Ọlọ́run jẹ́_______Àpẹrẹ
Olódodo ni Ọlọ́run
Olúwa kọjá níwájú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ ara rẹ̀ báyìí pé, “Olúwa Ọlọ́run,aláàánú and ati olóore Ọlọ́run,ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ ní ìfẹ́, ati àánú ati òtítọ́ , Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.” Ekisodu 34:6-7 NIV
A ti gbé díẹ̀ lára àwọn àmúyẹ Ọlọ́run yẹ̀ wò, a sì tún leè rí àìmọye wọn nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n ní Ẹ́kísódù orí 34, Ọlọ́run ṣe àfihàn nnkan márùn nípa ara Rẹ̀ sí Mósè: Ó jẹ́ aláànú, olóore, Ó lọ́ra láti bínú, Ónífẹ́ àti olódodo sì nifaithful.
Níbi kíkà yíi kan náà, Ọlọ́run sọ fún Mósè pé Òun kìí jẹ́ kí ẹlẹ́ṣè lọ láìjìyà.Èyí bá ni lójiijì, àbí? Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ènìyàn Òun mọ̀ pé nítòótọ́ ni Òun jẹ́ onífẹ̀ àti olódodo tí Òun sì ń lọ́ra láti bínú … ṣùgbọ́n yóò fi ìyà tó tọ́ jẹ ẹni tí ó bá ṣẹ̀. Báwo ni a ṣe wá lè gbé ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìdájọ́ Rẹ̀ s'ẹ́gbẹ̀ ara wọn?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ọ̀nà kan péré l'a fi máa ń wó nnkan - bí kò bá ṣe dúdú á ṣe funfun. Ṣùgbọ́n a kò lè díwọ̀n Ọlọ́run. Kò kàn nífẹ̀ẹ́ nìkan - Ó tún jẹ́ olódodo, èyí ni kò ṣe lè jẹ́ kí ẹni tó bá jẹ̀bi lọ láìjìyà. Síbẹ̀ Ó tún jẹ́ aláàánú, èyí tó túmọ̀ sí pé bí ó bá tilẹ̀ fi ìyà jẹ àwọn ìran díẹ̀, Ó ń fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran.
Ìfẹ́ Ọlọ́run àti òdodo Rẹ̀ l'a rí nínú ìwé mímọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Wọ́n jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tó ń fi òtítọ́ Ọlọ́run hàn.
Ètò gbòógì tí Ọlọ́run ṣe láti jẹ́ kí á ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Òun bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìlérí tí Ó ṣe fún Ábráhàmù àti Sérà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì. Ó ní Òun yó bùkún gbogbo ayé nípasẹ̀ ìrandíran wọn-ìlérí tí ó di mímúṣẹ nípasẹ̀ Jésù.
Ṣùgbọ́n àwa ènìyàn gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tẹ̀ṣíwájú láti má ko ipa tiwa nípa ìbáṣepọ̀ yí. Nígbà tí Mósè ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn tó kù kò lè ní sùúrù mọ́, wọ́n pinnu láti máa tẹríba fún ère wúrà dípò Ọlọ́run. Síbẹ̀ nítorí ìsòtítọ́ Ọlọ́run sí ìlérí Rẹ̀, Ọlọ́run kò pa wọ́n run.
Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọ́n tẹ̀síwájú nínú àìgbọràn wọn tí wọ́n sì k'ẹ̀yìn sí Ọlọ́run gba ìjìyà wọn, ṣùgbọ́n Ó fún àwọn t'ó ronú pìwàdà ní ànfààní ọ̀tun.
Nínú gbogbo ọ̀nà míràn tí ènìyàn fi já Ọlọ́run kulẹ̀, Ọlọ́run jẹ́ olótìítọ́ síbẹ̀, àfihàn èyí tí a rí nípa pé Jésù mú ìlérí Ọlọ́run ṣẹ.
Nítorí náà, ní gbogbo ìgbà tí a bá kùnà, a lè sá padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ọkàn ọpẹ́ pé ìkùnà wa kò yí òtítọ́ Ọlọ́run láti dáríjì wá àti láti mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ padà..
Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún òtítọ́ Rẹ nípasẹ̀ Jésù àti nínú ayé mi. Nígbà tí mo jẹ́ aláìsòótọ́ tàbí tí mo kùnà, Ìwọ kò já mi kulẹ̀, mo sì yìn Ọ́ fún èyí. Là mí lójú láti lè rí iṣẹ́ tí òtítọ́ Rẹ̀ ń ṣe kí ìgbàgbọ́ mi kó sì ti ibẹ̀ dàgbà síi. Ní orúkọ Jésù, àmín..
Ìpèníjà: Ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àkókò tí o ti ní ìrírí òtítọ́ Ọlọ́run nínú ayé rẹ. Rò láti kọ wọ́n sílẹ̀ kí o lè máa gbé wọn yẹ̀ wò láti ìgbà dé ìgbà..
Nípa Ìpèsè yìí
Tani Ọlọ́run? Gbogbo wa l'a ní oríṣìríṣì ìdáhùn, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe leè mọ èyí tó jẹ́ òtítọ́? Irú ìrírí tí o ti lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn Krìstẹ́nì, àbí ìjọ látẹ̀hìnwá kò já sí nnkan kan - àsìkò tó láti mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe rí - gidi ni, Ó wà láàyè, Ó sì ṣetán láti bá ọ pàdé níbi tí o wà yẹn gan an. Gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Ètò Bíbélì Kíkà Ọlọ́jọ́ Mẹ́fà yìí tí ó tẹ̀lé ìwàásù Àlùfáà Craig Groeschel pẹ̀lú àkọlè, Ọlọ́run Jẹ́ ____.
More