20/20: A Ti Rí. A Ti Yàn. A Ti Rán. Nípasẹ̀ Christine Caine Àpẹrẹ

ỌLỌ́RUN RÍ Ọ
Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún Sámúẹ́lì pé, "máṣe wo ojú rẹ̀, tàbí gíga rẹ̀; nítorípé Èmi kọ̀ ọ́: nítorítí Olúwa kìí wò bí ènìyàn ti ń wò; ènìyàn a máa wo ojú, Olúwa a máa wo ọkàn.” -1 Sámúẹlì 16:7 YBCV
Ní ìrìn-àjò kan ní odún púpọ̀ sẹ́hìn, mo lọ ra kọfí kí ìdílé wa tóó tẹ bàlúú létí. Nick lọ ṣáájú pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wa láti fi wọ́n l'ára balẹ̀. Nígbàtí mo padà dé ẹnu ìloro, mo bẹ̀rẹ̀ síí kọjá láti ìdíkọ̀ sí ibi afárá jẹ́ẹ́tì, ni òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú kan bá wò mí sùn-ùn ló bá wípé, “Ẹ ò níbi í lọ o màdáámú.”
Ẹnu yà mí, mo bá bèèrè pé kílódé.
“Hẹn-ẹn, bí o bá ní àsìkò láti lọ ra kọfí, a jẹ́ pé o kò ní àsìkò láti wọ inú bàlúù nìyẹn.”
Ẹnu yà mí gidi. Ohun tó sọ kò m'ọ́gbọ́n dání. Mo mọ̀ pé àsìkò láti w'ọnú ọkọ̀ kò ì tíì kọjá. "Ilẹ̀kùn ṣì wà ní ṣíṣí arábìnrin. Jọ̀wọ́, gba ìwé ìwọkọ̀ mi kí o jẹ́ kí ń w'ọkọ̀.”
Kò mà dáhùn.
“Màdàámú, ọkọ mi àti àwọn ọmọ ti wà nínú ọkọ̀,” mo wí bẹ́ẹ̀ fún un. “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n w'ọkọ̀.”
Kò tilẹ̀ mi'ra pẹ́kẹ́.
Mo rántí pé mo dàbí aláìlágbára, t'ẹ́nu yà mí gan an, bí ẹni pé mi ò já mọ́ ǹkànkan. Kò tilẹ̀ wò mí ṣe láàánú, kò bìkítà pé òún yà mí nípa pẹ̀lú ẹbí mi. Ó ń wò mí, ṣùgbọ́n kò rí mi.
Ẹ̀yìnọ̀rẹyìn mo wọnú ọkọ̀ bàlúù, ṣùgbọ́n mi ò tíì gbàgbé ohun tí obìnrin yẹn mú mi rí. Àti síbẹ̀, mo mọ̀ pé lọ́pọ̀ ìgbà ni mo ti hùwà bíi tirẹ̀ ju kí n hùwà bíi Jésù lọ—nígbàtí mo wò, sùgbọ́n tí mi ò rí. Báwo ló ṣe rọrùn fún wa tó láti má náání agbọ́únjẹ tó ń dá wa lóhùn níle oúnjẹ, aṣaralóge nínú ṣọ́ọ̀bù tàbí akọ̀wé ní ilé-ìtajà. Báwo ló ṣe wọ́pọ̀ tó láti má a ranjú mọ́ ẹ̀rọ-ìléwọ́ wa kí a sì gbàgbé láti lu òṣìṣẹ́ tí ó ń gbọ́ tiwa l'ọ́gọ ẹnu? Bíi ìgbà mélòó ni àwa náà tí f'ojú réénà ẹlòmíràn?
Wíwò kìí ṣe ohun kannáà pẹ̀lú rírí. Obìnrin ẹnu ìloro yẹn wò mí, ṣùgbọ́n kò rí mi. Ó tẹ'jú mọ́mi, ṣùgbọ́n kò níran tàbí kó ní òye ohun tí mò ń là kọjá.
Ọlọ́run fẹ́ kí a wò kí a sì rí! Ó fẹ́ kí a rí àwọn ẹlòmíràn bí Òun ṣe rí wọn—pàápàá bí ó ba kan rírí àwọn tí wọ́n ń bá wa pàdé lójoojúmọ́.
ÀDÚRÀ
Baba ọ̀run, sí ojú ọ̀kàn mi kí n lè rí àwọn ènìyàn, kí n sì má f'ojú réénà ẹnìkankan mọ́. Ràn mí lọ́wọ́ láti mú àwọn tí ó wà l'áyìká mi jẹ́ rírí, kí wọn di mímọ̀, jẹ́ gbígbọ́, kí wọ́n jẹ́ ẹni iyì àti ẹ̀yẹ. Lo ẹ̀kọ́ yìí láti fi hàn mí bí mo ṣe lè dàgbàsókè láti rí àwọn ẹlòmíràn dáadáa jù ti tẹ́lẹ̀ lọ, láti rí wọn gẹ́gẹ́bí O ti rí wọn. Ní orúkọ Jésù, àmín.
Àdàkọ láti inú 20/20: Seen.Chosen.Sent láti ọwọ́ Christine Caine. Copyright © 2019 by Christine Caine. Àtúntẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Lifeway Women. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni tiwa.
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o le fi ojú inú wòó bí yíò ṣe rí kí Ọlọ́run rí ọ lọ́nà tí ó jẹ́ wípé ìwo gan ò lè má ṣe aláìrì àwọn ẹlòmíràn? Ṣé o le fi ojú inú wòó wípé lójoojúmọ́, kí ìgbésí ayé rẹ̀ máa ní ipa tí ó ṣe pàtàkì nípa ìyè ayérayé? Ìfọkànsí ọlọ́jọ́ méje yìí, tí a kọ láti ọwọ́ Christine Caine yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Ọlọ́run ṣe rí o, tí ó yàn ọ́, àti bí Ó ṣe rán ọ láti rí àwọn ẹlòmíràn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wón le rí ara wọn bí Ọlọ́run ṣe rí wọn- pẹ̀lú ìríran 20/20.
More