Àìní Àníyàn fún OhunkóhunÀpẹrẹ

Anxious For Nothing

Ọjọ́ 3 nínú 7

Nje ibale okan see ni loni? Cheri lo ipakede odun mokanla s'ehin lati se iwadi. Eyi ni ohun ti o mu bo:

Mo ranti ni kedere. Ojo ti mo pinu pe mi o le maa gbe bayi lo.

Emi re, ọmọlẹhin Kristi olufọkansin ni kikun, to wa n fesi si isesi aye gege bii gbogbo eniyan miiran. Mo ngbe nnu ibẹru ati aibalẹ okan, sibẹ mo mọ pe ko yẹ ki o jẹ bee.

Ni ibamu nigbagbogbo mo ka ninu Ọrọ Ọlọrun lati maṣe bẹru ati lati ṣe aniyan fun ohunkohun. Ṣugbọn iyẹn dabi ẹni pe ko ṣee ṣe! Ọlọrun ni ohun pupo lati sọ ninu Bibeli nipa iberu ati egboogi rẹ: àlàáfíà. Ni apeere kan, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin Rẹ wa lori ọkọ oju-omi kekere ti o nkoja Okun Galili nigbati iji nla kan ha'lẹ lati rì wọn. Gbogbo wọn ja láti wà lójúfò, ati pe kini Jesu nṣe? O nsun wọra! Ninuu agbedemeji iji.

Awọn ọmọ-ẹhin beere, “Olukọ, iwọ ko fiyesi boya awa rì sinu omi?” Jesu dide, o ba iji na wi, o si dakẹ patapata. Lẹhinna O beere lọwọ awọn ọmọ-ẹhin pe, Kiniṣe ti ẹ fi bẹru bayi? Ṣe eo tii ni igbagbọ?” Máàkù 4:40 NIV

Iyẹn se konge akopọ awọn ọrọ ti mo nse pẹlu Ọlọrun. Mo ri lara wipe O n beere lọwọ mi idi ti mo fi bẹru, ati pe mo n dahun, Ṣe ko han gbangba ni? Wo awọn ayidayida mi! Tani yio kò tabi tani kò lé bẹru?

Ninu iwadi mi fun alaafia, ọpọlọpọ nkan han kedere.

  1. Ayidayida mi npinnu ipèlé alaafia mi. Ti ayidayida igbesi aye mi gbogbo ba dara, maa wa ni alaafia. Ti awọn iji ba yi mi ka, maa wa nnu wahala, aibalẹ okan, ati aarẹ ni gbogbo igba — yio rẹ mi lati awọn ero-inu mi wa. Mo dabi awọn ọmọ-ẹhin ninu iji. Mo bẹru iji, ipalara, ati idamu nitori mo ro pe Ọlọrun ko fiyesi. Ṣugbọn Jesu mu mi wa si ojuami ti o tẹle eyi.
  2. Jesu n'gbiyanju lati kọ mi pe alafia ṣee ni, laibikita iji. Ṣe o ni ibatan si ogun yii? Ko rọrun, abi? Mo ngbiyanju lati ni oye bi Jesu ṣe le reti ki n ni iriri alaafia ninu iji, mo nro boya Oun paapaa ò bikita, nigbana ni mo wa loye nípa àṣeyọrí mi ti ó kàn.
  3. Awọn iji mi ṣafihan ipele igbẹkẹle mi. Alafia ko tumọ si pe ohun gbogbo n lọ ni deede ni igbesi aye rẹ. O tumọ si pe o wa ni alaafia nigbati awọn iji n mì aye rẹ. Emi oi kọ ẹkọ lati gbẹkẹle Ọlọrun ati lati wa alaafia paapaa ninu awọn iji wọnyẹn. Njẹ o tíì sun kan ogiri yẹn?

O han gbangba pe mo ni aaye diẹ lati gbon si. Ṣugbọn mo n kọ ẹkọ na wipe ọna si alafia wa nipa gbigbekele ati fifi okan tó Ẹni ti awọn iji ko ni daamu. Ko ṣẹlẹ ni alẹ kan, ṣugbọn diẹ diẹ, alaafia diẹ sii ati isinmi tun ẹmi mi ti o rẹwẹsi ṣe.

-Cheri

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Anxious For Nothing

Kíni tí ọ̀nà míràn tí ódára jù báwà láti dojú ìjà kọ àwọn àníyàn tí kò lópin tí ó mú ọ ṣe àìsùn? Ìsinmi tòótọ́ wà—ótilẹ̀ lè súnmọ́ ju bí o ti lérò lọ. Fi àláfíà dípò ìjayà pẹ̀lú ètò bíbélì ọlọ́jọ́ méje yí láti ọwọ́ Life.church, tèlé ìfiránṣẹ́ àtẹ̀léra àníyàn fún ohuńkóhun ti àlùfáà Craig Groeschel.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ