Rírìn Ní Ọ̀nà NáàÀpẹrẹ
ÀFOJÚSÙN #2: DÀ BÍI RẸ̀
Fún Jésù, ìdí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ni láti wà pẹ̀lú rẹ̀ kí wọ́n lè dà bíi Jésù. A rí èyí nínú àkọsílẹ̀ Jésù: “Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.” (wo Matiu 10:24). Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni àwọn tí ó bá fi orúkọ sílẹ̀ fún ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, àwọn tí ń fi ète ṣe ètò ìgbésí ayé wọn tí wọ́n sì ń d'àgbà nípa ti ẹ̀mí áti nípa idàgbà dé inú.
(Àwọn tí kí í ṣe ọmọ ẹ̀yìn Jésù jẹ́ àwọn tí wọ́n máa ń ṣe ètò ìgbésí ayé wọn yí ká ohunkóhun mìíràn mìíràn.)
Ìgbésẹ̀ ìdàgbàsókè àti ìyípadà ni a ń pè ní “Ìgbédìde nípa ti ẹ̀mí.” Ìgbédìde nípa ti ẹ̀mí kò jẹ kó àwọn Kristẹni nìkan; ó jẹ́ ohun tí ènìyàn máa ń ṣe.
Jíjẹ́ ènìyàn túmọ̀ sí ìyípadà, ní gbogbo ìgbà. Yálà a jẹ́ ẹlẹ́sìn tàbí a kì í ṣe ẹlẹ́sìn, a máa ń d'àgbà, a máa ń yí padà, a máa ń tú ká, a sì máa ń padà wà pa pọ̀. A ò lè ṣe ohunkóhun; ìwà ẹ̀dá ọkàn ènìyàn máa ń yí padà, kì í dúró ṣinṣin. Ìdí rèé tí á fi ń fi àwòrán àwọn ọ̀dọ́langba tí kò bójú mu hàn ní ibi ìgbéyàwó àwọn fọ́tò ìgbéyàwó àti ti ìsìnkú—gbogbo wa ni àyípadà yìí máa ń wú lórí.
Nítorí náà, ìbéèrè náà kì í ṣe, Ṣé ìwọ náà ń gba ìgbédìde?
Ìbéèrè náà ni pé, Ta ni tàbí Kí ni a ń sọ ọ́ dì?
Ìgbédìde nípa tí ẹ̀mí ní Ọ̀nà Jésù ni ilana ti awọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé n pè ní imitatio Christi, tàbí "ìfarawé Kristi." "Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀” (Romu 8:29). Ìyàlẹ́nu gbáà ni ó jẹ́ nítorí pé bí èyí ṣe ń ṣẹlẹ̀, a máa ń di ẹni gidi tí ó wà nínú wa—irú ẹni tí Ọlọ́run ní fún wa ní ọkàn láti di ní ìgbà tí ó ti pinnu láti dá wa kí àkókò tó bẹ̀rẹ̀.
Ìwà òmùgọ̀ tí ó wà nínú àṣà “máa ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú ara rẹ” ni pé gbogbo ènìyàn ni ó máa ń rí bákan náà. Bí ó tí lè jẹ́ wípé, ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe nǹkan kan ní ojú gbogbo ènìyàn. A tún padà sí ẹ̀mí ẹranko tí a ní fún ìpamọ́ ara ẹni àti fún ìgbádùn—ìwọra, àjẹkì, ìṣekúṣe, irọ́ pípa, lílo agbára. Ohun kan náà ní ó ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbà, láti ìran dé ìran.
Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun tí Ọ̀nà Jésù náà sọ ni ẹni tí ó jẹ́ ẹni ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nítorí pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ àbínibí ju ẹni mímọ́ lọ.
O ń di ènìyàn; èyí kò ṣeé yẹ'ra fún.
Ìwọ náà á sì wá ní ibì kan layé.
O ò ṣe di ẹni tí ìfẹ́ Jésù kún inú rẹ̀?
Kí ni ó dé tí o kò fi dà bíi rẹ̀?
Àwọn ànímọ́ Jésù wo ni ó wù ọ́ láti ní? Dúró nísinsìnyí kí o sì gba àdúrà fún Ẹ̀mí Jésù láti dá àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn sílẹ̀ nínú re.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Irú ènìyàn wo ni ò ń dà? Tí o bá ń fi ojú inú wo ara rẹ ní ìgbà tí o bá wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin, ọgọ́rin tàbí ọgọ́rùn-ún, irú ẹni wo ni o máa ń rí? Ǹjẹ́ ohun tí ò ń rò nínú ọkàn rẹ ń mú kí o ní ìrètí? Àbí ìbẹ̀rù? Nínú ìfọkànsìn yìí, John Mark Comer fihàn wá bí a ṣe lè ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú Ọlọ́run kí a lè túnbọ̀ dà bíi Jésù ní ojoojúmọ́.
More