Lilépa ÀlàáfíàÀpẹrẹ
Níní Àlàáfíà ní Àkókó Yìí
Nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kàǹkan pẹ̀lú ìfẹ́, ìkáàánú, àti ìṣòótọ́ Ọlọ́run lọ́kàn bíi ìyípadà ńlá ni yóò ti rí. Nínú ìsá-sókè-sódò ayé, ó ṣe pàtàkì láti ya àkókò sọ́tọ̀, bóyá ní àfẹ̀mọ́jú tàbí ní àṣálẹ́, láti tọrọ ẹ̀bùn àlàáfíà Ọlọ́run.
Òwe Àwọn Adúláwọ̀:
Ìdákẹ́-rọ́rọ́ a máa mú àlàáfíà sú yọ àti wípé ààbò a máa kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú àlàáfíà. ~ Òwe Ìlà-Oòrùn Afrika
Mátíù 5:9 sọ wípé, “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan, nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀.”
Èyí ni ìbùkún tó tóbi jù lọ, lọ́gán tí a bá rí ẹ̀bùn yí gbà, kìí ṣe láti fi pamọ́, bí kò ṣe láti fi fún àwọn mìíràn. Láti jẹ́ ẹni tí ń fi Àlàáfíà fúnni nínú ayé tí ńṣe ìpòngbẹ fún un. A lè ṣe èyí nípa gbígba àdúrà fún àlàáfíà àwọn ẹlòmíràn, fún àlàáfíà ní àwọn ibi tí rògbòdìyàn wà, fún ìtanijí àti ọgbọ́n fún àwọn adarí àti apẹ̀tù-sí-aáwọ̀ ní àwọn ibi tí wàhálà wà.
Òwe Ilẹ̀ Adúláwọ̀:
Ìsúré ní gbogbo ìgbà kò dẹ́kun ikú, bẹẹni fífà bí ìgbín kò ní kí a pẹ́ láyé. ~ Òwe ẹ̀yàa Igbo
Nígbà tí ohun gbogbo bó ti yẹ, ìjọ Ọlọ́run wà gẹ́gẹ́bí ‘àwòrán ìyè’ àti ajẹ́rìí sí iṣẹ́ ìwòsàn, àti ìmúbọ̀sípò ti Kristi. Tearfund tẹ́ pẹpẹ ètò tí a pè ní Ìlù èyí tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣísẹ̀ tí o lè fi sójú ìṣe, pẹ̀lú ìpinnu láti jẹ́ apẹ̀tù sí ááwọ̀ ní ojojúmọ́.
Ìgbésẹ̀:
Lọ sí gbàgede láti wo àwọn tí ń kọjá. Gbàdúrà fún àwọn tí o bá rí, pẹ̀lú ìmọ̀ wípé Ọlọ́run mọ̀ wọ́n dénú dénú. Gbàdúrà wípé kí wọ́n ṣe kòńgẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, àti láti ní ìmọ̀lára ìwàláàyè Rẹ̀ pẹ̀lú pẹ̀lú ohun tí wọ́n lè máa là kọjá.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ẹgbé̩e̩ Tearfund ńṣe àfẹ́ẹ́rí ìtó̩ni Ọlọ́run nípa bí wọn yóò ṣe jẹ́ abẹnugan ti àlááfíà, ìmúpadà bọ̀ sípò ìbáṣepọ̀ àti àjọṣepọ̀ tí o múná dóko láàrín àwọn ìletò káàkiri àgbáyé. Ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ méje yìí ní àwọn ìlànà ìṣe fún ìmúpadà bọ̀ sípò àjọ́ṣe rẹ àti gbígbàdúrà fún ayé tí a n gbénú rẹ̀ nípa lílo ọrọ̀ ìjìnlẹ̀ tí n bẹ nínú àwọn òwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láti rànwálọ́wọ́ kí abaà leè ṣe àwárí àlááfíà Ọlọ́run tío jẹ́ òtítọ́.
More