Àìní Àníyàn fún OhunkóhunÀpẹrẹ
Jésù a máa bá wa pàdé láàárín àníyàn wa, kódà láìní ìmọ̀lára fún-un. Chelsea kọ́kọ́ ní ìrírí àníyàn ní kété tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè láti ilé-ìwé gíga. Ìtàn bí Ọlọ́run ti múu kúrò nínú òkùnkùn àti wá sí inú ìfọ̀kànbalẹ̀ ni èyí.
Ìmọ̀lára fún ìbẹ̀rù, ìdààmú ọkàn, àti ìkárísọ jẹ́ èyí tí kò ṣòro láti mọ̀. Tipátipá ni mo fi ń jẹun nítorí èébì olójojúmọ́. Wákàtí méjìlá ó lè ni mo fi ń sùn lójúmọ́, pẹ̀lú rẹ̀ ìjàkadì ni ó máa ń jẹ́ láti dìde lórí ibùsùn l'ówùúrọ̀. Inú ìrònú ni mo máa ń wà lọ́pọ̀ ìgbà tí mi ò ní sọ̀rọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Mo wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ ẹbí, dókítà, olùfọrọ̀lọ̀, Olusoaguntan, àti àwọn ọ̀rẹ́, àmọ́ bíi wípé àwọn ọjọ́ òkùnkùn yí kò ní wá sópin ló ti rí.
Gbogbo wa la ma ń ní ìrírí àwọn ọjọ́ òkùnkùn báyìí. Èyí tí ó lè fà fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan. Tàbí oṣù. Tàbí ọdún. Àmọ́ tí o bá mọ ìtàn Ọjọ́ Ẹtì Olóyin, ọjọ́ tí Jésù fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún tìrẹ, o mọ̀ wípé ìròyìn ayọ̀ lèyí, ọ̀rẹ́. Ọjọ́ Ẹtì náà dúdú, ṣùgbọ́n Ọjọ́ Àìkú ńbọ̀ pẹ̀lú ìṣẹ́gun!
A ní ìrètí nínú òkùnkùn, ìrètíi wa sì lórúkọ. Orúkọ Rẹ̀ ni Jésù.
Ní ọjọ́ tí mo ní ìrírí òkùnkùn tó rinlẹ̀ jù, ọjọ́ Ẹtì kan nínú Oṣù Kéje, Mo tiraka láti fà súnmọ́ Ọ bó ti ń súnmọ́ mi. Mo gbàdúrà wípé:
Jésù, ràn mí lọ́wọ́ láti kọ àwọn irọ́ ọ̀tá sílẹ̀.
Jésù, ràn mí lọ́wọ́ láti borí àníyàn ọkàn.
Jésù, ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́rìí wípé gbogbo ìṣàkóso wà ní ìkápá Rẹ
Jésù, ràn mí lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ wípé Ẹ̀míi nì tó jí Ọ láti ipò òkú ń gbé nínú mi.
Ọjọ́ méjì lẹ́yìn èyí, ní ọjọ́ Àìkú, àníyàn, ìpòrúru ọkàn, àti ìkárísọ di àwátì nígbà tí mo jí. Fún ìgbà àkọ́kọ́ lọ́jọ́ pípẹ́, mo ní àlàáfíà. Mo sì ní ìwòsàn ìyanu tó lè ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá.
Lákòókò àwọn ọjọ́ òkùnkùn, Jésù fún mi ní ìrètí. Kódà nígbà tí n kò ní ìmọ̀lára Rẹ̀, Ó wà pẹ̀lú mi. Ojojúmọ́ tí mo bá fi jìnà Si, ló fi ń fàmí padà wá sọ́dọ̀ ara Rẹ̀.
N kò mọ̀ bóyá ìrírí ọwọ́ ìyanu òjijì, bíi tèmi ni ìwọ náà yóò ní. Àmọ́ ohun tó dá mi lójú ni wípé Ọlọ́run ń bẹ pẹ̀lú rẹ nínú ìrora náà.
Gbogbo ìṣòro àwa ẹlẹ́ran-ara ló yé Jésù. Ó ní ìkáàánú. Ó káàánú wa tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọ̀run sílẹ̀ ó sì kú fúnwa láti lè borí gbogbo òkùnkùn ayée wa lẹ́ẹ̀kan náà.
Bíbélì sọ wípé: … Ẹ̀mí rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá fún gbogbo ọkàn. Ìmọ́lẹ̀ náà tàn nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì leè borí rẹ̀. Jòhánù1:4-5 NLT
Ọjọ́ Àìkú ńbọ̀.
-Chelsea
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni tí ọ̀nà míràn tí ódára jù báwà láti dojú ìjà kọ àwọn àníyàn tí kò lópin tí ó mú ọ ṣe àìsùn? Ìsinmi tòótọ́ wà—ótilẹ̀ lè súnmọ́ ju bí o ti lérò lọ. Fi àláfíà dípò ìjayà pẹ̀lú ètò bíbélì ọlọ́jọ́ méje yí láti ọwọ́ Life.church, tèlé ìfiránṣẹ́ àtẹ̀léra àníyàn fún ohuńkóhun ti àlùfáà Craig Groeschel.
More