Ọlọ́run jẹ́_______Àpẹrẹ
Tani Ọlọrun jẹ sí ọ?
F'ojú inú wo awọn ọdọmọde méjì tí wọ́n ńṣe àpèjúwe bàbá wọn. Ọmọ kini lè ní àfojúsùn bí bàbá wọn ṣe jẹ apanílẹ́rin, tí ó duro ṣinṣin tí ó sí ní ìfẹ, nígbàtí èkejì sí wo bí bàbá òun ṣe dojukọ iṣẹ rẹ, ó ní ìwà pẹlẹ àti sùúrù pẹlu. Awọn ọdọmọde méjèjì sí ńṣe àpèjúwe ẹ́nìkan náà, ṣugbọn ìrírí ẹnikọọkan wọn fí ìwòye tí wọn ní nípa bàbá jẹ èyí tí ó jẹ àrà ọtọ pátápátá.
Bákannáà, gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun l'oni ìrírí Rẹ ní ọ̀nà tí ó yatọ diẹdiẹ sí ara wọn, ìdí níyì ti awọn kan ní àfojúsùn tí ó le nípa ìwà mímọ́ àti agbára Rẹ, tí àwọn míràn sí f'ojúsun ìwà rere àti àánu Rẹ. Ní ọ̀nàkọ́nà, Ọlọrun jẹ Bàbá pípé atí pé ìwà Rẹ wà ní ìbámu pẹlú ọrọ Rẹ.
Ṣugbọn Ọlọrun tí fí ara Rẹ han fún ẹnikọọkan wa. Ìdí níyì ti ó fí jẹ pé ọ̀nà tí olúkúlùkù ńgbà láti ṣe àpèjúwe Ọlọrun kò lè bá ara wọn dọgba, èyí sì dára bẹẹ! Èyí tí ó ṣe kókó nipé á fẹ rí dájú wípé ìwòye wa nípa Ọlọrun wà ní ìbámu pẹlú ọrọ Rẹ
Nítorí tí a rí iṣẹ tí Ọlọrun ńṣe nínú ayé wa ní orísirísi ọ̀nà, ìbáṣepọ̀ wa pẹlu Rẹ fúnwa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹnití Ó jẹ. Bóyá ní àkókò àìsàn, á ní ìrírí Ọlọrun gẹgẹbi Olùwòsàn, tí ẹlòmíràn sí ní àgbàyánu ìtàn nípa Ọlọrun gẹgẹbi Olùpèsè. Ìrírí méjèjì ńró ìgbàgbọ wa l'ágbára ó sí tún ràn wá lọwọ láti kẹkọọ irú ẹnití Ọlọrun ńṣe.
Orin Dafidi jẹ àpẹẹrẹ nlá kán nípa èyí. Á rí orin ìdárò àti orin ìyìn, ọkọọkan sí dá lórí ohun ọtọtọ nípa Ọlọrun. Á ṣe àwárí Ọlọrun tí ó jẹ Olùtùnú, aláàbò wa nínú wàhálà àti Ọlọrun tí ó jẹ orísun ayọ wa.
Á máà ńní ìṣòro nígbàtí á bá gbé ojú ìwòye wa nípa Ọlọrun kárí ipò tí a wa dípò wiwa Ọlọrun láàrin wọn. Nígbàtí á bá wo Ọlọrun nípa èrò inú wa lọwọlọwọ a ó rí ọlọrun tí o ńdún bí àwa náà. Tàbí kí á ṣe àtúndá ọlọrun tí ó wá tí ó sí ńse ojúṣe tiwa.
Ṣugbọn dípò èyí nígbàtí á bá yàn lati ṣe àgbéyẹwo òtítọ́ ìwà Ọlọrun nínú àwọn ipò tí a wa, ibẹ̀ ní á ó tí rí ìrètí, àlàfíà, ìtùnú àti ayọ̀.
Nitorina tani Ọlọrun jẹ sí ọ?
Ṣiṣe àwárí ìdáhùn ìbéèrè yí lè jẹ ohun tí á ó máà lépa rẹ títí ayérayé, ṣugbọn eléyi yíò jẹ́ ìbéèrè pàtàkì tí ó yẹ kí á máà ronú lé lórí.
Gbàdúrà Ọlọrun, á dupẹ lọwọ Rẹ nítorípé Ó jẹ àìlópin, ó sí súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí. Mo mọ̀ Ọ́ gẹgẹbi ----------, mo sí ní ìgbàgbọ́ pé Ẹ̀yin ní -----------. Rán mí lọwọ láti ṣe àtúnṣe tí ó tọ́ àti láti kojú awọn irọ́ èyíkéyi tí mo sí gbagbọ nípa Rẹ, àti pé kí ó fúnmi ní ọpọlọpọ ìrírí tí yíò ṣe àfihàn àwọn ìwà rere Rẹ. Rán mí lọwọ láti dẹ́kun gbígbé ìwòye mí sí Ọ́ lè ipò ìgbé ayé mí dípò èyí kí ḿbẹ̀rẹ̀ sí ní wá Ọ́ l'aarin wọn. Ní orúkọ Jésù,. àmín.
Ìpèníjà: Padà sí àtòkọ rẹ láti ọjọ kíni. Kíni ohun míràn tí ìwọ yíò fí kun? Ronú nípa ìrírí rẹ tí ó tí ní pẹlu Ọlọrun nípa ọkọọkan ohun tí á mọọ mọ. Ṣe awọn àkọsílẹ nípa wọn kí ó sí rán ara rẹ létí nígbàtí ó bá bẹrẹ sí ṣe ìbéèrè nípa ìwà Rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Tani Ọlọ́run? Gbogbo wa l'a ní oríṣìríṣì ìdáhùn, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe leè mọ èyí tó jẹ́ òtítọ́? Irú ìrírí tí o ti lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn Krìstẹ́nì, àbí ìjọ látẹ̀hìnwá kò já sí nnkan kan - àsìkò tó láti mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe rí - gidi ni, Ó wà láàyè, Ó sì ṣetán láti bá ọ pàdé níbi tí o wà yẹn gan an. Gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Ètò Bíbélì Kíkà Ọlọ́jọ́ Mẹ́fà yìí tí ó tẹ̀lé ìwàásù Àlùfáà Craig Groeschel pẹ̀lú àkọlè, Ọlọ́run Jẹ́ ____.
More