Ọlọ́run jẹ́_______Àpẹrẹ

God Is _______

Ọjọ́ 2 nínú 6

Aláanú ni Ọlọrun

Nitorina ẹ jẹki á wá pẹlu ìgboyà síwájú itẹ Ọlọrun wà olore-ọfẹ. Níbẹ ní á ó tí rí àánu Rẹ gbà, á o sí rí ore-ọfẹ láti ràn wá lọwọ nígbàtí á bá nílò rẹ julọ.Hébérù 4:16NLT

Bí á tí ṣe sọ l'ana, Ọlọrun ńlépa wa nígbà gbogbo, àní nígbàtí a jẹ alààyè. Irú ìsesí bayi jẹ àmì láti fí mọ pé Aláanú ní.

Gbogbo wa lo tí ṣẹ̀ a sí tí kùnà ìlànà Ọlọrun, eléyi sí mú ìdènà wá láàrín àwa àti Ọlọrun wa tí ó pé tí ó sí jẹ mímọ pẹlu. Nínú àánu Ọlọrun, Ó rán Jésù láti tẹ́rígba ìjìyà tí ó tọ síwa-ikú- Ó sì ṣe ọnà àbayọ fúnwa láti jẹ alábapín ìyè àìnípẹkun pẹlu Rẹ.

Nitorina àánu Ọlọrun túmọ sí pé a kò gbà ohun tí ó tọ síwa. Ṣugbọn kò tàn síbẹ̀ Àánu Ọlọrun kìíse pípèsè ọna àbáyọ nìkan. Ò tún jẹ ṣiṣe ọnà Rẹ nínú wa.Kìíse pé ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kuro nìkan, Ó rán ọmọ Rẹ. Ó ṣe ọnà láti bá wa níbití a wà, àti bí a ṣe wà.

Jésù wá gẹgẹbi Immanuẹli: Ọlọrun pẹlu wa. Ó ní ìrírí gbogbo ìmọ̀lára ẹdá ènìyàn, ìgbé ayé Rẹ lórí ilẹ alààyè sí jẹ ẹrí ifẹ ọkan Ọlọrun láti sunmọ wa. Ati pe nínú ìsúnmọ́ra-ẹni bayi láti rí àánu Ọlọrun

Nínú gbogbo awọn Ihinrere, lati rí ọpọlọpọ àpẹẹrẹ "awọn tí ó nbeere àánu lọwọ Jésù". Àpẹẹrẹ kan tí ó lágbára ní a ṣe agbekalẹ rẹ nínú ìwé Luku 17 nigbati awọn adẹtẹ tọ Jésù wá.

Gẹgẹbi agbekalẹ, ẹ̀tẹ̀ nigba yẹ sọ awọn eniyan ti ó bá ní dì aláìmọ́, ti wọn kò sí gbọdọ gbé ní àárín ilú. Bí a tí ṣe kọ sílẹ nínú ìwé òfin Léfítíkù, a kà wọn sí aláìmọ èyí tí o túmọ sí pé ẹnikẹni tí ó bá fí ọwọ kàn wọn oun náà yíò dì aláìmọ́.

Ṣugbọn bí Ọlọrun tí wá nínú ara, Jésù jẹ ẹni mímọ, Ó jẹ aláìlábáwọn, mímọ àti pípé pẹlu. Bí àwọn adẹtẹ náà ṣe tọ Jésù wà, wọn kígbe soke fún àánu. Jesu sí sọ fún wọn láti lọ rí àlùfáà- gẹgẹbi agbekalẹ òfin. Bí wọn sì tí nlọ wọn rí ìwòsàn

Laiṣe àníàní, Jésù fi òfin múlẹ ní idakeji. Dípò kí ó di aláìmọ nípa fífi ọwọ kan wọn, Ó fí jíjẹ mimọ Rẹ bó aimọ wọn

Àti pé ìyẹn jẹ àmì pípé ohun tí Jésù ṣe fún olukuluku wa nípa ikú ati ajinde Rẹ. Ọlọrun kò kàn mú ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìrora, àti ìrora aya kuro - Ó bawa nínú rẹ nipasẹ Jésù. Nígbàtí a bá rí ìgbàlà nínú Kristi, a o ní ìrírí àánu Ọlọrun

Ṣugbọn lẹẹkansi, ó ju ìyẹn lọ daradara. Kìíse nipa ìgbàlà ní a fí ní ìrírí àánu Ọlọrun ṣugbọn ni àkókò ìrora, ìbànújẹ àti àinireti- gẹgẹbi ìrírí àwọn adẹtẹ yẹ. Nitorina bí o bá wà ní àkókò ìṣòro nisisiyi kígbe fún àánu Ọlọrun. Ó wà pẹlu rẹ, Ó wà nítòsí, Ó ṣe tán láti wo ọ sàn, dá ọ padà sí ipò, àti láti rà ọ padà

Gbàdúrà Ọlọrun, a dupẹ lọwọ Rẹ fún ọpọlọpọ àánu Rẹ tí a nrigba. Ẹ ṣe fún Jésù tí ẹ fí fúnwa. Ẹ ṣeun fún jíjẹ Ọlọrun tí ó fẹ láti sunmọ wa bíótilẹ jẹ pé a kò lẹtọ sí. Sí mí lójú láti rí àánu Rẹ pápá nínú ìrora, kí ó sí ran mí lọwọ láti fí irú àánu ifẹ bẹẹ hàn sí àwọn tí ó yimika pẹlu. Ní orúkọ Jésù, àmín

Ìpèníjà: Wá àyè láti rí àánu Ọlọrun ní igbesi aiye rẹ àti láti s'àánu fún àwọn ẹlòmíràn lóni.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

God Is _______

Tani Ọlọ́run? Gbogbo wa l'a ní oríṣìríṣì ìdáhùn, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe leè mọ èyí tó jẹ́ òtítọ́? Irú ìrírí tí o ti lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn Krìstẹ́nì, àbí ìjọ látẹ̀hìnwá kò já sí nnkan kan - àsìkò tó láti mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe rí - gidi ni, Ó wà láàyè, Ó sì ṣetán láti bá ọ pàdé níbi tí o wà yẹn gan an. Gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Ètò Bíbélì Kíkà Ọlọ́jọ́ Mẹ́fà yìí tí ó tẹ̀lé ìwàásù Àlùfáà Craig Groeschel pẹ̀lú àkọlè, Ọlọ́run Jẹ́ ____.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/