Jí Jókòó Níbi Ìdákẹ́ Rọ́rọ́: Ọjọ́ 7 Lórí Dí Dúró Sínú Ìlérí Ọlọ́runÀpẹrẹ

Sitting in the Still: 7 Days to Waiting Inside of God’s Promise

Ọjọ́ 5 nínú 7

DAY 5

JÍJÓKÒÓ NÍ IBI ÌDÁKẸ́RỌ́RỌ́: DÍDÚRÓ FÚN OHUN TÓ YẸ FÚN WA:

A fí àmìn òróró yàn Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba nígbàtí ó wà láàrin ọdún mẹ́rìndínlógún sì mọ́kàndínlógún, ṣùgbọ́n ó pe ọgbọ́n ọdún kí ó tó di ọba ní Ísírẹ́lì. Láàrín ọdún mẹ́tàlélógún títí di ọgbọ̀n ọdún, Dáfídì rí inúnibíni láti ọ̀dọ̀ ọba Sọ́ọ̀lù àti àwọn ìnira miran pẹ̀lú, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ó dúró ṣinṣin nínú òtítọ́ àti ìdí tí Ọlọ́run fi ṣe ìlérí fún un

Ní ìjọba Ọlọ́run, kí ì ṣe ohun tí a fẹ́ ni ó ń tẹ wá lọ́wọ́, àti ní àkókò tí a fẹ́ sì. Dídúró de asẹ̀dá jẹ́ apá kan pàtàkì tí a pè wá sí bí a ṣe ń dàgbà nínú Kristi. Dídúró de Olúwa a màá fún wa ní ìgbáradì fún ìdí tí a fi wà láyé, ó sì ń ró ìgbàgbọ́ wá lágbára sí, àti pé ó ń kọ́ wa ni ìfaradà tí ó péye.

Ọlọ̀run fúnra Rẹ̀ mọ dájú wípé gẹ́gẹ́ bí ọba, Dáfídì yíò nílò àwọn ọgbọ́n, ìfaradà, àti òye láti ṣe adarí tí ó fi ẹsẹ̀ múlẹ̀. Mò ni ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńkan tí Dáfídì nílò gẹ́gẹ́ bí ọba fún un láàrin àwọn ọdún wọ̀nyí.

Ó sèése kí ìwọ náà nílò irú ìgbáradì yí fún ìdí tí a fi mú ọ wà láàyè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó ní ìmọ̀lára ìgbáradì bí ó ti ń lọ sínú ìpè rẹ, Ọlọ́run nìkan ló mọ ohun tí ìpè rẹ dà lè lórí., nítorí náà mú ìgbàgbọ́ rẹ dúró ṣinṣin nínú Rẹ̀. Nígbàtí ó bá ní ìmọ̀lára nípa ìpè rẹ sì ohunkóhun ṣùgbọ́n tí ó kó bá mọ ìdí tí àkókò ìpè náà kò ì tí ì de, rántí pé Ó lè máà kọ ẹ l'ẹ́kọ̀ bí ti Dáfídì. Gbọ́ràn sì àṣẹ Rẹ̀, jẹ olótítọ́ sì í, kí ó sì jẹ akíkanjú kí ìpè rẹ tó dé. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run ni ìpinnu rere fún wa ju tiwa tìkálára wa; gbàdúrà loni pé ó jọ̀wọ́ ọkàn rẹ sì ìlànà àti ìfẹ́ Rẹ̀ tí ó péye.

IDAGBASOKE Bọtini: ọjọ_5 ọjọ_5
Day 4Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Sitting in the Still: 7 Days to Waiting Inside of God’s Promise

Àwọn àkókò kan tí a gbá ìlérí Ọlọ́run mú, ṣùgbọ́n a kò rí ayé wa kí ó máa dọ́gba pẹ̀lú ìlérí náà tí Ọlọ́run fún wa. Ẹ̀wẹ̀ àkókò wà tí a bára wa ní oríta ní ìrìnàjò ayé wa, nígbàtí à ń gbára lé Ọlọ́run láti darí ipa ọ̀nà ayé wa, ṣùgbọ́n ìdákẹ́ rọ́rọ́ ni ohùn tó fọ̀ sí wa. Ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-7 yìí yóò sọ̀rọ̀ sí ọkàn rẹ nípa bí a ti ún rìn nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nígbàtí ó dàbíi pé Ó dákẹ́ jẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Jessica Hardrick tó pèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://jessicahardrick.com/