Rírìn Ní Ọ̀nà NáàÀpẹrẹ
Ọ̀NÀ ÌGBÉSÍ AYÉ
Orúkọ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù (tàbí bí mo ṣe ń pè wọ́n, àwọn ọmọ ìkọ́ṣẹ́) ni Ọ̀nà náà tàbí Àwọn ọmọlẹ́yìn Ọ̀nà Náà (Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 9:2; 19:23; 24:14).
Ọ̀nà Jésù kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀kọ́ ìsìn (àwọn èrò tí a gbà gbọ́ nínú ọkàn wa). Òhunni ṣùgbọ́n ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Kì í ṣe ìwà rere nìkan ni ó sì ń ṣe é (ìwé àwọn ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe àti ohun tí a kò gbọ́dọ̀ ṣe, tí a bá tẹ̀lé wọn tàbí tí a kò bá tẹ̀lé wọn). Òhun ni ṣùgbọ́n ó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó jẹ́ ohun tí a pè é gan gan—ọ̀nà ìgbésí ayé.
Ọ̀nà ìgbésí ayé- tí Jésù fún ra rẹ̀ gbé kalẹ̀ yìí kọjá ohunkóhun mìíràn tí ó wà nínú ayé yìí. Ó lè ṣí ọ payá fún wíwà ní iwájú Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ ní ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kàn ń rò ní ọkàn. Àmọ́, ó gbà pé kí o tẹ̀lé ọ̀nà tí Jésù fún ra rẹ̀ fi hàn ọ́.
Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ bá ẹnu-ọ̀na híhá wọlé; gbòòrò li ẹnu-ọ̀na náà, àti oníbú li ojú [ọ̀na] náà tí ó lọ sí ibi ìparun; òpọlọpọ li àwọn ẹni tí mba ibẹ̀ wọlé. Nítorí pé híhá ni ẹnu-ọ̀na náà, àti tóóró li [oju-ọ̀na] náà, tí ó lọ sí ibi ìye, díẹ̀ li àwọn ẹni tí o n rìn í.” (Matiu 7:13-14).
Ọ̀nà tí ó "gbòòrò" jù lọ ni ti àṣà ìbílẹ̀ àwọn tí ó pọ̀ jù lọ, èyí tí ó rọrùn gan-an ni kò ní láárí: “Máa tẹ̀lé àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ẹ́.” Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ni ó ń gbé ní ọ̀nà yìí, àmọ́ kì í jẹ́ kí wọ́n rí ìyè, kàkà bẹ́ẹ̀, ó sábà máa ń yọrí sí ìparun.
Ọ̀nà Jésù jẹ́ "ọ̀nà tí ó “tóóró,” tí ó túmọ̀ sí pé, ó jẹ́ ọ̀nà tí ó ṣe pàtó láti gbé ìgbé ayé . Tí o bá sì tẹ̀lé e, yóò ṣe amọ̀nà rẹ sí ìyè, nínú ayé yìí àti nínú ayé tí ń bọ̀.
Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ìyè yìí. "Èmi wá kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní i ní ọ̀pọ̀ yanturu," ni ó wí (Jòhánù 10:10). Ìyè tí Jésù ń tọ́ka sí yìí ni ó tún pè ní "ìyè àìnípẹ̀kun," èyí tí kò ṣe àpèjúwe ìyè nìkan bí kò ṣe irú ìwàláàyè tí ó jẹ́
Ó dà bíi pé àwọn ènìyàn díẹ̀ ni ó máa ń dáhùn sí ìkésíni Jésù. Ṣùgbọ́n o lè di ọ̀kan lára àwọn aláyọ̀ díẹ̀- tí ó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.
Ìdí ni pé gbogbo ènìyàn ni ó ní àǹfààní láti ní ìyè àìnípẹ̀kun
Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ tẹ̀lé Jésù gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà ìgbésí ayé, báwo ni èyí ṣe lè bẹ̀rẹ̀ síi yí ìgbésí ayé rẹ padà? Àwọn ìwà wo ni ó yẹ kí o yí padà? Fi àkókò díẹ̀ sílẹ̀ nísinsin yìí láti dúró, kí o mí, kí o sì ní ìbátan pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn rẹ fún Jésù àti ìyípadà. Jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn yẹn mú kí o ṣe àyípadà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Irú ènìyàn wo ni ò ń dà? Tí o bá ń fi ojú inú wo ara rẹ ní ìgbà tí o bá wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin, ọgọ́rin tàbí ọgọ́rùn-ún, irú ẹni wo ni o máa ń rí? Ǹjẹ́ ohun tí ò ń rò nínú ọkàn rẹ ń mú kí o ní ìrètí? Àbí ìbẹ̀rù? Nínú ìfọkànsìn yìí, John Mark Comer fihàn wá bí a ṣe lè ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú Ọlọ́run kí a lè túnbọ̀ dà bíi Jésù ní ojoojúmọ́.
More