Ọlọ́run jẹ́_______Àpẹrẹ

God Is _______

Ọjọ́ 3 nínú 6

Ọlọ́run Tó Gbójúlé

Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lí àná, lónìí, àti títí láé.Hébérù 13:8 BM

Ǹjẹ́ ẹnìkan ti parọ́ fún ọ rí, ó dà ọ́, tàbí ó já ọ kulẹ̀? Ó ṣeé ṣe, kí èyí májẹ̀ẹ́ ǹkan titun sí ọ, àti pé ó ṣeé ṣe kí padà ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Kí nìdí? Nítorí kòsí ènìyàn kan tó jẹ́ pípé.

A máa ń gbìyànjú láti mú àdéhùn ṣẹ ati lati jẹ olódodo, ṣùgbọ́n ní igba míràn, gbogbo wa ni ò ní ṣe aláìṣe àṣemáṣe ni igba kan tàbí òmíràn. Bóyá nípa àìlèparí iṣẹ́ nígbà tó yẹ tàbí àìlè mú àdéhùn ṣẹ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ, gbogbo wa la máa fìgbà kan kùnà ìdánilójú tí a ní síwa nínú àwọn ìbáṣepọ̀ wa.

Níní ìrírí ìjákulẹ̀ nípa ìdánilójú a máa fa ẹ̀dùn ọkàn yálà nísinsìnyí tàbí ní ọjọ́ iwájú. Kódà, onírúurú ìwádìí ìjìnlẹ̀ ló ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ìrírí ìjákulẹ̀ nípa ìgbẹ́kẹ̀lé a máa nípa lórí ọpọlọ, ara, àti àwọn ìbáṣepọ̀ wa.

Ìṣọwọ́ rọ ọpọlọ wa a máa múwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ènìyàn, nígbà tí a bá ṣe èyí, ara wa ma pèsè omi kan tí ó ń jẹ́ oxytocin, èyí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ń pè ní “kẹ́míkà ìfẹ́” tàbí “ògùn ìgbẹ́kẹ̀lé.” Ìpèsè kẹ́míkà yí nínú ọpọlọ wa a máa mú ìṣọwọ́ ní ìgbẹ́kẹ̀lé wa yanrantí, fún ìdí èyí bí àwọn ìrírí tí a ní pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé òtítọ́ ṣe ń pọ̀síi, bẹ́ẹ̀ni ó ma yáwa lára láti fi inú tọ àwọn ẹlòmíràn.

Ṣùgbọ́n, bí ìdàkejì rẹ̀ náà ti rí nìyí. Nígbà tí ẹnìkan bá já wa kulẹ̀, ó ma mú kí ẹ̀yà ọpọlọ wa tó nííṣe pẹ̀lú ìbẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́, èyí tó máa jẹ́kí ó ṣòro láti gbẹ́kẹ̀lé ẹnìkẹ́ni l'ọ́jọ́ wájú.

Fún ìdí èyí tí a bá dé ìkòríta àti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a máa ń ní ìdojúkọ èyí tó máa múwa ṣe àfiwé ìrírí wa nípa ìjákulẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran-ara àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run pípé.

Bóyá ó ṣòro fún ìwọ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nítorí òbí tàbí adarí kan ti já ọ kulẹ̀ rí. Tàbí ó ṣòro fún ọ láti ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ láburú kan tí ṣẹlẹ̀ sí ọ rí, tí ó sì wá dàbíi wípé Ọlọ́run kò dáhùn àdúrà rẹ rárá.

L'òtítọ́ ni irú àwọn ìrírí báyìí a máa dunni, ṣùgbọ́n kò yí òtítọ́ nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ padà. Òhun ni ẹnìkan ṣoṣo tí a lè gbójúlé láì fòyà. Ẹ jẹ́ kí a wo ìdí tí a gbọ́dọ̀ fi gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nínú Ìwé Mímọ́.:

  • Òun ni Ẹni tí kò yí padà. kí ń ṣe ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ padà ní igbakigba, Ọlọ́run kì ń yí ọkàn padà nípa ìfẹ́ tí Ó ní sì wa tàbí èrò rere tí Ó ní fún wa. (Wò Malaki 3:6 àti Hébérù 13:8.)
  • Kò ní fi ọ̀ silẹ tàbí Kọ ọ̀ sílè kò sohun tí ó lè ṣe tí o máa mú Ọlọhun kúrò lọdọ rẹ. Ìwàláàyè Rẹ wà pẹ̀lú wa ni gbogbo igba, àti pé kò sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò bá sele sì wá, Òun yóò wà pẹ̀lú wa ninu gbogbo rẹ. (Wò Hébérù 13:5 àti Róòmù 8:39.)
  • Òun ni Ẹni tí ṣíṣe pọ sì rere fún wa ní gbogbo ìgbà. Yálà nínú ìrora láyé yìí, Ọlọ́run lè dá ọsọ́ jáde nínú erú. Òun ni Alamoja àtúnṣe àti ìràpadà, àti pé Òun ni Ó mọ ìdí ìrora wá. (Wo Róòmù 8:28, Aísáyà 61:1-3.)

Kò sí iye ìgbà tí àwọn ènìyàn ti já ọ kulẹ̀, Ọlọ́run kò ní fi ẹ́ ṣílẹ̀. Kò ní fi ìgbà kankan fi ọ́ sílẹ̀, àti pé Òun ni ó yẹ láti gbẹ́kẹ̀lé.

Gbàdúrà: Ọlọ́run, ní ìgbà míràn ó ma ń ṣòro fún mi láti gbẹ́kẹ̀lé Ẹ nítorí _________. Ǹjẹ́ ó lè ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìdènà ìgbẹkẹ̀lé kíkún nínú Rẹ? Mo dúpẹ́ pé O jẹ́ ẹni tí mo lè fọkàntán. Di ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú Rẹ ní àmùrè, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ fún ìṣe tí ó ńṣe láti mú ohun gbogbo ṣiṣẹ́ papọ̀ sí rere. Ní orúkọ Jésù Kristi, Àmín.

Ìpèníjà: Wa àkókò láti gbàdúrà nípa àwọn ibi tí ó nira fún ọ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run. Kí o sì jọ̀wọ́ gbogbo ǹkan wọ̀nyí s'ọ́wọ́ Rẹ̀. Ó lè kọ wọ́n sílẹ̀ kí o sì fi sínú àbọ̀ láti fi ṣààmì wípé ó ti jọ̀wọ́ wọn fún Ọlọ́run.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

God Is _______

Tani Ọlọ́run? Gbogbo wa l'a ní oríṣìríṣì ìdáhùn, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe leè mọ èyí tó jẹ́ òtítọ́? Irú ìrírí tí o ti lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn Krìstẹ́nì, àbí ìjọ látẹ̀hìnwá kò já sí nnkan kan - àsìkò tó láti mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe rí - gidi ni, Ó wà láàyè, Ó sì ṣetán láti bá ọ pàdé níbi tí o wà yẹn gan an. Gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Ètò Bíbélì Kíkà Ọlọ́jọ́ Mẹ́fà yìí tí ó tẹ̀lé ìwàásù Àlùfáà Craig Groeschel pẹ̀lú àkọlè, Ọlọ́run Jẹ́ ____.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/