Wá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀Àpẹrẹ

Seek God Through It

Ọjọ́ 5 nínú 10

Ǹjẹ́ o ti ní láti wakọ̀ rí lójú òjò tó ń rọ̀ gan-an tàbí lójú ọ̀gẹ̀dẹ̀? O gbọ́dọ̀ máa forí ṣe fọrùn ṣe kó o tó dé ibi tó ò ń lọ. Òjò àti ìkùukùu ò jẹ́ kó o rí ibi tó ò ń lọ. Nígbà míì, o lè dúró títí ìjì tàbí kùrukùru á fi rọlẹ̀.

Nígbà tá a bá ń wá Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ sapá láti borí àwọn ohun tó lè dí wa lọ́wọ́ nínú ìrònú àti nígbà míì, ká borí àwọn ohun tó lè dí wa lọ́wọ́ nípa tara. Wíwá Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà tá a gbọ́dọ̀ máa tọ̀, tá a sì gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Kì í ṣe ohun tá à ń ṣe lọ́nà àbínibí.

Ìrora ọkàn máa ń mú ká má lè wá Ọlọ́run, nítorí pé ohun tá a máa ń rí ni ìrora wa. A máa ń rí bí àwọn ìdílé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa ṣe ń fẹ́ ká ṣe ohun tí wọn ò fẹ́. A máa ń rí i pé ẹ̀dá inú wa ń dàwátì lábẹ́ ìnira àwọn ẹrù iṣẹ́ wa àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa.

Gbogbo èyí jẹ́ àwọn ohun ìdènà tó wà lọ́kàn wa tá a gbọ́dọ̀ borí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin aláìsàn ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ṣe borí àwọn èrò tó wà láàárín rẹ̀. Kì í ṣe pé èrò pọ̀ lọ́tùn-ún lósì nìkan ló ń dí èèyàn lọ́wọ́, ó tún ń dí èèyàn lọ́wọ́ láti ronú. A ní láti tẹ̀lé gbogbo iyèméjì nípa ara ẹni, iyèméjì nípa Ọlọ́run, àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe, ìdí tí èmi, àti púpọ̀lọpọ̀lọpọ̀ láti dé ibi ìmúpadàbọ̀sípò àti ìmúṣẹ tí Jésù pèsè. Bí èrò inú wa bá wà nínú òkùnkùn nípa ipò wa, báwo la ṣe lè rí ìmọ́lẹ̀?

Obìnrin yìí mọ̀ pé tóun bá fọwọ́ kan Jésù nípa ìgbàgbọ́, ara òun á dá. Kíkó wọn gba àárín èrò kò tó. Ìgbàgbọ́ tó ní ló mú kó wọlé, tó sì fọwọ́ kàn án, èyí ló mú kí ara rẹ̀ yá.

Nípa wíwá Jésù àti lílọ síbi tí Jésù wà, àwa náà lè rí ìmúpadàbọ̀sípò.

Ọjọ́ Karùn-ún:

  • Máa gbàdúrà kó o sì máa jọ́sìn.
Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Seek God Through It

Ìrẹ̀wẹ̀sì. Àníyàn. Àwọn okùnfà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ro ni lára máa ń ní ipa tí ó ní agbára lórí ọpọlọ, ìmọ̀lára àtì ìgbé-ayé ẹ̀mí wa. Ní àwọn àkókò yìí, wíwá Ọlọ́run á dàbíi pé ó ṣòro tí kò sì já mọ́ ǹǹkan kan. Èròńgbà ètò kíkà yìí, "Wíwá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀" ni láti gbà ọ́ ní ìyànjú àti láti kọ́ ọ ní ọ̀nà tí o fi lè ṣe ìtara níwájú Ọlọ́run, kí o ba lè ní àlàáfíà Ọlọ́run nínú irú ipòkípò tí o lè wà.

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ Brionna Nijah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.brionnanijah.com/