Ọlọ́run jẹ́_______Àpẹrẹ

God Is _______

Ọjọ́ 4 nínú 6

Ọlọ́run Wà Níbí

“… ẹ mọ èyí dájú: Èmi wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, títí ó fi dé òpin ayé.”Mátíù 28:20

Ọlọ́run níi ní ọkàn láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ènìyàn ṣáájú, a sì ń rí èròńgbà yí di mímú ṣe ní oríṣiríṣi ọ̀nà ways over time.

Ní àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run gbé Ó sì ń rìn pẹ̀lú Ádámù àti Éfà nínú Ọgbà. Nígbàtí wọ́n ṣẹ sí Ọlọ́run, ó dá àjọṣe wa rú ṣùgbọ́n síbẹ̀, kò dá èrò Ọlọ́run dúró láti sún mọ wa.

Ọlọ́run Bàbá rán Jésù sáyé láti wá tún àjọṣepọ̀ wa àti Òun ṣe, àti pé Jésù nínú ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Rẹ̀ láyé, Ó ṣèlérí láti wà pẹ̀lú wa títí láé. Èyí tó tún dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ó ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ pé wọn yóò gba Ẹ̀mí Mímọ́, tí Yíò jẹ́ Ọlọ́run in us.

Tí a bá tẹ̀lé Kríístì, Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run Kò kàn wà pẹ̀lú wa—Ó wànínú wa. Nínú Májẹ̀mú Àtijọ́, àwọn ènìyàn ń ma ń lọ sínú tẹ́ńpìlì láti lọ ní ìrírí iwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, tí a bá ti gba Jésù, a di tẹ́ńpìlì tí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé.

Ní gbogbo àkókò yí, Ọlọ́run fẹ́ sún mọ́ wa, nípasẹ̀ Jésù, ó tún ti ṣeéṣẹ padà. Botilẹ̀jẹ́pé a ń fi ìtara dúró de ọjọ́ tí Ọlọ́run Yíò sọ ohun gbogbo di ọ̀tun kí á bàa lè gbe pẹ̀lú Rẹ̀ ní Ìjọba aláìní àbàwọ́n, a ò dúró bíi ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dilẹ̀ ní ìdúró di àkókò náà tí yóò ṣẹlẹ̀. Ọlọ́run ti fún wa ní iṣẹ́ láti ṣe.

Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ kí ènìyàn jọba lórí oun gbogbo tí a dá. Ó ti fún wa ní ẹ̀bùn àti iṣẹ́ láti ṣe fún Un nígbàtí a wà laye, nítorí náà ìgbàlà kìí ṣe owó ọkọ̀ sí ọ̀run—ó jẹ́ ìwé ìfipeni láti tẹra mọ iṣẹ́ àti mú ọ̀run di ẹ si wà sínú ayé.

Bí a sì ń ti n se bẹ́ẹ̀, a ò ní máa ṣe nínú agbára wa tí kò múná dóko. A ó ma bá Ọlọ́run dòwòpọ̀, ní ìdúróṣinṣin pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀ ninu wa láti ṣe ohunkóhun. Láìsí Ọlọ́run, a ò leè ṣe ohunkóhun, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run alààyè tí Ẹ̀mí Rẹ̀ si gbé inú wa, a lè se jù ohùn tí a lérò pé ó ṣe. éṣẹ ju yen lọ.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a ma ún rò pé Ọlọ́run wà jìnà réré ní ọ̀run, tó bẹ́ẹ̀ tí à ń pè É ní "ọ̀gà ńlá orí òkè.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà níbí.

Nígbàtí a bá sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa àti nínú wa, a lè tẹsíwájú nínú ète tí Ó ní fún wa—pínpín ìhìn réré Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn míràn nígbàtí a sì ń mú ọ̀pọ̀ ire Rẹ̀ wá sí ayé.

Gbàdúrà: Ọlọ́run, Ẹ ṣeun nítorí bí mo ṣe ń pe Jésù sínú ayé mi, Ẹ kò wà pẹ̀lú mi nìkan, ṣùgbọ́n nínú mi! Mo bèèrè pé kí Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ tọ́ mi Kí Ó sì darí mi ní gbogbo ọjọ́ yìí. Ẹ fi hàn mí bí mo ṣe leè mú púpọ̀ ìjọba Rẹ wá sì ayé, mo sì dúpẹ́ wípé Ẹ bá ènìyàn ṣiṣẹ́ pọ̀ láti ṣe ìfẹ́ Yín. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Yín, mo sì béèrè fún ìmọ̀lára tó gbòòrò sí wíwà pẹ̀lú wa Rẹ lónìí. Ní orúkọ Jésù, àmín.

Ìpèníjà: Bí o ti ṣe ń tẹ̀ sí wíwà Ọlọ́run pẹ̀lú wa lónìí, ṣe àkíyèsí sí ohunkóhun tí o rò pé Ẹ̀mí ń ru ọ́ sókè láti ṣe, lẹ́yìn náà béèrè fún ìgboyà láti ṣe é!

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

God Is _______

Tani Ọlọ́run? Gbogbo wa l'a ní oríṣìríṣì ìdáhùn, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe leè mọ èyí tó jẹ́ òtítọ́? Irú ìrírí tí o ti lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn Krìstẹ́nì, àbí ìjọ látẹ̀hìnwá kò já sí nnkan kan - àsìkò tó láti mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe rí - gidi ni, Ó wà láàyè, Ó sì ṣetán láti bá ọ pàdé níbi tí o wà yẹn gan an. Gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Ètò Bíbélì Kíkà Ọlọ́jọ́ Mẹ́fà yìí tí ó tẹ̀lé ìwàásù Àlùfáà Craig Groeschel pẹ̀lú àkọlè, Ọlọ́run Jẹ́ ____.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/