Bíbélì Wà LáàyèÀpẹrẹ
Bíbélì Lu Ihò Sínú Òkùnkùn
Diya kò fẹ́ ní ǹkan kan láti ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn Kristẹni. Àmọ́ ní ọdún 2017, ọ̀rẹ Diya tímọ́tímọ́ sọ ọ̀rọ̀-ẹ̀rí rẹ̀ nínú ìjọ New Zealand tó tí n jọ́sìn. Diya yọjú láti gbárùkù tìí lọ́jọ́ náà … lẹ́yìn èyí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wá. Nígbà tí ọdún náà ma fi parí ó ti fi ayé rẹ̀ fún Jésù, ìyẹn kí ó tó kó lọ sí ìlú India.
Ìrìn àjò ìgbàgbọ́ ní ìlú tí kò ti sí àwọn Kristẹni púpọ̀ kò rọrùn rárá, èyí sì wá fa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn fún Diya débi wípé á máa nira láti dìde lórí ibùsùn ní òwúrọ̀.
“Mo máa ń dá nìkan wà àti pé kì í rọrùn fún mi láti bá àwọn ènìyàn ṣe. Lẹ́yìn tí mo rékọjá sí ìlú India ni mo pàdánù púpọ̀ nínú àwọn òmìnira tí mo ní tẹ́lẹ̀ rí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò ibi wá bẹ̀rẹ̀ sí ní lúgọ s'ọ́kàn mi. Àmọ́ kò rọrùn láti ṣe àyípadà àwọn èrò yí kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní lo Ìwé Mímọ́ lóríi YouVersion.”
YouVersion pèsè ọ̀nà àsọpọ̀ fún Diya láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni míràn àti láti kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn nípasẹ̀ àwọn Ètò Bíbélì. Wàyí láti ọdún 2018, ó ti parí ètò tó lé ní 428.
Nígbàkigbà tí Diya bá ní ìbéèrè, yóò sí ohun-èlò YouVersion rẹ̀ yóò sì ṣe àwárí àwọn Ètò tó dá lórí àkòrí náà. Bí ó sì ti ń ka àwọn Ètò síi, ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti ń gbèrú si.
“Lọ́jọ́ mìíràn mo máa bẹ̀rẹ̀ Ètò mọ́kànlá papọ̀ ní ìgbìyànjú láti ri ara mi bọ inú òtítọ́. Àǹfààní ló jẹ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tó ti là irúfẹ́ ìpèníjà wa kọjá àti jíjẹ àǹfààní ìgbani-níyànjú fún ìtẹ̀síwájú. Ó ti wá ń yé mi wípé n kò dá wà nínú ìtiraka mi. Mo lè kọ́ ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tó ti la ìrẹ̀wẹ̀sì re kọjá rí, èyí wá múu yémi wípé àwọn ọmọ lẹ́yìn Jésù pẹ̀lú a máa tiraka láti mú ìlera ọpọlọ wọn dúró déédéé.”
Ní báyìí, nígbàkúùgbà tí Diya bá ń ní ìmọ̀lára ìdáwà, ìrẹ̀wẹ̀sì, ó ti ní ìgboyà láti dúró lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run dípò àwọn èrò tó lè fẹ́ ṣe lòdì sí ọ̀rọ̀ Jésù nípa rẹ̀.
“Nígbà míràn, tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá dìde sí ọ, kìkì ọ̀rọ̀ kan lo nílò. Ohun-èlò Bíbélì náà jẹ́ ‘àbùjá’ èyí tó ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ si nípa Bíbélì àti ìgbàgbọ́ mi. Ìmọ̀-ẹ̀rọ jẹ́ irinṣẹ́ tó rọrùn láti mú ìmúgbòòrò bá ìgbàgbọ́ wá. M̀bá má sí níbí lónìí ká ní n kò wá àyè láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Kristi, nítorí àkókò náà kún fún òkùnkùn birimù Òhun sì ní orísun ìmọ́lẹ̀ kan ṣoṣo tí mo ní—tí ó sì wà síbẹ̀.”
Nítorí agbára tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìdáwà lè paradà sí ìdàpọ̀, a sì lè rí ìrètí nínú ìpọ́njú.
Gba ìtàn Diya rò, kí o sì wá àkókò láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ò ń làkọjá lọ́wọ́ lọ́wọ́. Bí o ti ń ṣe èyí, bèèrè pé kí Ọlọ́run ṣe àfihàn àwọn òtítọ́ nípa ohun tí ò ń làkọjá, lẹ́yìn èyí kí o wá ka Ìwé Mímọ́ fún àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí àti ìgbani-níyànjú Rẹ̀. Gba ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ láyè láti lu ihò sínú òkùnkùn ayé rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ní àtètèkọ́ṣe, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń mú ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn bọ̀sípò—Ọlọ́run ò sì tíì parí iṣẹ́. Nínú Ètò pàtàkì ọlọ́jọ́-méje yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ agbára Ìwé Mímọ́ tó ń yí ìgbé-ayé ẹni padà nípasẹ̀ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà lo Bíbélì láti yí àkọsílẹ̀-ìtàn padà àti láti mú àyípadà dé bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.
More