Wá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀Àpẹrẹ

Seek God Through It

Ọjọ́ 7 nínú 10

A níílò àkókò ìdákẹ́jẹ́—àkókò láàrin àwa àti Ọlọ́run nìkan. Láàrin àkókò yìí, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àtúpalẹ̀ ọ̀rọ̀ Rẹ̀, kí a máa gbàdúrà, àti kí á máa jọ́sìn. Àwọn ǹǹkan wọ̀nyí kìí ṣe ohun tí "àwọn ará ilé-ìjọsìn maá ń ṣe" tàbí "àṣẹ ìsìn" tí ó le koko ṣúgbọ́n ó jẹ́ àǹfààní láti mọ Ọlọ́run nítòótọ́.

Mo fẹ́ tẹ ẹnu mọ́ àǹfààní nítorí pé àǹfààní gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ Ọ́.

Ronú nípa rẹ̀.

Ó mọ ohun gbogbo. Ó ní òye ohun gbogbo. Ọgbọ́n Rẹ̀ TÓBI. Ní iwájú Rẹ̀ nìkan ní àlááfíà pípé, ìmúláradá, àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wà. Nítorínáà kíni ìdí tí o kò ṣe lo àsìkò rẹ pẹ̀lú Ẹni tí Ó ń pèsè fún àìní wa tí ó ga jùlọ, èyí tíí ṣe àlááfíà?

Àkókò aláìnídîwọ́ lójoojúmọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run yíó yí ayé wà padà. A lè dàbíi Jésú nínú ọkọ̀, kí a sùn ní ìgbà tí wàhálà bá dìde yí wà ká..

Lo àkókò tí ó ní ìtumọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lónìí. Kódà gbìyànjú láti fikún àkókò tí wàá lò ní ọjọ́ mẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn. Wáá wò bí ọkàn rẹ àti àlááfíà inú rẹ yíó ṣe yípadà!

Ọjọ́ 7:

  • Gbàdúrà, kí o sì jọ́sìn ní àìsí ìdíwọ́.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6Ọjọ́ 8

Nípa Ìpèsè yìí

Seek God Through It

Ìrẹ̀wẹ̀sì. Àníyàn. Àwọn okùnfà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ro ni lára máa ń ní ipa tí ó ní agbára lórí ọpọlọ, ìmọ̀lára àtì ìgbé-ayé ẹ̀mí wa. Ní àwọn àkókò yìí, wíwá Ọlọ́run á dàbíi pé ó ṣòro tí kò sì já mọ́ ǹǹkan kan. Èròńgbà ètò kíkà yìí, "Wíwá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀" ni láti gbà ọ́ ní ìyànjú àti láti kọ́ ọ ní ọ̀nà tí o fi lè ṣe ìtara níwájú Ọlọ́run, kí o ba lè ní àlàáfíà Ọlọ́run nínú irú ipòkípò tí o lè wà.

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ Brionna Nijah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.brionnanijah.com/