Bíbélì Wà LáàyèÀpẹrẹ
Bíbélì Ò Ṣeé Dá Dúró
Ní bíi ọdún ọgọ́rùn-ún méèdógún lẹ́yìn ikú Kristi, a kò tíì ní Bíbélì ní onírúurú èdè. Ìwọ̀nba àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlè tàbí tí ó lówó gidi ni ó lè kẹ́kọ̀ọ́ Hébérù, Gíríìkì, tàbí Látìn.
Ṣùgbọ́n ọ̀mọ̀wé kan tí à ń pè ní William Tyndale wòye wípé gbogbo ènìyàn ló yẹ láti lẹ́tọ̀ọ́ sí Ìwé Mímọ́. Fún ìdí èyí ó bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ rẹ̀ sí èdè abínibí rẹ̀: Gẹ̀ẹ́sì.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláṣẹ ló tako ìgbésẹ̀ yi àti àwọn ìgbàgbọ́ míràn tí Tyndale ní, fún ìdí èyí ó sá kúrò ní England, léyìn tó sì ṣe tán o fi ọgbọ́n kó àwọn Májẹ̀mú Tuntun wọlé pẹ̀lú rẹ̀ láì gba àṣẹ. Fún ọdún mẹsan ni Tyndale fi ńbọ lọ́wọ́ àwọn amúni tí ó sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìtumọ̀ Bíbélì Gẹ̀ẹ́sì àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn-òrẹyìn, ọwọ́ tẹ̀ ẹ́, wọ́n fẹ̀sùn ìsọ̀rọ̀-òdì kàán, wọ́n sì dáná sún (gẹ́gẹ́ bí ìjìyà).
Àmọ́ bí Ọlọ́run bá lọ́wọ́ sí ohun kàn—kò sí ǹkan náà tó lè dáA dúró.
Bí Tyndale ṣe jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ikú nípasẹ̀ iná fà ìdásìlẹ̀ ẹgbẹ́ abẹ́lẹ̀ tó ń bèrè fún àyípadà. Níwọ̀n bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn èyí, àyípadà ṣẹlẹ̀. Bíbélì ti Ọba Jákọ́bù ṣe agbátẹrù rẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì dé àrọwọ́tó—ẹ̀yà yí ṣe àmúlò púpọ̀ nínú àwọn ìtumọ̀ tí Tyndale ṣe nínú àtẹ̀jáde rẹ̀ àkọ́kọ́.
Lẹ́yìn àkókò di ẹ, Bíbélì fa àyípadà ńlá ní ìlú England. Isọjí ati ìtannijí bẹ sílẹ̀, awon ẹgbẹ́ ajihinrere ń dìde, ati àwọn àjọ tó fara jìn fún ìtúmọ̀ Bíbélì di gbígbé kalẹ. Ìwé Mímọ́ ta odindi ìlú jí—ṣùgbọ́n ìsọjí yi bẹ̀rẹ̀ nígbàtí àwọn aṣáájú atúmọ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan gbàgbọ́ pé gbogbo ènìyàn ló lẹtọ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run … wọn sì wá ǹkan ṣe nípa rẹ̀.
Báwo ní ìgboyà àwọn aṣáájú atúmọ̀ Bíbélì yí ṣe ṣí ọkàn rẹ payá?
Ní báyìí, ronú nípa àwọn ǹkan tí Tyndale là kọjá, lẹ́yìn náà, bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìṣíjú nípa ìgbésẹ̀ tó dájú bí ìwọ náà ṣe lè pín Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn tó yí ọ ká. Boya nípa pín pín ẹsẹ̀ kan sì ẹnìkan, tàbí fífi ara jìn sí ètò ìtúmọ̀ Bíbélì kan.
Bó ti lè wù kó rí, ronú nípa bí ayé rẹ ìbá ti rí ká ní o kò ní àǹfààní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorí náà gbìyànjú láti jẹ́ ìwúrí àti oun èlò fún àyípadà ayé ẹlòmíràn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ní àtètèkọ́ṣe, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń mú ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn bọ̀sípò—Ọlọ́run ò sì tíì parí iṣẹ́. Nínú Ètò pàtàkì ọlọ́jọ́-méje yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ agbára Ìwé Mímọ́ tó ń yí ìgbé-ayé ẹni padà nípasẹ̀ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà lo Bíbélì láti yí àkọsílẹ̀-ìtàn padà àti láti mú àyípadà dé bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.
More