Lilépa ÀlàáfíàÀpẹrẹ
Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Ọlọ́run
Èyí ò kàn rí bẹ́ẹ̀ lásán, àmọ́ àwa tún lè yangàn nínú Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a fi ìlàjà fúnwa. (Róòmù 5:11)
Ìlépa àlàáfíà jẹ́ ohun tí a lè gùn lé fúnra ra wa. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni a lè gbà rí àlàáfíà. Bóyá ní yàrá ìgbafẹ́ tàbí ibikíbi tó bá fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀, ó dára láti máa ṣàwárí ibi-ìyàsímímọ́ fún ọkàn wa, pẹ̀lú ìpinnu.
Ọ̀rọ̀ yí 'ibi-ìyàsímímọ́' ní èdè Gẹ̀ẹ́sì wá látinú Látìn ‘sanctus’ èyí tó túmọ̀ sí mímọ́.
A ti mú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run bọ̀sípò nípasẹ̀ Jésù. Jésù ti mú wa ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Baba, èyí tó kàwáyẹ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
Bí a ti ńṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa tó jọjú, a ní láti jẹ́ olóòótọ́ pẹ̀lú fífi ọkàn wa hàn fún ìbáṣepọ̀ náà lè rinlẹ̀. Tọ Ọlọ́run lọ pẹ̀lú àwọn ǹkan tí o nílò láti jọ̀wọ́, pẹ̀lú ṣíṣe àwárí ìfẹ́ àti ìkáàánú Rẹ̀ láti fún ọ ní àlàáfíà. Bẹ̀bẹ̀ pé kí Ó túbọ̀ máa yí ọ padà láti dà bíi Kristi.
Òwe Àwọn Adúláwọ̀
Fi ọ̀rẹ́ẹ̀ rẹ hàn mí èmi yóò sì fi ìwà rẹ hàn. ~ Òwe Àwọn Adúláwọ̀
Ìgbésẹ̀:
Ní ìtàkùrọ̀sọ pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ẹ̀ rẹ tímọ́ tímọ́ kí o sì sọ àǹfààní ìbáṣepọ̀ yín fún un. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ yìí, ṣe àṣàrò lóríi bí o ti lè ní irúfẹ́ ìbáṣepọ̀ yí pẹ̀lú Ọlọ́run, nítorí Ó ti pè ọ́ ní ọ̀rẹ́.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ẹgbé̩e̩ Tearfund ńṣe àfẹ́ẹ́rí ìtó̩ni Ọlọ́run nípa bí wọn yóò ṣe jẹ́ abẹnugan ti àlááfíà, ìmúpadà bọ̀ sípò ìbáṣepọ̀ àti àjọṣepọ̀ tí o múná dóko láàrín àwọn ìletò káàkiri àgbáyé. Ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ méje yìí ní àwọn ìlànà ìṣe fún ìmúpadà bọ̀ sípò àjọ́ṣe rẹ àti gbígbàdúrà fún ayé tí a n gbénú rẹ̀ nípa lílo ọrọ̀ ìjìnlẹ̀ tí n bẹ nínú àwọn òwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láti rànwálọ́wọ́ kí abaà leè ṣe àwárí àlááfíà Ọlọ́run tío jẹ́ òtítọ́.
More