Lilépa ÀlàáfíàÀpẹrẹ

Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Ara Wa
Ìjàkadì tó lágbára jù fún àlàáfíà máa ń wáyé lóóókan àyàa wá. A gbọ́ ìtàn kan nípa bàbá àgbàlagbà kan tó sọ fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ wípé, "ó ńṣe mí bíi wípé ìkookò méjì ń ja ìjàkadì lóóókan àyà mi. Ọ̀kan nínú àwọn ìkookò yí jẹ́ oníbìnú, onípàáǹle, àti èyí tí ń gbẹ̀san. Ìkookò kejì ní ìfẹ́ àti ìkáàánú. Ọmọ-ọmọ yí wa bèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ àgbà wípé, "Èwo nínú àwọn ìkookò yí ní yóò borí ìjàkadì inú ọkàn yín?" Baba àgbà náà fèsì wípé, "Èyí tí mo bá bọ́ nínú méjèèjì ni."
Àwa ni yóò yan ǹkan tí a ma fi bọ́ ọkàn wa. Irú èrò wò lò ń rò sí araà rẹ? A gbọ́dọ̀ darí èrò ọkàn wa àti bí a ti ń kojú ìpòrúru ọkàn wa. Bíbélì rọ̀ wá láti mú àlàáfíà jọba lọ́kàn wa nípa jíjọ̀wọ́ gbogbo àníyàn wa sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti gbígbàá láàyè láti pa ọkàn wa mọ́, bó tilẹ̀ kọjá òye wa.
Òwe Àwọn Adúláwọ̀:
Àwọ̀ àmọ̀tẹ́kùn rẹwà púpọ̀, àmọ́ ọkàn rẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. ~ Òwe àwọn èèyàn Baluba
Àrọko tó ń peni níjà kan wà lóríi òpó orí ìtàkùn Tearfund èyí tó yẹ láti kà, èyí tó ń tọ pinpin tí ìdánimọ̀ wa bá dá lóríi aṣọ tí à ń wọ̀ sọ́rùn.
Ìgbésẹ̀:
Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ohun ìní máa ń jẹ́ ìdánimọ̀ wa. Lọsí ilé ìtajà tó ń ta àwọn aṣọ tí o fẹ́ràn, kiise láti rajà ṣùgbọ́n láti ní àǹfààní fún àṣàrò lóríi àìní rẹ. Gbàdúrà ìyìn sí Ọlọ́run nítorí ó fi aṣọ ìwà mímọ́ bò ọ́. Tọrọ fún ìbápàdé pẹ̀lú Rẹ̀ lákòókò yẹn kí o sì jáde kúrò nínú ilé ìtajà náà láì ra ohun kan, ní ìmọ́ wípé àwárí ohun kàn tí Ọlọ́run nìkan lè fi fún ọ ló gbé ẹ lọ síbẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ẹgbé̩e̩ Tearfund ńṣe àfẹ́ẹ́rí ìtó̩ni Ọlọ́run nípa bí wọn yóò ṣe jẹ́ abẹnugan ti àlááfíà, ìmúpadà bọ̀ sípò ìbáṣepọ̀ àti àjọṣepọ̀ tí o múná dóko láàrín àwọn ìletò káàkiri àgbáyé. Ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ méje yìí ní àwọn ìlànà ìṣe fún ìmúpadà bọ̀ sípò àjọ́ṣe rẹ àti gbígbàdúrà fún ayé tí a n gbénú rẹ̀ nípa lílo ọrọ̀ ìjìnlẹ̀ tí n bẹ nínú àwọn òwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láti rànwálọ́wọ́ kí abaà leè ṣe àwárí àlááfíà Ọlọ́run tío jẹ́ òtítọ́.
More