Ìrìn-àjò HábákúùkùÀpẹrẹ
"Pípádé Hábákúùkù Apákejì"
Èrò Òǹkọ̀wé:
1. Kókó wo ló jé jáde sí ọ jù nígbàtí o ka Hábákúùkù 1?
Kókó pàtàkì yìí wà níbẹ̀ "kílódé tí Ọlọ́run yíò fi gba ibi láàyè láti borí rere."
Ìbéérè yìí jẹ́ èyí tí ó sì jẹmọ́ ayé òde òní. Bí a bá wo ayé tí à ń gbé, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a maá ń bèèrè ìbéèrè yí. Ẹ̀wẹ̀, bí a ó bá s'òótọ́, ìbéèrè yíkò t'ọ̀nà. Ìbéèrè tódára jù ní; kíni Ọlọ́run ńṣe lààrin gbogbo aburú yìí?
2. Kíni ohun tí o rò pé ó jẹ́ kí ìwé yìí wọ àkójọ ìwé Bíbélì Kíni ohun tí o rò pé ó jẹ́ èrèdí tí Ọlọ́run ní fún orí ìwé yìí?
Nígbàtí mo ka èyí, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo ṣe àkíyèsí pé Hábákúúkù ń bi Ọlọ́run léèrè torí pé kò dá síi. Ipa méjì ni èrò mi pín sí: Àkọ́kọ́, ìgbésẹ̀ akin ni èyí, ẹ̀kejì, kílódé tó fi y'akin bẹ́ẹ̀?
Orí ìwé yìí gan an ni àfihàn oore-ọ̀fẹ́ àti ìfẹ́. Bíi Krìstíẹ́nì a mọ̀ pé Ọlọ́run ní agbára tó ga jù lórí ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ tàbí tí ó lè ṣẹlẹ̀. Ìyẹn nipé, o maà ń dàbíi pé à ń fi wèrè pé Ọlọ́run lẹ́jọ́ ni bí a bá ń wádìí ohun tí kò yé wa.
Èrèdí ìwé yìí nìyí. Kò sí ohun tí ó burú níbẹ̀ kí a ní àwọn ìbéèrè tí a fẹ́ bi Ọlọ́run. Ọlọ́run kò ní ní èrò pé kí a jẹ́ aláìlóyenínú tí yíò kàn màá tẹlé Òun bíi gọ̀ǹgọ̀sú kí a sì jẹ́ Krìstíẹ́nì bùúdàálẹ̀. Kò sí ohun tí ó burú níbẹ̀ kí bi Ọlọ́run léérè ìdí rẹ̀ tí ohun gbogbo fi rí bí ó ṣe rí àti pé kíni ohun tí Óń ṣe sí i. Ìdáhùn Rẹ̀ sí Hábákúùkù kìí ṣe l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́: kókó ibẹ̀ nipé Ọlọ́run mọ̀ pé ǹkan kò ṣ'ẹnuure, ṣùgbón ó wà n'íkàwọ́ Rẹ̀.
3. Kíni ẹ̀dùn ọkàn tí ó wà l'ákókò tí a kọ̀wé yìí?
Ogun abẹ́lé wà káàkiri. Orílè-èdè Ísráẹ́lì wà ní àkókò ẹ̀rù bí àwọn ara Bábílóònì ṣe ń l'ágbára sí i. Wọ́n ńyan kiri àwọn orílẹ-èdè wọn sí ń gba àkóso wọn. Ìsráẹ́lì fòyà pé àwọn ló kàn. Hábákúùkù wò yíkà àwọn orílẹ-èdè tó yí wọn ká ó sìń rí ìlọ́rọ̀ àti ìṣerere nínú ohun ìjà ogun orílè-èdè tí Ísráẹ́lì gbà pé ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀. Làti rí èyí àti láti mọ̀ pé Ísráẹ́lì wà ní àrọ́wọ́tó wọn àtinpé Ísráẹ́lì jẹ́ aláìṣòdodo tí ó jìnnà sí òdodo dé bii pé òfin Ọlọ́run ti di kíkọ̀ sílẹ̀ tí ó sì jẹ́ pé aburú ni ó ní èrè.
4. Báwo ni eléyìí ṣe kàn wà báyìí?
Ìran wa yìí tí dé ibi tí ó jẹ́ pé kò sí ìyàtọ̀ láàrin rere àti búburú. Òkè ti di ilẹ̀, olóńgìnní ti di ọ̀rẹ́ ajá, kí ló wáá tọ́? Bí a bá wò yíká, ìbéèrè a máa gbé wa l'ọ́kàn, ṣùgbọ́n ẹ̀rù ńbà wá. Fún àwọn kan, ẹ̀rù àti bèèrè ni àti fún àwọn ẹlòmíràn ẹ̀rù ìdáhùn ni. Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni wípé kí òye yé wa, kí a gbé ìgbésẹ̀ làti bèèrè, àmọ́ kí a mọ̀ pé ọwọ́ Ọlọ́run la wà àti pé Ó ní ètò fún wa. A ri pé ọ̀tá ńyan bọ̀ àti pé à ń gbógun ti àwọn Krìstíẹ́nì káàkiri ayé, ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ wà fún wa. Hábákúùkù jẹ́ àpẹẹrẹ agbára wa láti lè bá Bàbá wa sọ̀rọ̀ gbangba. Èbùn kan tí a rí gbà làti ọwọ́ Jésù ní pé a lè tọ̀ọ́ lọ tààrà nípa ohunkóhun, nígbàkùúgbà. Bá Bàbá rẹ sọ̀rọ̀ nítorípé gbogbo ìgbà ni ohun tí ó jẹ ọ́ l'ógún jẹ Òun náà l'ógún.
Ìpèníjà:
Ka Hábákúùkù lẹ́ẹ̀kan sí i kí o sì gbìyànjú làti rí i bí i ìrètí fún àwọn ohun tí ń bọ̀.
Nígbàtí Hábákúùkù kọ ìwé yìí, ó rí ọ̀nà ìparun àwọn ènìyàn àyíká rẹ̀, síbẹ̀ ó kọ̀ sinminlé ìwé-mímọ́ tí ó dàgbà nínú rẹ̀. Gẹ́nẹ́sísì 50:20 sọ wípé, ibi ni ẹ̀yín rò sí mi; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ̀ ọ́ sí rere, láti mú u ṣẹ, bí o ti rí lónìí lati gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là.” Ọ̀rọ̀ Jósẹ́fù sí àwọn arákùnrin rẹ̀ nìyìí. En tà á sí oko ẹrú nígbàtí wọ́n sì padà pàdé wọ́n bẹ̀rù ìgbẹ̀san, ṣùgbọ́n Jósẹ́fù kò sọ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nù nínú ètò Ọlọ́run. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ búburú gbogbo, ohun rere kan wà tí yíó tí ibẹ̀ yọ bí a kò tilẹ̀ rí i.

Nípa Ìpèsè yìí
Ètò ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìrìn-àjò kọjá láàrin àkókò ìpèníjà Hábákúùkù.
More
A fẹ́ dúpẹ lọ́wọ́ Tommy L. Camden II fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://portcitychurch.org/