Jí Jókòó Níbi Ìdákẹ́ Rọ́rọ́: Ọjọ́ 7 Lórí Dí Dúró Sínú Ìlérí Ọlọ́runÀpẹrẹ

Sitting in the Still: 7 Days to Waiting Inside of God’s Promise

Ọjọ́ 6 nínú 7

ỌJỌ́ 6

JÍJÓKÒÓ NÍ ÌDÁKẸ́RỌ́RỌ́: SÍSỌ ÀYÀNMỌ́ NÙ

Nínú Májẹ̀mú Láéláé, a rí i pé Sọ́ọ̀lù pinnu láti ṣe bí ó ṣe wù ú nígbà tí Sámúẹ̀lì kò dé láàrin àsìkò tó dá. Dípò kí ó dúró de Ọlọ́run, Sọ́ọ̀lù ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ó sì pàdánù gbogbo ìjọba rẹ̀.

Ìtọ́ni Ọlọ́run lè ṣòro nítorí pé nígbà míràn ó máa ń dàbíí pé kò dá sí wa. Àmọ́, àwọn ìgbà yìí máa ń sábà jẹ́ ìgbà tí ó ń dán ìgbàgbọ́ àti ìgbọ́ràn wa wò. Bí a ti ń wá Ọlọ́run tí a sì ń dúró láti gbọ́ ohùn rẹ̀, a níláti kọ́ bí a ti ń dúró jẹ́ẹ́ ní àwọ́n ìkòríta wa, kí á má yà sọ́tùnún tàbí sósì, títí tí Ọlọ́run yóó fi sọ̀rọ̀ ìtọ́ni. Bí a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Sọ́ọ̀lù, eléyì ṣe kókó gan an! Ìgbésẹ̀ láì gba ìtọ́ni Ọlọ́run lè mú wa kùnà ìlérí wa. Ó tún lè mú wa pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ayé wa nínú àrìnká jìnnà sí ète wa.

Adarí ni Sọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì gbójú lé e fún ìtọ́ni; nítorí bẹ́ẹ̀, àṣìṣe t'ó bá ṣe yóò kó ọ̀pọ̀ ṣìnà. Wíwà lábẹ́ ìdojúkọ̀ àwọn ẹgbẹ́ àti àwọn ènìyàn t'ó ń sọ̀rọ̀ sínú ayé wa lè mú wa ṣìnà pẹ̀lú. Èyí tilẹ̀ lè mú wa pàdánù Ọlọ́run tí ó bá ń sọ̀rọ̀ tàbí kí a gbé ìgbésẹ̀ láì kọ́kọ́ gbọ́ ohún Ọlọ́run.

Mo gbàgbọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ kí á gbé ayé t'ó yááyì, ó sì ń rán àwọn ìlérí rẹ̀ sínú ayé wa láti fi dá wa lójú pé a gbé irú ayé t'ó fẹ́ kí á gbé, ayé t'ó ní ipa lórí àwọn mìràn t'ó sì jẹ́ ìbùkún fún wa. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá tẹ̀lé ìtọ́ni tiwa tàbí ti àwọn ẹlòmíràn, a ó pàdánù ohun tí Ọlọ́run ní fún wa.

Nítòótọ́ ni, àwọn ìgbà wà tí a kò ní gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tàbí kí á rí ìdáhùn gbà lójú ẹsẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n má sọ àyànmọ́ rẹ nù nípa títẹ̀lé ìdarí t'araà rẹ tàbí ti àwọn ẹlòmíràn. Jẹ́ kí ó hán pé olótítọ́ ni ọ́, àgùntàn tí yóò tẹ̀lé ohùn olùṣọ́ àgútàn rẹ̀ nìkan. Tí o bá ń dúró de ìmúṣẹ̀ ìlérí Ọlọ́run tí ariwo t'ó yí ọ ká sì pọ̀, wá ibi ìdákẹ́ rọ́rọ́ láti dúró, ibi tí Ọlọ́run yóò ti sọ̀rọ̀ nígbà tí ó ba ṣetán láti sọrọ̀. Jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run lónìí pé oò ní yẹsẹ̀ títí tí oó fi gbọ́ ohùn rẹ̀.

Ìwé mímọ́

Day 5Day 7

Nípa Ìpèsè yìí

Sitting in the Still: 7 Days to Waiting Inside of God’s Promise

Àwọn àkókò kan tí a gbá ìlérí Ọlọ́run mú, ṣùgbọ́n a kò rí ayé wa kí ó máa dọ́gba pẹ̀lú ìlérí náà tí Ọlọ́run fún wa. Ẹ̀wẹ̀ àkókò wà tí a bára wa ní oríta ní ìrìnàjò ayé wa, nígbàtí à ń gbára lé Ọlọ́run láti darí ipa ọ̀nà ayé wa, ṣùgbọ́n ìdákẹ́ rọ́rọ́ ni ohùn tó fọ̀ sí wa. Ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-7 yìí yóò sọ̀rọ̀ sí ọkàn rẹ nípa bí a ti ún rìn nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nígbàtí ó dàbíi pé Ó dákẹ́ jẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Jessica Hardrick tó pèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://jessicahardrick.com/