Ìrìn-àjò HábákúùkùÀpẹrẹ

Habakkuk's Journey

Ọjọ́ 6 nínú 6

"Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Apá Kejì"

Èrò Òǹkọ̀wé:
1. Kíni kókó pàtàkì inú orí-ìwé yìí? Kókó pàtàkì ibẹ̀ ni ipá àti agbára Ọlọ́run.

Hábákúkùkù lọ láti ibi bíbá́ Ọlọ́run wí'jọ́ sí dídúró dè É àti lẹ́yìn ọ̀rẹyìn yínyin Ọlọ́run. Ó ní òye pé Ọlọ́run ní ètò àti pé Òun nìkan ni Ó lè mú ètò náà ṣẹ. Bí a ṣe ń lọ nínú ayé, a ó ṣe alábàpàdé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó wá ku s'ọ́wọ́ bí a ṣe pinnu láti ṣe ìkáwọ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run tí a sì ní ààyè láti yàn, a ní agbára láti ṣiṣẹ́ ní onírúurú ọ̀nà, sùgbọ́n bí ó bá dé ojú ọ̀gbagadì Ó ń wá kí a gbẹ́kẹ̀lé Òun.

Lọ́pọ̀ ìgbà Ọlọ́run a máa gba ìṣẹ̀lẹ̀ míràn láàyè láti kọjá agbára wa kí ó bà lè jẹ́ pé tí Ó bá mú wa padà bọ̀ sípò a ó lè mọ̀ pé Òun ni. Ìyẹn ni pé Ó ńṣe àfimúlẹ̀ ìfẹ́ Rẹ̀ sí wa, Ó sì ń rán wa létí pé nígbàtí ó bá jọ pé a dá nìkan wà, Ọlọ́run kò ì tíì, kò sì níí fi wá sílẹ̀ láíláí.

2. Kíni pàtàkì “selah” àti pé báwo ni a ó ṣe dáhùn síi?

Selah jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí ó ti ru èrò ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sókè. Òtítọ́ ibẹ̀ nipé kò ṣeéṣe kí a mọ ìtumọ̀ kíkún ọ̀rọ̀ yìí nítorípé kò sí aáyán ògbùfọ̀ rẹ̀ tààrà. Pẹ̀lú èyí lọkàn, àyẹwò kíkún tí wà fún gbogbo ibi tí a ti lo ọ̀rọ̀ yìí kí a ba lè ní òye ìtumọ̀ rẹ̀. Nítorínáà bí a bá fojú sun àwọn ibi tí a ti lo ọ̀rọ̀ yìí, ìgbàgbọ́ wà pé ìtúmọ̀ kannáà ni ó ní pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin, "fi kọ́.”

Bí a bá wòó báyìí, ìlò rẹ̀ dàbíi ìsinmi; ìdánudúró kúrò nínú ohun tí à ń sọ. Àkókò ìṣàrò nìyìí, gba ohun tí o kà sínú kí o sì ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ náà. Ohun pàtàkì ni à ń sọ ní àsìkò ìyìn yìí àti pé òǹkọ̀wé fẹ́ ríi dájú pé àkókò wà làti gbàá sínú ní kíkún.

3. Ronú padà sí kókó pàtàkì: Kíni Hábákúùkù ńgbìyànjú láti sọ fún òǹkàwé?

Hábákúùkù ní ọ̀nà tirẹ̀ ńgbìyànjú láti fi yé òǹkàwé pàtàkì níní òye ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Láti ní òye Ọlọ́run nínú ẹ̀kún ọgbọ̀n, agbára àti ìfẹ́ Rẹ̀, ni láti mọ ẹni tí o lè fi gbogbo ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sínú rẹ̀. Ó rọrún làti yiiri ohun tí Ọlọ́run ńṣe wò ó sì nira nígbàgbọ́ pé Ó mọ ohun tí Ó ńṣe ní pàtó. Gẹ́gẹ́ bíi ẹlẹ́ran ara, a kò ní ìmọ̀ àná, òní àti ọjọ́ iwájú, látàrí èyí, a kìí fẹ́ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ní wọn ní ìkáwọ́ Rẹ̀. Kò se àjèjì láti kọminú kí a sì ṣe àníyàn, ibi ni ìgbàgbọ́ yíò ti d'ẹ́sẹ̀ wọ̀lé. Ní ẹ̀yìn-ọ̀rẹyìn, Hábákúùkù parí ọ̀rọ̀ lọ́nà tó yẹ jùlọ:
18 Ṣùgbọ́n èmi ó ma yọ̀ nínú Olúwa, èmi ó ma yọ̀ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.
19 Olúwa Ọlọ́run ni agbára mi, Òun ó sì ṣe ẹsẹ̀ mi bíi ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín, lórí ibi gíga mi ni yíó sì mú mi rìn!

Ìfihàn ìjọ̀wọ́-araẹni àti ìgbàgbọ́ ni eléyìí. Hábákúùkù fi gbogbo ipa àti agbára Ọlọ́run hàn àti ìdí rẹ tí a lè fi gbẹ́kẹ̀le ni gbogbo agbọn ayé wa.

4. Báwo ni a ṣe lè mú eléyìí wá sí ayé òde-òní tí a sì lè ṣe àmúlò rẹ̀ ní ọjọ́ yé wa kọ̀ọ̀kan?

Ìdáhùn tó rọrùn ni láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run síi. Ẹnu èyí dùn r'òfọ́ l'ọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé bí a ṣe ń d'ojú kọ ìṣòro, a kọ́kọ́ maa ń d'ara dé ara wa ná, lẹ́hìn náà ni a ó wàá f'ojú s'óde. Nígbàtí a bá wáá ríi pé a kò lè ṣé fún ara wa, a ó wàá kó ara wa sí ìpayà dípò kí á sinmi ninu Ọlọ́run. Níní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kìí ṣe fún gbígbẹ́kẹ̀lée, ṣùgbọ̀n fún mímọ̀ pé yíò gbé ọ ró kò sì níí fi ọ́ sílẹ̀.

Ní báyìí, kí a padà sí ìbéèrè náà. Bí o ṣe ń wọnú ayé yíká, rántí pé àwọn ńkankan wà tí kò sí ní ìkáwọ́ rẹ àti pé èyí gan an ni Ọlọ́run wà fún. Kò sí ohun tí ó lè yọ́ bọ́rọ́ mọ́ Ọ lọ́wọ́, gbogbo ǹkan ni ó yíó dáhùn sí I. Gbìyànjú làti rántí Ìwé-Òwe 3:5:
Fi gbogbo àiyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ;

Ìpèníjà:
Àwọn ǹkankan wà ti mo fẹ́ pè ọ n'íjà sí nínú orí-ìwé yii. Làkọ̀kọ́, gbìyànjú ka Hábákúùkù 3 lẹ́ẹ̀kànsíi kí o sì d'ẹ́nu dúró làti ronú nípa ohun tí o n kà. Ronú nípa àbájáde ohun ti Hábákúùkù ń sọ fún wa nípa Ọlọ́run àti irú ẹni tí Ó jẹ́.

Èkejì, a ní láti ronú lójóojúmọ́ nípa ọ̀nà tí a ó fi máa ṣe àfihàn ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Ọlọ́run ní gbangba. Nígbàtí a bá d'ara dé E fún àwọn ǹkan kéèkèèké nínú ayé wa, yíò múu rọrùn láti d'ara dé E nígbàtí ohun ńla bá ṣẹlẹ̀. Ronú nípa Jákọ́bù 4:8:
Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, Òun yíò sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyè méjì!

Lo àsìkò díẹ̀ làti d'ara dé Ọlọ́run kí o sì wá A nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Tọ̀ Ọ́ lọ Òun náà yíò sì tọ̀ ọ́ wá. Ọlọ́run kìí kan 'ni nípà, kò sì nìí f'ipa mú ọ làti ràn ọ́ lọ́wọ́. Ìpinnu rẹ ni yíò jẹ́ làti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run kí o sì yọ̀ǹda ìfẹ́ rẹ fún Tirẹ̀. Nípa ṣíṣe èyí, o ó ri pé wàá kún fún àlàáfíà àti ìtùnú láti inú wá. A kò le gba àníyàn ayé ìsinsìnyi láti gba ọkàn wa kan kí ó sì mú wa jìnnà sí ìbàlẹ̀-ọkàn ti Ọlọ́run.

Bí a bá gba ọkàn wà láàyè làti rín kiri, yíó máa daríi wa. Ṣe ìkáwọ̀ èrò rẹ kí o sí gbée lé Krístì nígbà gbogbo, ìṣe rẹ yíò sì jọ Tirẹ̀.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Habakkuk's Journey

Ètò ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìrìn-àjò kọjá láàrin àkókò ìpèníjà Hábákúùkù.

More

A fẹ́ dúpẹ lọ́wọ́ Tommy L. Camden II fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://portcitychurch.org/