Lilépa ÀlàáfíàÀpẹrẹ

Pursuing Peace

Ọjọ́ 7 nínú 7

Wà ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Ọjọ́ Ọ̀la

Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la? Àìlèsùn, wàhálà àti àníyàn lè já irọ́ tí o bá pa. Onírúurú ohùn ló ń ké sí wa. Ọ̀kan ń sọ wípé, “Ṣe àfihàn wípé ẹni dáradára lo jẹ́.” Ohùn mìíràn sọ wípé, “Ṣe ló yẹ kí ojú araà rẹ máa tì ọ́.” Ìmíì tún sọ wípé, “Kò sí ẹnì kan tó fẹ́ràn rẹ ní tòótọ́,” àti òmíràn, “Ri dájú láti di ọlọ́rọ̀, olókìkí, àti alágbára.” 

Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ohùn aláriwo wọ̀nyí ni ohùn tó dákẹ́ rọ́rọ́ kan wà, tí ń sọ wípé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ mi, ojú rere mi sì wà pẹ̀lú rẹ.” Ohùn tí a nílò láti máa gbọ́ jùlọ ni èyí. A ní láti dẹ́kun fífi ìgbàgbọ́ wá sínú àwọn ìlépa bí kò ṣe níní ìgbàgbọ́ tó péye nínú Ọlọ́run, pẹ̀lú àwárí àlàáfíà nínú ọjọ́ ọ̀la tí Ọlọ́run ti ṣètò fún wa. 

Òwe Àwọn Adúláwọ̀:

Orun àlàáfíà máa jìnà sí ènìyàn tó ní ìlépa tó kọjá a bótiyẹ . ~ Òwe Ìlúu Chad

Àdúrà ni èpò fún gbogbo ǹkan tí a bá fẹ́ gbé ṣe. Darapọ̀ mọ́ Tearfund, àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìjọ káàkiri àgbáyé, nínú àdúrà bí àti ń bèrè fún àlàáfíà àti ìwòsàn nínú ayé ìjìyà yí.

Ìgbésẹ̀: 

Tẹ́ pẹpẹ ètò àwọn ìlépa rẹ fún ọdún márùn-ún síwájú. Lẹ́yìn èyí ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ǹkan tí o ma nílò látọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe àwọn ǹkan tí o fẹ́ àti àwọn ǹkan tí o ṣetán láti kọ̀ sílẹ̀ tàbí àwọn ǹkan tí o lérò wípé o ní láti jọ̀wọ́ fún un.

Ìwé mímọ́

Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Pursuing Peace

Ẹgbé̩e̩ Tearfund ńṣe àfẹ́ẹ́rí ìtó̩ni Ọlọ́run nípa bí wọn yóò ṣe jẹ́ abẹnugan ti àlááfíà, ìmúpadà bọ̀ sípò ìbáṣepọ̀ àti àjọṣepọ̀ tí o múná dóko láàrín àwọn ìletò káàkiri àgbáyé. Ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ méje yìí ní àwọn ìlànà ìṣe fún ìmúpadà bọ̀ sípò àjọ́ṣe rẹ àti gbígbàdúrà fún ayé tí a n gbénú rẹ̀ nípa lílo ọrọ̀ ìjìnlẹ̀ tí n bẹ nínú àwọn òwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láti rànwálọ́wọ́ kí abaà leè ṣe àwárí àlááfíà Ọlọ́run tío jẹ́ òtítọ́.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Tearfund fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://www.tearfund.org/yv