Bíbélì Wà LáàyèÀpẹrẹ

La Biblia está viva

Ọjọ́ 6 nínú 7

Bíbélì A Máa Mú Ìrètí Wá

Ghana* jẹ́ ẹlẹ́sìn Musulumi tó nípọn nígbà kan rí kó tó ní àbápàdé agbára Jésù tó ń yí ni padà ní ọdún 2016. Àmọ́ lẹ́yìn tó di Kristẹni, àwọn ènìyàn kọ̀ọ́ sílẹ̀, wọ́n sì gba sẹ́gbẹ̀ nínú ẹbí àti ní àwùjọ. Ní àkókò kan, wọ́n gba àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ wọ́n sì fi wọ́n ṣọwọ́ sí orílẹ̀-èdè míràn.

Lóòótọ́ ni Ghana kọ̀ láti sẹ́ Jésù, àmọ́ ó ri wípé òhun kò ní ètò atinilẹ́yìn tí kò bá ràn án lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́. Nínú ìkárísọ àti ìdáwà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí ní gbèrò láti gb'ẹ̀mí ara rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn-ò-rẹyìn ó pàdé ẹnìkan tó bá a ṣe àkáálẹ̀ YouVersion sórí ẹ̀rọ ìléwọ́ rẹ̀. 

Ní àkọ́kọ́ Ghana kò ní ìwúrí, àmọ́ nígbà tó yá ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ká Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní ní ìdájí kí ó lé máa ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ àti fún ìtọ́ni bí ọjọ́ náà ti ń wọ́ lọ. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ohun tí a kò lérò ṣẹlẹ̀… 

“Àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì náà di ìyè wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé nínú mi. Wọ́n kọ́ mi bí a ti ń bá àwọn ènìyàn lò, wọ́n sì tú mi sílẹ̀ kúrò nínú ìkárísọ mi. Bí a tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀, ìtura a máa wá s'ọkàn mi nígbàkúùgbà tí mo bá kàá. Nígbàkúùgbà tí mo bá ka Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní, ó máa ń ru mí sókè, a sì máa fún mi ní ìrètí ní ọ̀nà pàtàkì kan tí n kò lè ṣàlàyé. Bí ìgbà tí Ọlọ́run fúnra Rẹ̀ bá ń bá mi sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì yí ló máa ń rí.”

Àǹfààní láti ṣe àfihàn Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní yí ni Ghana máa ń wá ní ibi gbogbo tó bá lọ. A máa ṣe àfihàn àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì wọ̀nyí lórí ìtàkùn ayélujára àti ìbánidọ́rẹ̀ẹ́, a sì máa sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́ àti oníbàárà rẹ̀ ní ibiṣẹ́. 

Ìtàn arábìnrin yí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àpẹrẹ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣe nínú gbogbo wa. Ìgbà lè yí padà, ìfẹ́ àwọn tó sún mọ́ ọ lè mẹ́hẹ, o lè kojú ìjákulẹ̀ tàbí ìkọ̀sílẹ̀—àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà síbẹ̀, kódà títí láé. Fún ìdí èyí, a lè ní ìrírí àlàáfíà àti ìrètí tó borí gbogbo ǹkan tí a lè ma là kọjá. Nítorí nígbà tí a bá gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàyè lóókan àyà wa, yóò máa wà níbẹ̀ títí.  

Lónìí, béèrè pé kí Ọlọ́run sọ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ di ìyè nínú ayé rẹ nípasẹ̀ gbígba àdúrà yí: 

Ọlọ́run, Ìwọ lo mọ mí, Ìwọ náà lo sì mọ̀ mí. Ìwọ nìkan ló ní agbára láti yí ayé mi padà. Fún ìdí yìí mò ń tọrọ wípé kí o mú ayé mi wà ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ohunkóhun tíì báà dojúkọ mí, fún mi ní ìgboyà láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kí n ba lè kéde òtítọ́ àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún àwọn tí O mú wá sọ́nà mi. Mú kí gbòǹgbò ìgbàgbọ́ mí kó máa rinlẹ̀ si bí mo ti ń sún mọ́ Ọ. Ní orúkọ Jésù, Àmín.

*A yí orúkọ ẹni tí ìtàn yí dá lórí padà láti bò ó láṣìírí.

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

La Biblia está viva

Ní àtètèkọ́ṣe, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń mú ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn bọ̀sípò—Ọlọ́run ò sì tíì parí iṣẹ́. Nínú Ètò pàtàkì ọlọ́jọ́-méje yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ agbára Ìwé Mímọ́ tó ń yí ìgbé-ayé ẹni padà nípasẹ̀ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà lo Bíbélì láti yí àkọsílẹ̀-ìtàn padà àti láti mú àyípadà dé bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.