Bíbélì Wà LáàyèÀpẹrẹ
Bíbélì A Máa Ró Wa Lágbára
Fi ojú-inú wo bí yó ti rí bí o bá ń gbìyànjú láti ṣàlàyé fún ẹnìkan wípé ìtumọ̀ orúkọ èdè rẹ ni "àwọn oní bóto-bòto." Ǹkan tí ọ̀rọ̀ náà “Popoluca” túmọ̀ sí nìyẹn, òhun ni wọ́n sì ma ń fi ṣe àpèjúwe àwọn ènìyàn àti èdè ìlú Veracruz, ní Mexico.
Títí dòní, "Popoluca" ni a fi ń pe àwọn ènìyàn bíi ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ọgbọ́n tó ń sọ èdè yí lágbègbè náà. Àmọ́ àwọn tó ni èdè yìí gan a máa pè é ní “Nuntajɨ̱yi”— “Ọ̀rọ̀ tó Já Geere.”
Àwọn ènìyàn lè ti gbá èdè Nuntajɨ̱yi s'ẹ́gbẹ̀ẹ́, àmọ́ àwọn tó rí Májẹ̀mú Titun Bíbélì kà ní èdè yí mọ̀ dájú wípé Ọlọ́run kò gbàgbé àwọn. Carolina jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí. Òhun ni ọmọ-ọmọ ẹni tí ó ṣe ìtumọ̀ Májẹ̀mú Titun sí Popoluca, Carolina jẹ́ obìnrin Popolucan àkọ́kọ́ tí yóò kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Ifásitì, tó sì wá jọ̀wọ́ ayé rẹ̀ láti ṣe àfihàn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè abínibí rẹ̀, àti wípé ó ti darapò mọ́ ẹgbẹ́ kan tí ńṣe ìtumọ̀ bíi àádọ́ta nínú àwọn orin Dáfídì.
“Bí a bá ka Bíbélì ní èdè Spanish, bí ẹní pọnmi s'ókun ló máa ń rí. Àmọ́ nígbàtí a bá kàá ní èdè abínibí wa, tààrà ló ń lọ sí oókan àyà wa. A máa fọwọ́ tọ́ ọkàn wa—á sì ru wá sókè—nítorí ìtumọ̀ rẹ̀ yé wa yéké.”
Carolina jẹ́ olùkópa ní Àwùjọ YouVersion, ó sì ma ń lo YouVersion lóòrè kóòrè láti ṣe àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè Nuntajɨ̱yi.
“Inú wa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀ wípé ẹ ti fi èdè wa sínú ohun-èlò yín, nítorí káàkiri àgbáyé ni àwọn ènìyàn ti lè rí èdè wa báyìí, àti wípé èdè wa ti wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èdè tó lórúkọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú wò wá, àmọ́ nínú ohun-èlò yí, a ríi wípé èdè wa ní ìdíyelé tó dára.”
Lónìí, wá àkókò láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àǹfààní láti lè ka Bíbélì ní èdè abínibí rẹ. Lónìí, dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún Carolina àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún atúmọ̀ Bíbélì bíi rẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ káàkiri àgbáyé. Nítorí ìtara àti ìṣòótọ́ wọn, Ìwé Mímọ́ àti ìrírí agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tan káàkiri ìgbèríko àgbáyé, pẹ̀lú ìyípadà ìdánimọ̀ gbogbo ènìyàn tó ń gbọ́ ọ tó sì ní òye rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ní àtètèkọ́ṣe, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń mú ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn bọ̀sípò—Ọlọ́run ò sì tíì parí iṣẹ́. Nínú Ètò pàtàkì ọlọ́jọ́-méje yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ agbára Ìwé Mímọ́ tó ń yí ìgbé-ayé ẹni padà nípasẹ̀ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà lo Bíbélì láti yí àkọsílẹ̀-ìtàn padà àti láti mú àyípadà dé bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.
More