Wá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀Àpẹrẹ

Seek God Through It

Ọjọ́ 1 nínú 10

Ìgbésí ayé wa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdojúkọ, fún àwọn kan, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wọn ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀. Láti ọmọ ọdún márùn-ún sí méjìdínlógún (5-18), èrò pé kí n gba ẹ̀mí ara mi, ìbínú, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti àníyàn bá mi fínra. Kódà lẹ́hìn ìgbà tí mo fi ọkàn mi fún Jésù, mo sì tún ja ìjàkadì pẹ̀lú àìní ìrètí.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwásù tí ó dá lé ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run ni mo gbọ́ tí wọ́n sì tù mí nínú ṣùgbọ́n wọn kò yí mi pádà. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ìwásù yẹn dàbí àjẹsára tí wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti la ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀ kọjá ni. Òkùnkùn, ìrẹ̀wẹ̀sì, àníyàn àti ìlàkàkà láti wà láàyè àti láti dáríjin ni ṣì wà síbẹ̀ digbí.

Mo máa ń ṣábà gbìyànjú fi ipá mú ara mi láti ní ìgbàgbọ́ kí n sì tún ṣe àtúpalẹ̀ ìyà tí ó ń jẹ mí. N kò fẹ́ jẹ́ Krìstẹ́nì oní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. Tẹ́lẹ̀ mo jẹ́ onírẹ̀wẹ̀sì ọkàn aláìgba Ọlọ́run gbọ́, nítorí náa, kò mú ọgbọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀wẹ̀sì ọkàn Krìstẹ́nì. (Mo lè dá búburú ṣe fúnra ara mi lol)

Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run ni mo tó rí i pé ó ṣeé ṣe láti ní àlàáfíà àti pé nínú Rẹ̀ ni ó sì wà.

Àlàáfíà Ọlọ́run jẹ́ ohun tí a máa ń dàgbà nínú rẹ̀ síwájú síi pẹ̀lú ìdarí ti È̩mí Mímọ́.

Mo gbàgbọ́ pé Jóòbù jẹ́ ẹnìkan tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ mọ́ tiwa jù tí ó bá di ọ̀rọ̀ ohun tí ó ba ni lọ́kàn jẹ́ tí ó sì mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn lọ́wọ́. Jóòbù jẹ́ ènìyàn tí ó sọ léraléra pé ìbá wu òun kí wọ́n má bí òun. Ìrírí ayé ti jẹ́ kí ó ronú pé kò yẹ kí ènìyàn wà láàyè. 

Njẹ́ o máa ń ní ìmọ̀lára pé nnkan búburú kàn máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ? Pé kò sí bí o ṣe mọ̀ ọ́n ṣe tàbí ṣe àìmọ̀ ọ́n ṣe tó, ilé ayé kàn ń tẹ̀síwájú láti pa ọ́ lára tàbí d'ójú tì ọ́ ṣá ni? Àsìkò yìí gan-an ni ó yẹ kí á wá Ọlọ́run, bí ó tilẹ̀ jé pé kò ní wù wá láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Gbà mí gbọ́, wíwá Ọlọ́run kò le tó bí a ṣe máa ń rò. Wíwá Ọlọ́run, rí gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí à ń wá ohunkóhun ni, ìfi ara jì ní ó gbà. Nígbà tí a bá wò pé nnkàn kan le, ó máa ń jẹ́ kí á ní ìrẹ̀wẹ̀sì láìṣe àní-àní, a kò sì ní lè fi ara jì.

Bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run pẹ̀lú èrò pé èmí yóò gbádùn èyí, yàtọ̀ sí èrò pé èyí kò ṣeé yí pádà.

Day: 1

  • Jọ́sìn fún Ọlọ́run ní gbàrà tí o bá jí kí ó sì jẹ ohun ìkẹhìn ní alẹ́. Bí o bá ṣe fẹ́ kí ó gùn sí wà lọ́wọ́ rẹ. Bí o ṣe ń jọ́sìn fi ọkàn rẹ sí ẹni tí Ó jẹ́.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Seek God Through It

Ìrẹ̀wẹ̀sì. Àníyàn. Àwọn okùnfà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ro ni lára máa ń ní ipa tí ó ní agbára lórí ọpọlọ, ìmọ̀lára àtì ìgbé-ayé ẹ̀mí wa. Ní àwọn àkókò yìí, wíwá Ọlọ́run á dàbíi pé ó ṣòro tí kò sì já mọ́ ǹǹkan kan. Èròńgbà ètò kíkà yìí, "Wíwá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀" ni láti gbà ọ́ ní ìyànjú àti láti kọ́ ọ ní ọ̀nà tí o fi lè ṣe ìtara níwájú Ọlọ́run, kí o ba lè ní àlàáfíà Ọlọ́run nínú irú ipòkípò tí o lè wà.

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ Brionna Nijah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.brionnanijah.com/