Ìrìn-àjò HábákúùkùÀpẹrẹ

Habakkuk's Journey

Ọjọ́ 5 nínú 6

" Ìgbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run"

Ìfọkànsìn:
Gẹ́gẹ́ bí Krìstẹ́nì a máa ń sọ̀rọ̀ lórí ìfẹ́ Ọlọ́run a sì máa ń wo àánú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a máa ń gbàgbé wípé ìbínú ń bẹ pelu nínú ìfẹ́ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbéèrè tí ó wà níbẹ̀ ni wípé kíni ó ń mú wá gbàgbé? Ohun tí ó fi  fún wa jẹ́ ẹbọ ìfẹ́ tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó bo ìbínú Rẹ̀ mọ́lẹ̀. Òtítọ́ kan tí kò ní àbùlà tí ó sì tayọ; Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run òlódodo kò sì ní tú ìbínú rẹ̀ sì aiyé tí kò tọ́ sí àti wípé Ọlọ́run kìí ṣe àrankàn. Ìfẹ́ Rẹ̀ fún araíyé pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó máa ń yọrí sí pé kí Ó ṣe lòdì sí ohun tí òun tìkara rẹ̀
fẹ́.

Nígbà kan mo gbọ́ tí a bí apologist kan léèrè wípé , “ Bí Ọlọ́run bá fẹ́ wá tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, kí ni ìdí rẹ̀ tí ó fi ń rán àwọn ènìyàn lọ sí ọ̀run àpáàdì?” Ìdáhùn rẹ̀ sì ìbéèrè yìí ni ipa ìyípadà lórí bí mo tí ń rò ó tẹ́lẹ̀. Ní títúmo èsì rẹ̀, “ Wíwà ní ọ̀run àpáàdì jẹ́ wíwà ní ìpínyà pẹ̀lú Ọlọ́run àti wípé nínú èyí Ọlọ́run bù ọ̀wọ̀ fún òmìnira wá fún àṣàyàn. Bí ẹnikẹ́ni bá yàn láti jìnà sì í nígbà tí ó wà láyé, kò ní fi ipá mú wọn nígbà tí wón bá kú.” Àwọn ìtọ́kasí rẹ jẹ́ ìyàlẹ́nu nítorí ìwé 2 Pétérù 3:9 sọ fún wà wípé:

Olúwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣùgbọ́n ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo ènìyàn lè ronúpìwàdà.

Àwọn Ìbéèrè Àṣàrò:
Fi àkókò díẹ̀ ronú sì àwọn ìbéèrè wonyi kí ó tó tesiwaju. Ṣé ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yí pelu ọkàn tòótọ́ ni ípalẹmọ́ fún èrò ẹni tí ó kọ ìwé yìí lọ́la.

1. Kí ni ori ìwé yí rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lè lori?

2. Kí ni ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú gbólóhùn kan yí selah '' simi" àti wípé kini ìdáhùn tí a lè fun ú ?

3. Bí a bá ní èròngbaà padà lórí ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ wá: Kí ni Hábákúkù ń gbìyànjú láti jẹ ki awon akàwé mọ̀?

4. Báwo ni a ṣe lè gba èyí sínú ìgbé aiye ojoojúmọ́ wá?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Habakkuk's Journey

Ètò ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìrìn-àjò kọjá láàrin àkókò ìpèníjà Hábákúùkù.

More

A fẹ́ dúpẹ lọ́wọ́ Tommy L. Camden II fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://portcitychurch.org/