Jí Jókòó Níbi Ìdákẹ́ Rọ́rọ́: Ọjọ́ 7 Lórí Dí Dúró Sínú Ìlérí Ọlọ́runÀpẹrẹ
DAY 4
JÍJÓKÒÓ NÍ ÌDÁKẸ́JÉ: NÍNÚ ÌFẸ́ RẸ̀
Púpọ̀ nínú wa rò pé ohun gbogbo yẹ kí ó ṣíṣe ní ìrọ̀rù tí a bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run kò ṣèlérí fún wa láé ní ojú ọ̀nà tó dán mọ́rán. O ṣe, sibẹsibẹ, ṣe ìlérí láti wà pẹ̀lú wa kí ó sì pa wá mọ nínu ìfẹ́ Rẹ̀. Bí a ṣe ń rìn lọ ní ọ̀nà Ọlọ́run, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ni a kó kúrò lọ́wọ́ àtakò nítorí a retí pé kí Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ohun gbogbo lọ́nà tí a fẹ́ràn. Ní àmì àkọ́kọ́ ti ìnira, a bẹ̀rẹ̀ láti ṣiyèméjì ohun Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ fún ìgbésí ayé wa.
Nígbà mìíràn a ní ìrírí ìnira àti àwọn àìní ìrọòrùn nítorí a lọ kúrò nínú àkókò, àti àwọn àkókò mìíràn wọ́n Jẹ́ apa kán ti ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tí a bá ṣègbọràn sí ohùn Ọlọ́run, àwọn ìdènà kéékèèké wọ̀nyí ń kọ́ wa, wọ́n sì ń fún wa lókun nígbà tí a wà ní ibi ààbò tí a lè wà; ìfẹ́ Ọlọ́run.
Bí a bá wo ọ̀kan lára àwọn àkọsílẹ̀ tó dára jù lọ nínú Bíbélì nípa wíwà nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run, a máa wo ìrìn àjò Jósẹ́fù àti Màríà láti dá ọmọ Ọlọ́run nídè sínú ayé yìí. Bí wọ́n ṣe ń wá ibì kan tí wọ́n ti bí ọmọ Ọlọ́run, wọ́n ní láti gbàdúrà tí wọ́n sì bẹ Ọlọ́run pé kó ṣamọ̀nà wọn kó sì fún wọn ní àyè àkànṣe fún ìbí Jésù. Nígbàtí àdúrà wọn dàbí ẹni pé kò ní ìdáhùn, Mo ṣe ìyàlẹ́nu bóyá wọ́n lérò pé Ọlọ́run ti kọ̀ wọ́n sílè nínú ìlérí tí Ó ti ṣe fún wọn. Wọ́n lè ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì ìlérí Ọlọ́run fún ìṣẹ́jú kan; ọpọlọpọ wa ti le ṣiyèméjì. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jósẹ́fù àti Màríà ń bá a lọ nínú ìgbàgbọ́; wọn kò fi ètò náà ṣílẹ̀ nítorí kò dàbí ìlérí tí wọ́n ti gbà
Bí o bá ń rìn nínú ohun tí ó dà bí ọ̀nà tí kò ṣàjèjì ti Ọlọ́run gbà mú ìlérí sínú ìgbésí ayé rẹ, máa gbàdúrà kí o sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, àní ní “àwọn ibi ìdákẹ́jẹ́” Má ṣe jọ̀wọ́ rẹ̀ tàbí ṣiyèméjì ìpinnu Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé rẹ nítorí pé o n wà nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kìí ṣe tìrẹ. Gbàdúrà lónì nípa “ibi iduro” rẹ, Jẹ́rì láti gbé nínú ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ nìkan.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àwọn àkókò kan tí a gbá ìlérí Ọlọ́run mú, ṣùgbọ́n a kò rí ayé wa kí ó máa dọ́gba pẹ̀lú ìlérí náà tí Ọlọ́run fún wa. Ẹ̀wẹ̀ àkókò wà tí a bára wa ní oríta ní ìrìnàjò ayé wa, nígbàtí à ń gbára lé Ọlọ́run láti darí ipa ọ̀nà ayé wa, ṣùgbọ́n ìdákẹ́ rọ́rọ́ ni ohùn tó fọ̀ sí wa. Ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-7 yìí yóò sọ̀rọ̀ sí ọkàn rẹ nípa bí a ti ún rìn nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nígbàtí ó dàbíi pé Ó dákẹ́ jẹ́.
More