Ìrìn-àjò HábákúùkùÀpẹrẹ

Habakkuk's Journey

Ọjọ́ 4 nínú 6

"Dídúróde Ọlọ́run Apá Kejì."

Èrò Òǹkọ̀wé:
1. F'ọkàn sí ẹsẹ 1 fún ìgbà díẹ̀ kí o sì ronú nípa pàtàkì ẹsẹ yìí. Ṣe àlàyé èrò rẹ lórí èyí.

Hábákúùkù mọ ohun tí ó ń ṣe dunjú. Ó ń dúró de Ọlọ́run láti dá òun lóhùn, ṣùgbón kíni ìdí rẹ̀ tí ẹsẹ 1 fí ṣe pàtàkí? Ìdáhùn tó rọrùn ni pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ bí ó ṣe yẹ́ kí a dúró de ìdáhùn Ọlọ́run. Bí ó ṣe ń dúró de ìdáhùn, kò y'ẹsẹ̀. Èmi gẹ́gẹ́ bíi ajagun ojú-omi tẹ́lẹ̀ rí, mo mọ pàtàkì kí ènìyàn dúró sí ààyè rẹ̀ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ tìfura-tìfura.

Hábákúùkù kò kàn jókòó kí ó maa wípé màá gbé ìgbésẹ̀ ní kété tí mo bá ti rí ìdáhùn, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ó wípé èmi yíò dúró lórí ìṣọ́ mi gẹ́gẹ́ bí mo ti dúró làti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kókó mìráàn tó yẹ ká mọ̀ ni pé Hábákúùkù ń gbèrò ìdáhùn tirẹ̀ sí ìdáhùn Ọlọ́run. Ó ń gbáradì láti dá Ọlọ́run lóhùn l'ọ́nà kan ṣá.

Èyí rán mí létí ìpolongo ìbò kan. Nígbàtí adíjedupò kan bá ń dupò, wọ́n maá ń gbáradì fún àbájáde méjéèjì. Wọ́n máa ń ṣètò ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ tí gbígba àṣeyọrí àti ti gbígba ìjákulẹ̀ sílẹ̀. Èyí ńṣe àfihàn pé wọn ṣetán láti ṣ'ẹ́pá ṣ'ẹ́sẹ̀ fún alákóso yòówù tó ń da rí wọn. Fún àwọn olóṣèlú ààyò àwọn ènìyàn ní àmọ́ fún Hábákúùkù Ọlọ́run ni.

2. Báwo ni Ọlọ́run ṣe yàn láti dá Hábákúùkù lóhùn àti pé kíni èyí sọ fún wa nípa bí a ṣe níláti t'ẹ́tí sílẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí gbogbo wa ṣe mọ̀, ọ̀nà Ọlọ́run kìí ṣe bí a ṣe ń retí tàbí l'érò pé yíó jẹ́. Ọlọ́run pinnu láti sọ fún Hábákúùkù pé kí ó ṣe àkíyèsí àwọn ǹkan tí yíó ṣelẹ̀ l'ọ́jọ́ iwájú. Èyí máa ń le nígbà míràn. Ní ayé òde-òní ìgbádùn kánmọ́ńkíá ni à ńwá. À ńgbé ní ìran márosẹ̀ tó fẹ́ rí èsì kíákíá. A fẹ́ kí ojútùú wá ní kíákíá, ṣùgbọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà eléyìí kìí ṣe ohun tí ó dára jùlọ fún wa.

Ọlọ́run mọ èyí Ó sì lo àsìkò yìí láti jẹ́ kí Hábákúùkù mọ̀, mú sùúrù, ǹkan kìí rí bí wọn ṣe rí l'ọ́pọ̀ ìgbà. Ó lè dàbí ohun tí kò ṣeéṣe, ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ohun tí Ó ńṣe. A máa ṣòro láti mú sùúrù fún ènìyàn. Sùúrù ni kí ènìyàn mọ ìgbà tí yíò dúró àti ìgbà tí yíò gbé ìgbésẹ. Nígbà míràn sùúrù a máa tún sí kí a dúró kí Ọlọ́run ṣetán kí a tó pinnu láti gbé ìgbésẹ. Èyí ni Hábákúùkù fẹ́ ní ìrírí rẹ̀. Ó tó àkókò fún Ọlọ́run láti gbé ìgbésẹ̀ kí òun sí mú sùúrù.

3. Kíni o rò pé ó jẹ́ ìdí rẹ̀ tí Ọlọ́run fi lo ọ̀rọ̀ yìí "ègbé" nígbátí Ó ńbá Hábákúùkù sọ̀rọ̀ dípò ọ̀rọ̀ míràn bíi "ègún"?

Ègbé ni ọ̀rọ̀ tí à ńlò fún ìkáanú. Èyí jẹ́ ìpènijá fún òǹkáwé kìí sìí ṣe ọ̀rọ̀ gbogbogbòò. Ó rọrùn láti sọ pé, "wo gbogbo àṣeyọrí tí wọ́n ti ní, èmi náà ńfẹ́ kí nní irú rẹ̀." Ohun ti Ọlọ́run fẹ́ kí a mọ̀ ni pé àwọn tí a kà sílẹ̀ kìí ṣe àwọn tí ó ṣeé j'owú, bíkòṣe àwọn tí ó yẹ fún ìkáanú. Kìí ṣe l'ọ́nà tí a ó gbà jẹ́ onídàjọ́ wọn, ṣùgbọ́n l'ọ́nà tí a ó gbà láti ṣìpẹ̀ fún wọn. Ìgbé-ayé ẹ̀ṣẹ̀ kìí ṣe ohun tí à ńjowú.

Kapil Dev, oníbọ́ọ̀lù àfigigbá tẹ́lẹ̀ rí láti ìlú India, sọọ́ l'ọ́nà tó m'ọ́yànlórí pé, “Léyìnọ̀rẹyìn, mo gbàgbọ́ pé òdodo ló dára jú. Ènìyàn lè màa mú irọ́ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, òdodo a máa ṣ'àǹfààní.” Aláìsòdodo yíò máa k'àyà s'ókè ní gbogbo ìgbà pé àìsòdodo àwọn yóò padà s'órí àwọn, eléyìí kìí sì ṣe bí ó ṣe yẹ kí ènìyàn gbé ìgbé-ayé tí Ọlọ́run ti fi jíǹkí wa.

4. Báwo ni a ṣe lè lo èyí ní ìgbé-ayé wa ojoojúmọ́?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ló wà tí a ṣe lè ṣe àmúlò ohun tí orí-ìwé yìí ńkọ́ wa, ṣugbọ́n bóyá ọ̀nà tí ó dára jùlọ ní kí a mú sùúrù pẹ̀lú Ọlọ́run nítorípé kò gbàgbé rẹ. O kò le fi ipò rẹ nínú ẹ̀mí sílẹ̀ bí o ṣe ńdúró dé Ọlọ́run fún èsì sí ìbéèrè rẹ. Ọlọ́run pé nínú ohun gbogbo, kódà nínú àkókò tí yóò lò, bí a bá sì fi ipò wà nínú ẹ̀mí sílẹ̀ nígbàtí à ńdúró dè É, a kò sàn ju ọmọ-ọ̀dọ̀ onítáléntì kan lọ nínú Mátíù 25:24-26.

24 "Èyí tí o gba tálẹ́ntì kan sì wá, ó ní, Olúwa, mo mọ̀ ọ́ pé òǹrorò ènìyàn ni ìwọ ńṣe, ìwọ ńkórè níbití ìwọ kò gbé fúnrúgbìn sí, ìwọ sì ńṣà níbití ìwọ kò fẹ́ká sí.

25 Èmi sì bẹ̀rù rẹ, mo sì lọ pa tálẹ́ntì rẹ mọ́ nínú ilẹ̀. Wò ó, ǹkan rẹ nìyìí.'

26 "Olúwa rẹ̀ sì dáhùn ó wí fún u pé, Ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú àti onílọ́ra! Ìwọ mọ̀ pé èmi ńkórè níbití èmi kò fúnrúgbìn sí, èmi sì ńṣà níbití èmi kò fẹ́ká sí,
Jẹ́ olódodo nínú ohun tí Ọlọ́run ti fi fún ọ, Òun yíó sì bùkún fún ọ. Má pòǹgbẹ fún ohun tí oò ní, ṣugbọ́n nínú ohun gbogbo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹlẹdàá àgbáyé.

Ìpèníjà:
Lo àsìkò díẹ̀ lóòní làti ronú lórí ohun tí o ní àti bí o ṣe rí wọn gbà. Bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ kí o sì jẹ́ kí Ó mọ̀ pé o m'oore. Ìpèníjà tó ga jùlọ ni pé jẹ́ kí Ọlọ́run mọ̀ pé oó máa ṣ'ọ́nà bí o ti ń dúró dè É.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Habakkuk's Journey

Ètò ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìrìn-àjò kọjá láàrin àkókò ìpèníjà Hábákúùkù.

More

A fẹ́ dúpẹ lọ́wọ́ Tommy L. Camden II fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://portcitychurch.org/