Rírìn Ní Ọ̀nà NáàÀpẹrẹ
ÀFOJÚSÙN #3: ṢE BÍ Ó TI ṢE
“Nitori náà ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo.” (Mátíù 28:19). Báyìí ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Jésù sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ.
Èyí gan-an ni ohun tí ènìyàn lè retí kí olùkọ́ àgbà kan sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ìparí àkókò ẹ̀kọ́ wọn. Bí a ti mọ̀, àfojúsùn olùkọ́ àgbà kìí ṣe láti kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ nìkan, bí kò se láti gbé àwọn ọmọlẹ́yìn bíi tirẹ̀ dìde tí yíò máa ṣe àfimọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà rẹ̀. Títí di òní, ní àkókò ìfàmì-òróró-yàn àwọn olùkọ́ àgbà, a máa ń gbà wọ́n ní ìyànjú láti lọ “gbé àwọn ọmọlẹ́yìn dìde,” láti inú ẹ̀kọ́ tí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ láti ìgbà ìgbésí ayé Jésù.
Ní báyìí, ẹ jẹ́ kí a jọ tan ìmọ́lẹ̀ síi, nítorí ó jẹ́ òye tí púpọ̀ nínú àwọn Kristẹni kò ní: tí ìwọ bá jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lẹ́yìn Jésù, àfojúsùn rẹ ìkẹyìn máa jẹ́ láti d'àgbà àti láti tó'júbọ́ débi wípé o máa di irúfẹ́ ènìyàn tí ó lè sọ̀rọ̀ tí ó sì lè ṣe ohun gbogbo tí Jésù gbé ṣe.
Òye ǹkan wọ̀nyí máa ń tètè yé àwọn ọmọdé; ní ìgbà tí wọ́n bá ka ìtàn aláàánú Samáríà tán, bíi kí òbí wọn ṣe ìrànwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ọkọ̀ rẹ̀ takú ní ọ̀nà ni ó ma ńṣe wọ́n. Nítorí Jésù parí ìtàn aláàánú Samáríà pẹ̀lú, “ẹ lọ ṣe gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú” (Lúùkù 10:37). Tàbí ní ìgbà tí wọ́n bá gbọ́ ìtàn bí Jésù ṣe mú aláìlera lára dá, tí wọ́n wá gbọ́ lẹ́yìn rẹ̀ wípé akẹgbẹ́ wọn ní ilé-ìwé ńṣe òtútù, kíá wọ́n ti dì mọ́ ẹni náà láti gba àdúrà ìwòsàn fún wọn. Àmọ́ ohun kàn máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa bópẹ́-bóyá ní ìgbà tí ìhùwàsí àwùjọ tí ó yí wa ká ma padà pa iná ìtara yìí nínú wa.
Tí ìtara yìí bá jẹ́ Ẹ̀mí náà ńkọ́?
Tí ìtanijí ọkàn yìí bá jẹ́ iṣẹ́ Ẹ̀mí náà tí ń tọ́ wa láti lọ ṣe irúfẹ́ iṣẹ́ tí Jésù gbé ṣe ńkọ́?
Gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ìkọ́ṣẹ́ lẹ́yìn Jésù Jòhánù ti kọ ọ́ sí inú Májẹ̀mú Titun wípé, “Nípa èyí li àwa mọ̀ pé àwa mbẹ ninu rẹ̀, Ẹni tí ó bá wípé on ngbé inu rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bi Jésù ti rìn.” (1 Jòhánù 2:5-6).
Gbogbo èyí ń mú wa lọ sí àfojúsùn #3: Ṣe bí ó ti ṣe. Àfojúsùn ìkẹyìn fún akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni láti tẹ̀ sì iwájú pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀gá rẹ̀. Lẹ́yìn ohun gbogbo, àrin gbùngbùn ìdí tí a fi ṣe àgbékalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ṣẹ́ nìyí.
Ní ìgbà tí o bá ronú nípa ṣíṣe irúfẹ́ ohun tí Jésù ṣe, èwo nínú rẹ̀ ni ó máa ń mì ẹ́ ní ọkàn jù? Kí ni ó fà á? Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ wo ni ìwọ ń gbà kópa nínú ayé yìí fún Ọlọ́run? Ṣé ò ńṣe àṣeyọrí nínú rẹ̀? Ipa wò ni ìwọ ń kó nínú ẹbí Ọlọ́run, èyí tí ńṣe ìjọ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ ń kó ipa yìí bí ó ṣe yẹ?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Irú ènìyàn wo ni ò ń dà? Tí o bá ń fi ojú inú wo ara rẹ ní ìgbà tí o bá wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin, ọgọ́rin tàbí ọgọ́rùn-ún, irú ẹni wo ni o máa ń rí? Ǹjẹ́ ohun tí ò ń rò nínú ọkàn rẹ ń mú kí o ní ìrètí? Àbí ìbẹ̀rù? Nínú ìfọkànsìn yìí, John Mark Comer fihàn wá bí a ṣe lè ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú Ọlọ́run kí a lè túnbọ̀ dà bíi Jésù ní ojoojúmọ́.
More