Rírìn Ní Ọ̀nà NáàÀpẹrẹ
![Practicing the Way](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F42239%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
GBÉ ÀGBÉLÈBÚ RẸ
Ṣé o fẹ́ láti tẹ́lè Jésù bí?
Gbogbo ènìyàn kọ̀ ni ó lè gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Ka Àwọn Ìhìnrere: Egbẹẹgbẹ̀rún èniyàn ni ó tọ Jésù wá, ṣùgbọ́n ìwọ̀nba ọgọ́rùn péréte ni ó di olùkọ́ṣẹ́ ni ọdọ rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó tọ Jésù wá ní tòótọ́ (báwo ni o ṣe lè kọ́ láti jẹ́ ìpè rẹ̀?), ṣùgbọ́n wọn kò múra tán láti fi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Wọn ṣe àwáwí bíi “Ẹ jẹ́ kí ń kọ́kọ́ lọ sin bàbá mi” (Lúùkù 9:59). Èyí jẹ́ ọ̀nà ayé àtijọ́ tí wọ́n fi ń sọ pé, “Jẹ́ kí n dúró kí àwọn òbí mi kú kí n lè gbà ogún ìdílé kí n sì di ọlọ́rọ̀ nínú òmìnira; lẹ́yìn náà èmi yóò wà tẹ̀lé ọ.” Àwáwí míràn? “Èmi yóò tẹ́lè ọ, Olúwa, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ń kọ́kọ́ padà lọ sọ pé o dàbọ̀ fún ìdílé mi” (ẹsẹ 61). Èyí tí ó túmọ̀ sí wípé, fún mi ní àkókò díẹ̀ sí kí ń tó lè fi ara mi jì sì irú ọ̀nà yí.
Ìyẹn ni ohun ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá ṣe: A fà ìdádúró, a ṣe kòṣeku-kòṣẹyẹ, a ṣe àwáwí? Bíi ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ tàbí dídi ẹni tí ó ní ìlera tí ó jí pépé tàbí ṣíṣè ètò ibi ìkó aṣọ sí, a máa ń fi nǹkan jáfara: "Èmi yóò se bẹ́ẹ̀.láì pẹ́.” Ṣùgbọ́n àìpẹ́ lọ́ra láti dé kánkán.
Kí ni Jésù sọ? “Jẹ́ kí àwọn òkú sin ara wọn (ẹsẹ 60).
Ìyẹn dà bíi ẹni pé kò ṣe è gbọ́ létí wá ní òde òní, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀; ó kàn jẹ́ ojú kòńkò ní. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, “Ìwọ lè ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n bí o bá yan ipa ọ̀nà yẹn, yóò mú ọ lọ sínú ikú, kì í ṣe ipa ọ̀nà ìyè.”
Ṣé o ríi, Jésù kò ṣ'agbe, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe àlùmọ̀kọ́rọ́yí tàbí pániláyà. Ìbẹ̀rùbojo kí i ṣe èso ti Ẹmi. Kò fi ipá múni tàbí se ìpolówó ọjà títà fún ẹnìkẹ́ni; ṣe ni ó kàn pè wá. Àti ní ìgbà tí àwọn ènìyàn bá ṣe orí kúnkún tàbí ṣe àwọn àwáwí . . .
Ó jẹ́ kí wọ́n lọ.
Ṣe o lè fi ojú inú wo pé kí a sọ wípé a kò ní jẹ́ ìpè Jésù?
Èmi lè fi ojú inú wó ó.
Ti ó ba pẹ́ ní ayé, ìwọ kò ní ṣàì kọ ìpè tí yóò jẹ́ àbámọ̀ fún ọ ní ọjọ́ iwájú. Èyí ti sẹlẹ̀ sí mi. Mo dúpẹ́ wípé tí mo bá ronú nípa àwọn àǹfààní nlá tí mo ti pàdánù ní ìgbésí ayé mi títí di òní yìí, wọn kò pọ̀. Ṣùgbọ́n títí di òní, ní ìgbà tí wọ́n bá wá sí ọkàn mi, àwọn ìpinnu mi bà mí ní inú jẹ́.
O ní ìpè kan ní iwájú rẹ láti di olùkọ́ṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ Jésù.
Kí ni ìwọ yóò sọ?
Àwọn ìkésíni wo ni o rí tí Jésù ṣe sí ọkàn rẹ àti ìgbésí ayé rẹ? Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Jésù ti rú ọkàn rẹ sí ohun kan bí? Njẹ̀ ó ti tẹ̀lé ìpàṣẹ Rẹ̀? Kí ni ó lè ṣe ní òní yìí láti sọ bẹ́ẹ̀ ni si àwọn ìkésiní Jésù?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
![Practicing the Way](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F42239%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Irú ènìyàn wo ni ò ń dà? Tí o bá ń fi ojú inú wo ara rẹ ní ìgbà tí o bá wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin, ọgọ́rin tàbí ọgọ́rùn-ún, irú ẹni wo ni o máa ń rí? Ǹjẹ́ ohun tí ò ń rò nínú ọkàn rẹ ń mú kí o ní ìrètí? Àbí ìbẹ̀rù? Nínú ìfọkànsìn yìí, John Mark Comer fihàn wá bí a ṣe lè ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú Ọlọ́run kí a lè túnbọ̀ dà bíi Jésù ní ojoojúmọ́.
More