Jí Jókòó Níbi Ìdákẹ́ Rọ́rọ́: Ọjọ́ 7 Lórí Dí Dúró Sínú Ìlérí Ọlọ́runÀpẹrẹ

Sitting in the Still: 7 Days to Waiting Inside of God’s Promise

Ọjọ́ 7 nínú 7

ỌJỌ́ 7

JÍ JÓKÒÓ NÍ ÌDÁKẸ́ RỌ́RỌ́: ÀṢẸ LÁTI WÁ Ọ̀NÀ ÀBÁJÁDE

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ nígbàtí “ibi ìdákẹ́ rọ́rọ́” kò ní àlàáfíà? Kíni yíò ṣẹlẹ̀ nígbàtí o bá há sí ibití kò ní ìdẹ́ra? Yálà ìgbéyàwó tí kò dára, iṣẹ́ tí kò múnú dùn, ìbádọ̀rẹ́ tí à kò fẹ́, ìdààmú lórí àwọn ọmọ, tàbí ẹbí tinú ìjọ tí ó tí dàrú. Àwọn wọ̀nyí ni ìdààmú tí à ún là kọjá àti èyítí Ọlọ́run fẹ́ kí á dúró nínú rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló ń la ìdánwò oríṣiríṣi kọjá, a sì fẹ́ wá ọ̀nà àti sá àsálà kúrò nínú ẹ̀ ní kíá. Amo o, Ọlọ́run kò gbà wá láàyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ní pàápàá nígbà ìdánwò a kò ní àṣẹ láti wá ọ̀nà àbájáde. A nílò láti gbàdúrà ká sì dúró de Ọlọ́run láti dáhùn pẹ̀lú ìtọ́ni. Nígbàtí Ọlọ́run kò bá dáhùn, èyí kìí ṣe àṣẹ fún wa láti wá ọ̀nà nà àbájáde.

Gbogbo wa ni a korira ká wà ní àìní ìdẹ́ra bí a ti ń rò bákannáà pé kí Ọlọ́run yọ wá kúrò ní kété tí ìnira bá yọjú. A má ń fẹ́ rò pé Ọlọ́run kò sí níbi àwọn ibi ìnira yẹn, ṣùgbọ́n ibi tí ódára jùlọ nìyí láti pàdé Rẹ̀. Mo ti ní àkókò tí mo súnmọ́ Ọlọ́run jùlọ nígbàtí mo há mọ́ ibi ìdákẹ́ rọ́rọ́ tí kò dẹra, tí mò ń wá Ọlọ́run tọkàntọkàn. Lóòótọ́, a lè gé ìdánwò kúrú nípa fífi ìjọ sílẹ̀, ìbáṣepọ̀, tàbí iṣẹ́, ṣùgbọ́n tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a leè pàdánù ohun èlò tí a nílò fún èrèdí wa tó wà níwájú.

Tí Ọlọ́run bá ti sọ̀rọ̀ ìlérí kan sínú ayé rẹ, rántí pé àwọn ohun èlò kan wà tí o nílò láti fi mú ìlérí náà ṣe. Tí o bá ní sùúrù nínú ìdánwò àti ìdààmú, oó làá kọjá sí òdì kejì lódindi. Gba Ọlọ́run láàyè láti fi sínú rẹ àwọn ohun èlò tí o nílò láti mú àwọn ìlérí rẹ ṣẹ. Wà níbi ìparọ́rọ́ títí Ọlọ́run Yóò fi tọ́ ọ̀nà rẹ jáde. Tí o bá wà ní ibi tí kò ní ìdẹ́ra nígbàtí ò ún dúró de ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, tẹ̀síwájú láti máa gbàdúrà kí o sì ṣe olóòtítọ́ sí Ọlọ́run, ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Yóò mú ọ làájá ní àkókò Rẹ̀.

Bí a ti ń mú ẹ̀kọ́ yí wá sí òpin, ohun yówù tó lẹ̀ jẹ́ “ibi ìdákẹ́ rọ́rọ́” tí Ọlọ́run fi ọ́ sí, jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti jókòó àti láti dúró de ohùn Rẹ̀. Máṣe ṣe àníyàn, máṣe kó sí ọwọ́ ohùn tí kìí ṣe ti Rẹ̀, má sì ṣe gbé ara lé òye rẹ nìkan, nítorí, nígbàtí àkókò bá tó, Yíò fọhùn.

Ìwé mímọ́

Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Sitting in the Still: 7 Days to Waiting Inside of God’s Promise

Àwọn àkókò kan tí a gbá ìlérí Ọlọ́run mú, ṣùgbọ́n a kò rí ayé wa kí ó máa dọ́gba pẹ̀lú ìlérí náà tí Ọlọ́run fún wa. Ẹ̀wẹ̀ àkókò wà tí a bára wa ní oríta ní ìrìnàjò ayé wa, nígbàtí à ń gbára lé Ọlọ́run láti darí ipa ọ̀nà ayé wa, ṣùgbọ́n ìdákẹ́ rọ́rọ́ ni ohùn tó fọ̀ sí wa. Ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-7 yìí yóò sọ̀rọ̀ sí ọkàn rẹ nípa bí a ti ún rìn nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nígbàtí ó dàbíi pé Ó dákẹ́ jẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Jessica Hardrick tó pèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://jessicahardrick.com/