MAKU 3:7-19

MAKU 3:7-19 YCE

Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra lọ sí ẹ̀bá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan sì ń tẹ̀lé e. Wọ́n wá láti Galili ati Judia ati Jerusalẹmu; láti Idumea ati apá ìlà oòrùn odò Jọdani ati agbègbè Tire ati ti Sidoni. Ogunlọ́gọ̀ eniyan wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó ń ṣe. Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn tọ́jú ọkọ̀ ojú omi kan sí ìtòsí nítorí àwọn eniyan, kí wọn má baà fún un pa. Nítorí ó wo ọpọlọpọ sàn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn aláìsàn ń ti ara wọn, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án. Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù bá rí i, wọ́n a wolẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n a máa kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.” Kíkìlọ̀ ni ó máa ń kìlọ̀ fún wọn gan-an kí wọn má ṣe fi òun hàn. Lẹ́yìn náà, ó wá gun orí òkè lọ, ó pe àwọn tí ó wù ú sọ́dọ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ. Ó bá yan àwọn mejila, ó pè wọ́n ní aposteli, kí wọn lè wà pẹlu rẹ̀, kí ó lè máa rán wọn lọ waasu, kí wọn lè ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Àwọn mejila tí ó yàn náà nìyí: Simoni, tí ó sọ ní Peteru, ati Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu àbúrò rẹ̀, ó sọ wọ́n ní Boanage, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Àwọn ọmọ ààrá”; ati Anderu, Filipi, Batolomiu, Matiu, ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Tadiu, ati Simoni, ọmọ ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ Kenaani, ati Judasi Iskariotu ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Àwọn fídíò fún MAKU 3:7-19