kigbe soke, wipe, Iwọ li Ọmọ Ọlọrun.
O si kìlọ fun wọn gidigidi pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn.
O si gùn ori òke lọ, o si npè ẹnikẹni ti o fẹ sọdọ rẹ̀: nwọn si tọ̀ ọ wá.
O si yàn awọn mejila, ki nwọn ki o le mã gbé ọdọ rẹ̀, ati ki o le ma rán wọn lọ lati wasu,
Ati lati li agbara lati wò arunkarun san, ati lati lé awọn ẹmi èṣu jade:
Simoni ẹniti o si sọ apele rẹ̀ ni Peteru;
Ati Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin Jakọbu; o si sọ apele wọn ni Boanerge, eyi ti ijẹ Awọn ọmọ ãrá:
Ati Anderu, ati Filippi, ati Bartolomeu, ati Matiu, ati Tomasi, ati Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Taddeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,
Ati Judasi Iskariotu, ẹniti o si fi i hàn pẹlu: nwọn si wọ̀ ile kan lọ.