Lilépa ÀlàáfíàÀpẹrẹ
Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Àyíká Rẹ
Ìfòyà lè já àlàáfíà wa gbà. Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ma ń wo ìròyìn kí ẹ̀rù sì máa bà ẹ́ wípé wàhálà òhun làásìgbò inú ayé ń peléke si? Láàrin gbogbo ìjàmbá, ìyípadà ojú ọjọ́ àti ìkọlù, Jésù kò sùn, ó ń kó ìbẹ̀rù ní ìjánu ó sì ń darí wa láti ní ìgbàgbọ́ dípò ìfòyà.
Nínú ayé àìmọ̀kan dájú àti ẹ̀rù, bí ìgbà tí ó bá pé láti fi àlàáfíà rẹ kọ̀ sára ààbò ni yóò rí, pẹ̀lú ìgbìyànjú láti ṣe àwárí àlàáfíà nínú ara wa nípa kíkó ọrọ̀ jọ.
Òwe Àwọn Adúláwọ̀:
Ọrọ̀ tí ń kó olúwa rẹ̀ ní ìpàm̀pá kìí ṣe ọrọ̀ rárá . ~ Yorùbá
Àlàáfíà tí Jésù fífúnni yàtọ̀ kedegbe. Àlàáfíà láàárín ìjìyà àti ìjì ni ó jẹ́. Ó sọ fún wa wípé “Ẹ ta gírí. Èmi ni. Ẹ má ṣe bẹ̀rù!” Níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ẹ má ṣe kó ọkàn sókè tàbí fòyà.”
Ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa ni láti rin ìrìn àjò ayé wa láìní ìfòyà, ṣùgbọ́n àwa kò lè dá a ṣe láì ní ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Tearfund a máa ṣiṣẹ́ ní àwọn àgbègbè tí ìjàmbá ti ṣẹlẹ̀, ní ìpinnu láti ṣiṣẹ́ fún Jésù níbi tí wọ́n ti nílò rẹ̀ jù. Wo fọ́nrán yìí this video láti rí àwọn ọ̀nà tí Tearfund New Zealand ṣe ta kìjí láti mú àlàáfíà wá sí ayé.
Ìgbésẹ̀:
Ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn kókó ìròyìn mélòó kan, pa ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán, fi ìwé ìròyìn náà kalẹ̀, kí o sì yí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsì náà sílẹ̀. Gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn ìpèníjà tí a ti mú wá sí etí-ìgbọ́ rẹ kí o sì bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà Rẹ̀ fún wọn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ẹgbé̩e̩ Tearfund ńṣe àfẹ́ẹ́rí ìtó̩ni Ọlọ́run nípa bí wọn yóò ṣe jẹ́ abẹnugan ti àlááfíà, ìmúpadà bọ̀ sípò ìbáṣepọ̀ àti àjọṣepọ̀ tí o múná dóko láàrín àwọn ìletò káàkiri àgbáyé. Ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ méje yìí ní àwọn ìlànà ìṣe fún ìmúpadà bọ̀ sípò àjọ́ṣe rẹ àti gbígbàdúrà fún ayé tí a n gbénú rẹ̀ nípa lílo ọrọ̀ ìjìnlẹ̀ tí n bẹ nínú àwọn òwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láti rànwálọ́wọ́ kí abaà leè ṣe àwárí àlááfíà Ọlọ́run tío jẹ́ òtítọ́.
More