Wá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀Àpẹrẹ

Seek God Through It

Ọjọ́ 2 nínú 10

Oluwa rí ọ. Ó lè dà bí atenumo, amò kò ri bẹ, Ó rí ọ lóòótọ́.

Ó rí wa nígbà tí á a bá ń jìyà. Ó rí wa nínú ìrora, Ó rí ohun tó ń bà wá lẹ́rù, Ìjákulẹ̀ wa, ohun tá a fẹ́, ìjákulẹ̀ wa, ìbínú wa, ẹ̀rín rírùn wa, ẹ̀rín èké wa. Ọ rí gbogbo ìyá tí a tí mú móra. Ojú rẹ kò fọ, bẹẹ náà ni kò dì eti rẹ síi igbe wá.

Ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo fẹ́ràn jù lọ ni Sáàmùi 56:8 "Kọ ẹkún mi sílẹ̀; kó omijé mi sí ìgò rẹ, wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ."

Nígbà míì, mo máa ń fẹ́ láti tún ẹsẹ Bíbélì yẹn kà, kí n sì máa rán ara mi létí pé omijé mi kò já sásán. Pé Ọlọ́run ka àwa èèyàn sí ẹni tó ṣeyebíye pé omije wá ni wọ́n kó sínú ìgò, tí wọ́n sì kọ sínú ọ̀run.

Àní nígbà tí a kò bá lè sọ̀rọ̀, omijé wa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run nìkan ló lè túmọ̀. 

Nitori náà tí a bá ní wá ojú olorun, a kì í wá a kiri láti lè gba àfiyèsí rẹ̀, ṣùgbọ́n láti ipò tí a wà a ti ni.

A ti gba àfiyèsí rẹ̀. À ti wà nínú èrò rẹ̀.

Ó ṣeé ṣe láti ní àlàáfíà nínú rúkèrúdò.Mo mọ̀ pé ó lè dà bí ohun tó ṣàjèjì, àmọ́ ó ṣeé ṣe.

.Ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká mọ ẹni tó jẹ́ gan-an. A ò lè wá ẹni tí a kò mọ̀, a ò sì lè fọkàn tán ẹnì kan tá ò mọ̀.

Bí mo bá mọ̀, láìsí iyèméjì kankan, pé Ọlọ́run ni Olùpèsè—èyí tí yóò pèsè fún mi, mo sì lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn nínú ipò tí mo wà báyìí. Màá máa ṣe ìjọsìn àti àdúrà lọ́nà tó yàtọ̀. Mi ò ní kà á sí àṣẹ tí ìsìn pa fún mi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àǹfààní láti gba agbára padà, kí a sì tún kún inú àlàáfíà rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa sọ pé: Àmọ́ mo gbà pé Olùpèsè ni.

Ìdáhùn mi: Tá a bá gbà bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí á fi ń ṣàníyàn? 

Mi ò ní láti máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun tí mo mọ̀ pé ó wà ní sẹ́yìn. Ìgbà tí mi ò bá dá ara mi lójú nìkan ni mo máa ń ṣàníyàn.

Bí mo bá béèrè lọ́wọ́ ẹnì kan tí mo mọ̀ pé ó máa ṣe nǹkan kan fún mi lọ́nà tó tọ́ tó sì kúnjú ìwọ̀n, Mi ò ṣàníyàn. Mi ò ní í ṣàníyàn nítorí pé ẹni yìí ti fi hàn pé òun mọyì mi. Mo mọ̀ pé mo lè fọkàn tán wọn.

AMÒ.

Bí mo bá ní kí ẹnì kan tí èmi kò ní àjọṣe pẹ̀lú ṣe nǹkan kan fún mi, Mi ò mọ̀ bóyá wọ́n lè ṣe é ohun tí mò ń retí ni pé kí wọ́n lè ṣe é. Mo fi aiyé lè fún kí ohunkóhun kó ìdààmú bá mi.

Ọjọ2:

    Máa sin Ọlọ́run tọ̀sán tòru.
  • Máa ṣàṣàrò lórí irú ẹni tó jẹ́.
Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Seek God Through It

Ìrẹ̀wẹ̀sì. Àníyàn. Àwọn okùnfà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ro ni lára máa ń ní ipa tí ó ní agbára lórí ọpọlọ, ìmọ̀lára àtì ìgbé-ayé ẹ̀mí wa. Ní àwọn àkókò yìí, wíwá Ọlọ́run á dàbíi pé ó ṣòro tí kò sì já mọ́ ǹǹkan kan. Èròńgbà ètò kíkà yìí, "Wíwá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀" ni láti gbà ọ́ ní ìyànjú àti láti kọ́ ọ ní ọ̀nà tí o fi lè ṣe ìtara níwájú Ọlọ́run, kí o ba lè ní àlàáfíà Ọlọ́run nínú irú ipòkípò tí o lè wà.

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ Brionna Nijah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.brionnanijah.com/