Àìní Àníyàn fún OhunkóhunÀpẹrẹ
Lórí Eré
Ìgbésí ayé àníyàn dà bí ìgbà tí èèyàn bá ń gbé lórí eré—àyàfi tí o bá ń sára fún ayéè rẹ. Ìpayà yóò gbilẹ̀ s'ọ́kàn rẹ bí o ti ń gbìyànjú láti sá lọ síbi tí o ti lè fara soko. Ìpòrúru yóò gba ọkàn rẹ kan tó bẹ́ẹ̀ tí yóò nira láti mí, ẹ̀rù yóò wá máa jẹyọ, tí yó sì fa iyèméjì.
Ṣé èyí jọ ǹkan tí o gbọ rí? Ipá kan wà tí máa mu kó nira láti ní ìsinmi—ímeèlì ò ní dáwọ́ dúró, bẹ́ẹ̀ni ìkànsí-ni orí ẹ̀rọ alágbèéká kònípẹ̀kun, má sì ṣe gbàgbé kòtò ìfiwéra tí ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ máa ń múni jìn sí. Báwo ni a ó ti k'ógo èyí já, ní ìrántí wípé ọmọ lẹ́yìn Jésù ni a jẹ́, a sì ti pè wá láti gbé ìgbé ayé tí kò ní àníyàn?
Lọ́pọ̀ ìgbà ni ẹ̀bi ma ń rẹ̀ wá sílẹ̀ nítorí a lérò wípé kò yẹ kó rí báyìí.
Ṣùgbọ́n tí a bá gbìyànjú láti má sàá fún ǹkan kí a sì máa sáré lọ sọ́dọ̀ ẹnìkan?
A lè ṣeé. Ìwọ lé ṣeé. Ìlérí wípé a lè gbé láìní àníyàn fún ohun kan kò dá lórí ǹkan tí a lè ṣe bíkòṣe lórí ìwàláàyè Ọlọ́run. Ṣe àgbéyèwò ǹkan tówà ní Fílípì 4:6-7 NIV:
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkohun dààmú yín, ṣugbọn ninu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ yín, ẹ máa fi àwọn ìbéèrè yín siwaju Ọlọrun pẹlu ọpẹ́. Alaafia Ọlọrun, tí ó tayọ òye eniyan yóo pa ọkàn ati èrò yín mọ́ ninu Kristi Jesu.
Nípa ìgbìyànjú tiwa, a kò lè ja àjàbọ́ lọ́wọ́ àníyàn. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run? A ní àǹfààní sí ìwàláàyè Rẹ̀, tí yóò fúnwa ní àlàáfíà tó kọjá òye.
Kí ni ǹkan tí a lè sọ pé ó tún níyì ju ìlérí náà? Ìṣísẹ̀ tó ń tẹ̀síwájú ni. Ní gbogbo ipò. Ní gbogbo ìgbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ní àníyàn lọ́kàn, a lè tọ Ọlọ́run lọ fún àlàáfíà nítorí àlàáfíà Rẹ̀ ma ń ṣú yọ látinú ìwàláàyè Ọlọ́run.
Lọ́pọ̀ ìgbà àníyàn ò ní pòórá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́sẹẹsẹ, tí a fi ń wá Ojú Ọlọ́run ni. Ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ tó ńbọ̀, a máa ṣe àfihàn ìtàn àwọn ènìyàn tó bá àníyàn jìjàkadì pẹ̀lú àwọn ǹkan tí wọ́n rí kọ́ nínú ìlà kọjá náà.
Ṣé o nífẹ̀ẹ́ láti kọ́ síi nípa gbígbé Láìní Àníyàn Kan ? Ṣe àgbéyèwò àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú tó bá ètò yí wá láti lè ṣàwárí àlàáfíà síi.
*Tí àìní-ìbàlẹ̀-ọkàn bá ń bá ọ fíra, ó ṣe pàtàkì láti bèrè fún ìrànlọ́wọ́ tí o nílò. Tí o bá ń fura wípé àìsàn àníyàn tí kò nídìí ń bá ọ jà, kàn sí dókítà rẹ. Bíbéèrè fún ìrànlọ́wọ́ kò túmọ̀ sí wípé o ya ọ̀lẹ; ṣeni yóò tún mú ọ gbọ́n síi.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni tí ọ̀nà míràn tí ódára jù báwà láti dojú ìjà kọ àwọn àníyàn tí kò lópin tí ó mú ọ ṣe àìsùn? Ìsinmi tòótọ́ wà—ótilẹ̀ lè súnmọ́ ju bí o ti lérò lọ. Fi àláfíà dípò ìjayà pẹ̀lú ètò bíbélì ọlọ́jọ́ méje yí láti ọwọ́ Life.church, tèlé ìfiránṣẹ́ àtẹ̀léra àníyàn fún ohuńkóhun ti àlùfáà Craig Groeschel.
More