Àìní Àníyàn fún OhunkóhunÀpẹrẹ

Anxious For Nothing

Ọjọ́ 6 nínú 7

Báwo ni ìbá ti rí tí o bá lè yin Ọlọ́run nínú ìpèníjà tó mú ìrora dání? Brian ní ìrírí àníyàn tó jẹyọ nípa ti ara. Àmọ́ nípasẹ̀ ìrírí rẹ̀, ó wá ri dájú wípé òhun ṣì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan láti yin Ọlọ́run fún: 

Mo kọ́kọ́ lu kúdẹ àìsàn àníyàn àti ìpayà ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn nígbà tí mò ń gbé ní ilẹ̀-àjèjì kan lákòókò tí mo ní ìpèníjà nínú ìgbésí ayé mi. Bí mo ti ń gbìyànjú láti kọ́ èdè titun, bẹ̀rẹ̀ okòwò, jẹ́ ajíhìnrere Kristi níbi tí ilé ìjọsìn ò ti pọ̀ lọ títí, àti títọ́ àwọn ìbejì ọlọ́dún kan, bí ìgbà tí mo bá sọ̀kalẹ̀ sínú kòtò òkùnkùn birimù ló ti rí. 

Láàárín oṣù díẹ̀, àyà bẹ̀rẹ̀ sí ní dùn mí, orí fífọ́ àti àwọn àìsàn míràn tó mú kí ẹ̀rù irú èyí tí kò bà mí rí bẹ̀rẹ̀. Kó tó di àkókò tí mò ń sọ̀rọ̀ rẹ yí, nkò ní ìpòrúru ọkàn lọ títí, tí n bá sì ma sọ òtítọ́, bíi akíkanjú ni mo ti ma ń wo araà mi. Àmọ́ láìpẹ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ro èrò búburú—pẹ̀lú ìdánilójú wípé ǹkan tó nípọn ń ṣe mí tàbí wípé ǹkan búburú kan ma dé bá ẹbí mi. 

Àwọn èèyàn bèrè bóyá ìṣẹ̀lẹ̀ àyíká, ìlera ara, tàbí ti ẹ̀mí ló fa àníyàn. Lẹ́yìn tí mo gbà á rò fúnra mi, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ wípé “bẹ́ẹ̀ni” ni èsì mi yóò jẹ́. Mo ní ìgbàgbọ́ wípé onírúurú ǹkan ló lè fà á. Wàhálà ní ọ̀nà tó ma fi ń ru tóbẹ̀ tí àwọn tó ní ìfaradà máa gbin lábẹ́ ẹrùu rẹ̀. 

Àti wípé, bíi àwọn àìlera ara tàbí àìsàn, àwa kan ní àkókò tí omi ara wa ma ń wà ní júuùju. Láfikún, àrékérekè ọ̀tá ẹ̀mí wa pọ̀ nípa ìkọlù, pẹ̀lú bí ó ti ma ń kọlù wá níbi tí a kùdíẹ̀ sí. 

Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù fi ránṣẹ́ nípa bí a ti lè borí àníyàn ní Fílípì 4:6-7, ó sọ wípé àdúrà nìkan kò tó láìṣe pé a ṣe ìdúpẹ́ pẹ̀lú. Ǹkan tó bí ìtọ́ni yìí kìí ṣe nítorí a borí tàbí nítorí ìṣẹ́gun ńlá kan. Kódà, Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ń kojú ìpèníjà nínú ayé rẹ̀. Ó kọ ìwé sí àwọn ìjọ Fílípì láti ọgbà ẹ̀wọ̀n láì mọ ilẹ̀ tí yóò mọ lóla. Síbẹ̀, ìwé rẹ kún fún ayọ̀ tó jinlẹ̀ àti ìhà ìdùnnú. 

Nítorí náà láàárín ìkorò, a sì lè máa fọpẹ́ f'Ólúwa. 

Ń kò gbàgbọ́ wípé Pọ́ọ̀lù ń tì wá láti ṣe ìdúpẹ́ tí kò ní òótọ́ nínú. Mo lérò wípé ṣe ni Pọ́ọ̀lù ń pè wá níjà láti máa ṣe ìdúpẹ́ nígbà tí ó yẹ, pàápàá nínú ìdojúkọ tí a bá ń là kọjá. 

Mo ti ṣe àkíyèsí wípé n kò lè wà láìní ìdí láti máa yọ̀. Kódà ní àwọn ìgbà tí ǹkan le koko, mo máa ń rí ǹkan ṣe ìdúpẹ́ fún. Ṣíṣe àṣàrò nínú àwọn ǹkan wọ̀nyí àti ṣíṣe ìdúpẹ́ sí ẹni tó yí ìrònú àti ìhà ọkàn mi padà. 

Dídi èrò búburú léra wa lórí ní gbogbo ìgbà lè mú kí èrò ìṣẹ̀lẹ̀ ibi máa wà lọ́kàn wa. Àmọ́ nígbà tí mo bá fi ìm'oore mi hàn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí ọ̀nà ìkóraàmi-ní-ìjánu, a máa ń yí èrò búburú yìí kúrò. 

Èyí kò túmọ̀ sí wípé ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí kan wà tí a fi lè k'ógo àníyàn já. Ṣùgbọ́n ètò ìyìn sí Ọlọ́run pàápàá nínú ìrora jẹ́ ọ̀nà sí níní ìwàláàyè Rẹ̀ pẹ̀lú wa, èyí tí yóò mú àlàáfíà wá. 

-Brian

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Anxious For Nothing

Kíni tí ọ̀nà míràn tí ódára jù báwà láti dojú ìjà kọ àwọn àníyàn tí kò lópin tí ó mú ọ ṣe àìsùn? Ìsinmi tòótọ́ wà—ótilẹ̀ lè súnmọ́ ju bí o ti lérò lọ. Fi àláfíà dípò ìjayà pẹ̀lú ètò bíbélì ọlọ́jọ́ méje yí láti ọwọ́ Life.church, tèlé ìfiránṣẹ́ àtẹ̀léra àníyàn fún ohuńkóhun ti àlùfáà Craig Groeschel.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ