Jí Jókòó Níbi Ìdákẹ́ Rọ́rọ́: Ọjọ́ 7 Lórí Dí Dúró Sínú Ìlérí Ọlọ́runÀpẹrẹ
ỌJỌ́ 2
JÍ JÓKÒÓ NÍ ÌDÁKẸ́ RỌ́RỌ́: OHUN TÍ ÀÁṢE, NÍGBÀTÍ ỌLỌ́RUN KÒ FỌHÙN.
Àwọn àkókò wà tí mo ti gbọ́ tí Ọlọ́run sọ̀rọ̀, mo sì fi ara mi sí ipò láti retí ìgbésẹ̀ tí ó kàn, tí mi ò sì gbọ́ ǹkankan mọ́ fún àkókò tó pé. Àkókò míràn sì wà pẹ̀lú tí Ọlọ́run ti fún mi ní ìlérí, tí ó sì ń di mímú ṣe kí òye rẹ̀ tó yé mi pátápátá. Èrèdí pàtàkì wà fún irú àkókò báyìí àti irú àkókò tí ó pè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti wọnú ìlérí Ọlọ́run lóríi ayé mi.
Mo rántí ìgbà kan ní ayé mi tí mo jẹ́ ọ̀dọ́ àti àpọ́n. Mo dáwà ní ẹ̀mí nìkan, dí dá wà tó ṣe pé kò sí ìfarajọ pé mo lè ní ẹni tí yóò fẹ́ràn láti fẹ́ mi. Mo mọ̀ pé a ti fọhùn ìgbéyàwó sórí ayé mi láti ọdún dí ẹ̀ sẹ́yìn, fún ìdí èyí mo kó ìlérí yìí mọ́ra. Mi ò fi ìgbà kankan ṣiyèméjì ètò Ọlọ́run lóríi ayé mi, ṣùgbọ́n mi ò ma fi mú fín lẹ̀ kiri láti wá a. Nígbà míràn ẹ̀rù á gba ọkàn mi tó bẹ́ẹ̀ pé màá sọ ìlérí Ọlọ́run nù tí mi ò bá ma jáde ìbádọ̀rẹ́. I Ọkàn mi á dààmú tí mo bá fi òpin sí ìbádọ̀rẹ́ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni ní kíákíá, kódà bí ẹni náà kò tilẹ̀ jọ pé ó yẹ fún mi. Mi ò fẹ́ tàsé pẹ̀lú Ọlọ́run, Fún ìdí èyí mo tẹ̀síwájú láti máa ṣe àwárí nínú ìdákẹ́ rọ́rọ́ Rẹ̀.
Mo mọ̀ dájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbésẹ̀ tí mo gbé ní àwọn àkókò ìdákẹ́ rọ́rọ́, tí mò ń gbìyànjú láti “ran Ọlọ́run lọ́wọ́,” lè ti mú ìfàsẹ̀yìn bá ìlérí Ọlọ́run fún mi. Mo gbé ìgbésẹ̀ tí ó fún mi ní ìrírí tó mú mi ní ègún ọkàn ju ète Ọlọ́run fún mi lọ nínú ìrìn àjò yí. Gẹ́gẹ́ bíi Sárà, mo rò pé Ọlọ́run ní lò ìrànlọ́wọ́ mi. Dípò kí n ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìrírí "ibi ìdákẹ́ rọ́rọ́" tí Ọlọ́run pèsè fún mi, mo gbìyànjú láti ran Ọlọ́run lọ́wọ́ àti láti mú ètò Rẹ̀ yàrá kíá.
Ní wíwo ẹ̀hìn hìn, mo rí bí àwọn “ibi ìdákẹ́ rọ́rọ́" ṣe fún mi ní ìgbáradì fún ibi tí mo wà báyìí. Àwọn ibi ìdákẹ́ rọ́rọ́ kọ́ mi ní ìgbàgbọ́ àti ìfaradà ó sì fún mi ní ànfàní láti ní ìrírí àwọn nkan kọ̀ọ̀kan tí mo ní láti là kọjá láti le dé ibi tí mo dé lọ́wọ́lọ́wọ́. Mo ti ṣègbéyàwó fún ọdún méje báyìí, nínú ọkàn mi, mo mọ̀ pé ibí ni ibití Ọlọ́run ti yàn fún mi.
Kíni ohun tí ó ṣe láàárín ìgbà tí Ọlọ́run fi ìlérí Rẹ̀ kan lélẹ̀ ni ọkàn rẹ tàbí tí Ó sọ nípa rẹ̀ sórí ayé àti ìgbà tí o wọnú ìlérí náà? Oó sinmi. Oó gbáradì. Oó dúró. Oó gba Ọlọ́run láàyè láti ṣiṣẹ́ nínú rẹ àti nípasẹ̀ rẹ. Ọlọ́run mọ ohun tí o máa nílò fún ìrìn-àjo tó wà níwájú, mo sì gbàgbọ́ pé Ó ún mú ọ gbáradì fún “ibi ìdákẹ́ rọ́rọ́.” Nígbàtí a rò pé Ọlọ́run ti gbàgbé wa, Ó ún ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ ní àkókò ìdákẹ́ rọ́rọ́ yìí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àwọn àkókò kan tí a gbá ìlérí Ọlọ́run mú, ṣùgbọ́n a kò rí ayé wa kí ó máa dọ́gba pẹ̀lú ìlérí náà tí Ọlọ́run fún wa. Ẹ̀wẹ̀ àkókò wà tí a bára wa ní oríta ní ìrìnàjò ayé wa, nígbàtí à ń gbára lé Ọlọ́run láti darí ipa ọ̀nà ayé wa, ṣùgbọ́n ìdákẹ́ rọ́rọ́ ni ohùn tó fọ̀ sí wa. Ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-7 yìí yóò sọ̀rọ̀ sí ọkàn rẹ nípa bí a ti ún rìn nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nígbàtí ó dàbíi pé Ó dákẹ́ jẹ́.
More