Àìní Àníyàn fún OhunkóhunÀpẹrẹ

Anxious For Nothing

Ọjọ́ 2 nínú 7

Tí o bá ṣe pé àníyàn lè mú ọ sún mọ Jésù si ńkọ́? Jordan lo ọdún kan gbáko láti gbàdúrà kí àníyàn rẹ̀ lọ títí tó fi ṣàwarí ohun tó tún jinlẹ̀ — ìbáṣepọ̀ tó lókun pèlú Jésù. Bóyá ìtàn yí lè yé ọ:

“Mo rò pé mo má kú.”

Ìyẹn gan-an ni ohun tí mo rò mo ara mi ni òpò ìgbà àìlesùn ní ọdún tó kọjá. Mo gbìyànjú láti sún, fún mi láti jí lójijì láì nìdí kan pàtó. Àyà mi gaa. Mo nímọ̀lára pé mo ń ṣé èémí, àti pé mi kò lè mí nígbà mìíràn. Èyí ṣẹlẹ̀ léraléra títí mofi pinu láti máa sún sórí àga kí n ba lè dẹ́kun àti ma jí ìyàwó mi lóru.

Lọ́jọ́ kan, mo lọ sọ́dọ̀ dọ́kítà mi láti ṣàlàyé àwọn—ìrora, àìrórunsùn, àti ìpayà ọkàn. Lẹ́yìn àwọn àyẹwò mélò kan, o ri wípé mo ní àníyàn. Ṣé mo lè sọ òtítọ́? O mú mi dà bí Kristẹni tó tí kùnà. Ṣé mo ti ma ń gbàdúrà lòdì sí èyí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Kò yẹ kí n ma bá èyí jijàkadì, mo máa ń ro sí ara mi, ó yẹ kí n ní àlàáfíà kìí ṣe àníyàn lo yé kí n ní—ohun tí Jésù ní kí a ṣe nìyẹn!

Léyìn tí mo tẹ̀lé àwọn ìmọ̀ràn dókítà náà ti mo bẹ̀rẹ̀ sí ní lo oògùn díẹ̀ díẹ̀, mo tẹ̀síwájú láti gbàdúrà kí àníyàn kúrò. Mi kò fẹ́ tiraka pẹ̀lú rẹ̀ mọ́.

Ní Kọ́ríńtì Kejì 12 (NIV), Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe "ẹ̀gún nínú ara" rẹ̀. Nígbà tí a kò mọ̀ dájú ohun tí "ẹ̀gún" tí Pọ́ọ̀lù sọọ́ jẹ́ àmó àníyàn lè dá báyìí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn pèlú èmi náà. Pọ́ọ̀lù sọ wípé òun bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta , láti mú kúrò, àmọ́ dípò rẹ̀, Jésù sọ fún un Òòrè Ọfẹ mi tó fún ọ , nítorí a ṣe agbára ní pípé nínú àìlera.” (àfikún wà níbẹ̀)

Òòrè ọfẹ Jésù tó, ní ipò kí pò tí a bá wà. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní gbàdúrà fún ìwòsàn, Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ Jésù sí. Bíi Pọ́ọ̀lù, Olórun kò tíì mú “ẹ̀gún” mi kúrò. Àmọ́, mo ri wípé ìwúrí mi láti máa ka Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ti pọ̀si, mo sì ti ń gbàdúrà ju àtẹ̀yìnwá lọ.

Mo rò pé ohun tí mo nílọ̀ ní ìwòsàn fún àníyàn mi. Àmọ́, ṣe ni mo nílò Jésù ní ọ̀pọ̀ yanturu. Nísìsiyìí, Mi kò sọ pé tí mo bá tí súnmọ Jésù tẹ́lẹ̀ n kò ní ní àníyàn. Mi kò ní dẹkùn láti máa gbàdúrà pé kí àníyàn kúrò. Mo tèsíwájú láti máa gbàdúrà kí a gbà mi là lọ́wọ́ ẹ̀gún bíi Pọ́ọ̀lù ṣe gbàdúrà

Àmọ́ ohun kan tó tún dára tún ṣẹlẹ̀ sí mi jù ìwòsàn lójú ẹsẹ̀ látọwọ́ àníyàn: mò ń ní òye tó gbèrú síi tó sì jinlẹ̀ nípa Olórun àti ìbáṣepọ̀ tó dára pẹ̀lú Rẹ̀.

Dípò gbígbàdùrá fún àlàáfíà, Mo rí ara mi tó ń sún mọ́ Olórun Aládé Àlàáfíà. Nígbà tí mo bèrè sí ní ṣàníyàn nípa ojó iwájú mi, Mo rán ara mi létí pé Òun ní Alpha àti Omega— ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, àkọ́kọ́ àti ìkẹyìn.

Mo gbàdúrà kí àníyàn mi lọ, àmọ́ mo rí nǹkan kan tó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ: èyí tí ó ya ni lẹ́nu, ni ìwàláàyè Jésù nínú ayé mi— pàápàá láàrín àníyàn.

-Jordan

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Anxious For Nothing

Kíni tí ọ̀nà míràn tí ódára jù báwà láti dojú ìjà kọ àwọn àníyàn tí kò lópin tí ó mú ọ ṣe àìsùn? Ìsinmi tòótọ́ wà—ótilẹ̀ lè súnmọ́ ju bí o ti lérò lọ. Fi àláfíà dípò ìjayà pẹ̀lú ètò bíbélì ọlọ́jọ́ méje yí láti ọwọ́ Life.church, tèlé ìfiránṣẹ́ àtẹ̀léra àníyàn fún ohuńkóhun ti àlùfáà Craig Groeschel.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ