Ọlọ́run jẹ́_______Àpẹrẹ
Tani Ọlọ́run?
Ọlọ́run jẹ́_______.
Ọ̀rọ̀ wo ni ó wá sọ́kàn rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Bóyá o mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Bàbá rẹ tí o fẹ́ràn. Bóyá o ti ní ìrírí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Olùwòsàn tàbí Olùpèsè. Tàbí bóyá o ro Olọ́run bíi pé ó jìnà sí ọ, inú ńbi tàbí Onídájọ́.
Kò sí bí o se dáhùn ìbérè yìí, bí o se rí Ọlọ́run sí se pàtàkì nínú ayéè rẹ. Kódà, Olùṣọ̀ àgùntàn àgbà àti olùkọ̀wé A.W Tozer kọ wípé "Ohun tí ó wá sọ́kàn wa nígbà tí a bá ńrò nípa Ọlọ́run ni ó jẹ́ kókó jù nípa wa."
Bí a se rí Ọlọ́run ní ipa nínú bí a se ńwo ara wa, àwọn ẹlòmíràn, àti gbogbo nkan tí ó yí wa ká. Nítorí èyí ní ó se se pàtàkì kí á kọ́ ìpilẹ̀ wa nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ lórí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí kò lè yí padà- kí á má kọ́ lórí èrò wa tí kò fìdímúlẹ̀
Bóyá o ti ní ìrírí ọ̀fọ̀, o sọ nkan nù, tàbí ìjákulẹ̀ tí ó jẹ́ kí inú bí o sí Ọlọ́run tàbí ìpalára láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bóyá o ti pàdé àwọn Ọmọ lẹ́yìn Krístì tí wọ́n jẹ́ kí o lérò pé a dá ọ lẹ́jọ́ a dá ọ lẹ́bi, nítorí náà o rò pé bákannáà ni Ọlọ́run rí. Bóyá o ti gbìyànjú láti gbàdúrà tàbí bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, sùgbọ́n ó dàbí nkànkan ò sẹlẹ̀, nítorí náà o rò pé Ọlọ́run jìnà ṣí ọ, tàbí Ọlọ́run ò bìkítà.
Àwọn ìrírí yì àti èrò ọkàn rẹ yì le jẹ́ òótọ́, sùgbọ́n àwọn ìrírí yìí kò sàfihàn tòótọ̀ nípa ìwà Ọlọ́run.
Kódà, síse àyípadà ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ síwa jẹ́ ọ̀kan nínú ọgbọ́n àrékérekè tí ̀̀ọ̀tá ńlò láti ìbẹ̀rẹ̀. Níní Ọgbà ídẹ́nì tí ó dára, Ọlọ́run bá Ádámù àti éfà rìn, ó wá fún wọn ní ohun kan ṣoṣo pé kí wọ́n má se: Ẹmá jẹ nínú èso igi ìmọ̀. Sùgbọ́n ọ̀tá wọlé, ó bi éfà wípé sé lòótọ́ ni Ọlọ́run sọ wípé kò gbọdọ̀, ọ̀tá wá gbìyànjú láti dá éfà lójú wípé Ọlọ́run fi nkàn tí ó nílò ganngan pamọ́ fún ni.
Nítorí ìdí yìí, Éfà jẹ èso, bẹ́ẹ̀ni ẹ̀sẹ̀ wọnú ayé, ó yà wá kúrò nínú ìbásepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.
Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí, Ìwà Ọlọ́run kò yípadà. Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè ìbora fún Ádámù àti Éfà, tí ó fi ìse rẹ̀ ńlá ti ẹbọ ìfẹ́ ṣáájú: Órán Ọmọ Rẹ̀ tí kò lábàwọ́n, Jésù, láti gbé ayé àìlẹ́sẹ̀ àti láti kú ní ipò wa láti ra ìbásepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run padà.
Nígbà míràn a le máa rò wípé Ọlọ́run Májẹ̀mú Àtijọ́ jẹ́ Ọlọ́run tí ó má ńdájọ́, àti wípé inú Májẹ̀mú Titun ni a ti rí àánú láti ipasẹ̀ Jésù. Sùgbọ́n ní Òtítọ́, Ọlọ́run wà nínú ìṣòwò àti máa lépa àwọn ẹlẹ́sẹ̀ pẹ̀lú oore kí àwá tóó lépa rẹ̀. Ó jẹ́ olódodo láti se àwọn ìlérí Rẹ. Ósì tún jẹ́ Olódodo àti aláànú, mímọ́ àti oní ìfẹ́, ó ba lórí ohun gbogbo àti wípé kòyípadà.
Ìwà Ọlọ́run jìn, ó lọ́rọ̀, àti wípé ó níńlá láti túmọ̀ pátápátá, sùgbọ́n arí àwọn òye yì nínú gbogbo Bíbélì.
Nítorí náà bí o se ńrò nípa Ọlọ́run, rò nípa òyeè rẹ nípa Ọlọ́run. Ṣé ó fídímúlẹ̀ nínú Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí ẹ̀dùn ìrírí rẹ tó ti kọjá?
Ní ọjọ́ díẹ̀ síwájú, a ó gbé àwọn àwòmọ́ Ọlọ́run wò láti inú Ìwé Mímọ́. Bí a se ńse àwárí wọn, bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wípé kí Ó túbọ̀ fi ara Rẹ̀ hàn sí ọ. Láìbìkítà, kíni àwọn ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ìrírí àwọn ọmọ lẹ́yìn Rẹ, tàbí bí ìrírí rẹ pẹ̀lú ìjọ ti se rí, mọ̀ wípé: Ọlọ́run àgbáyé ló dá ọ, ó fẹ́ràn rẹ, àti pé ó ń lépa rẹ̀ pẹ̀lú ìtara.
Gbàdúrà:Ọlọ́run, mo wá rí wípé ìwò mi nípa ẹnití O jẹ́ lé lórí àlàyé tí kò pé. Fi àwọn irọ́ tí mo ti gbàgbọ́ nípa Rẹ̀ hàn mí kí o sì rọ́pò wọn pẹ̀lú òtítọ́. Se àfihàn díẹ̀ sí nípa Rẹ̀ àti ìwà rẹ fúnmi lóní. Ní orúkọ Jésù, àmín.
Ìpèníjà: Fọwọ́sí ọ̀rọ̀ yìí: Ọlọ́run jẹ́_______. Kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bí o ṣe ńrò, lẹ́hìńnà wá àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ó tẹ̀le láti ṣe àtìlẹyìn fún wọn.
Nípa Ìpèsè yìí
Tani Ọlọ́run? Gbogbo wa l'a ní oríṣìríṣì ìdáhùn, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe leè mọ èyí tó jẹ́ òtítọ́? Irú ìrírí tí o ti lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn Krìstẹ́nì, àbí ìjọ látẹ̀hìnwá kò já sí nnkan kan - àsìkò tó láti mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe rí - gidi ni, Ó wà láàyè, Ó sì ṣetán láti bá ọ pàdé níbi tí o wà yẹn gan an. Gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Ètò Bíbélì Kíkà Ọlọ́jọ́ Mẹ́fà yìí tí ó tẹ̀lé ìwàásù Àlùfáà Craig Groeschel pẹ̀lú àkọlè, Ọlọ́run Jẹ́ ____.
More