Wá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀Àpẹrẹ

Seek God Through It

Ọjọ́ 3 nínú 10

Ǹjẹ́ ohun gbogbo tí t'ojú sú ọ rí tí o sì sọ wípé, "Ọlọ́run, bí O kò bá ṣe èyí, mi ò rò pé mo le rùú là"?

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wíwá Ọlọ́run láàrin hílàhílo àti ìpọ́njú maá ń jọ bí ẹni pé ó ṣòro. Kódà nínú pé à ń gbìyànjú láti di ìgbàgbọ́ wa mú, a kàn maá ń ri pé ó ń bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́ ni.

É jẹ́ kí á wo obìnrin onísun ẹ̀jẹ̀. Ó ní ìsun fún ọdún méjìlá. Ó wà nínú ìrora fún ọdún méjìlá. Ó jìyà fún ọdún méjìlá. Mo wòye pé ó tilẹ̀ ti le gbàdúrà kí àwọn ẹlòmíràn náà sì ti gbàdúrà fún ùn fún ọdún mèjìlá.

Máàkù 5:26 sọ wípé ó jìyà ohun púpọ̀, ó ti rí ọ̀pọ àwọn oníṣègùn, ṣùgbọ́n àìsàn náà túbọ̀ ń burú sí i.

Èyí kò ṣe àjèjì nítorípé, fún àwọn kan, ó dàbí ẹni pé ìrora ọkàn àti àlékún ìrora ọkàn ni ayé ń mú wá fún wọn. Kò níí fi ṣe ẹni yòówù tí a lè bá sọ̀rọ̀—ẹbí, ọ̀rẹ̀, onímọ̀-ìṣègùn ọpọlọ, olùsọ́-àgùntàn—ìrora wà ń túnbọ̀ ń burú sí í ni.

Obìnrin yìí ṣe ìpinnu kan ní ọkàn rẹ̀. Ó gbàgbọ́ pé bí òun bá lè fí ọwọ́ kan ìṣétí aṣọ Rẹ̀, òun yíó di alára dídá ṣáṣá. Ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú wíwá kiri rẹ̀ ni ó mú u lára dá. Ó tẹ̀ síwájú láàrin èrò, láàrin ìrora rẹ̀, àti ìsun rẹ̀—láàrin ìrírí ìrora ọkàn rẹ̀—láti dé ọ̀dọ̀ Jésú.

Wíwá Ọlọ́run yíó mú wa dé ibi náà, kìí kàn ṣe ibi kan ṣáá, ṣùgbọ́n ibi NÁÀ tí ó jẹ́ ti ìmúpadàbọ̀sípò àti ìwòsàn.

Àwọn ohun kan wà tí olùsọ́-àgùntàn, ẹbí, àti onímọ̀-ìṣègún ọpọlọ kò lè mú kúró, yànjú tàbí mú dára sí i. Ọlọ́run nìkan ló lè mú èmi àti ìwọ di alára dídá ṣáṣá. Ẹwà tí ó wà nínú kí á wá A nìyìí.

Ọjọ́ 3:

  • Wá àsìkò láti jọ́sìn, kí o wá A nítòótọ́.
  • Ṣé àṣàrò lórí Máàkù 5:25-34
Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Seek God Through It

Ìrẹ̀wẹ̀sì. Àníyàn. Àwọn okùnfà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ro ni lára máa ń ní ipa tí ó ní agbára lórí ọpọlọ, ìmọ̀lára àtì ìgbé-ayé ẹ̀mí wa. Ní àwọn àkókò yìí, wíwá Ọlọ́run á dàbíi pé ó ṣòro tí kò sì já mọ́ ǹǹkan kan. Èròńgbà ètò kíkà yìí, "Wíwá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀" ni láti gbà ọ́ ní ìyànjú àti láti kọ́ ọ ní ọ̀nà tí o fi lè ṣe ìtara níwájú Ọlọ́run, kí o ba lè ní àlàáfíà Ọlọ́run nínú irú ipòkípò tí o lè wà.

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ Brionna Nijah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.brionnanijah.com/