20/20: A Ti Rí. A Ti Yàn. A Ti Rán. Nípasẹ̀ Christine Caine Àpẹrẹ

20/20: Seen. Chosen. Sent. By Christine Caine

Ọjọ́ 7 nínú 7

A TI RÍ WA, YÀN WÁ, A SÌ TI RÁN WA LỌ. Ẹ JẸ́ KÁ LỌ!

Ẹ lọ sí gbogbo ayé kí ẹ sì máa wàásù ìhìnrere fún gbogbo ẹ̀dá. -Mark 16:15 BM

Dídàgbà bíi àkóbí ọmọbìnrin nínú ìran Gíríkì àkọ́kọ́ túmọ̀ sí pé mo dàgbà nínú pádi Gíríkì. Nítorípé àwọn òbí mi—àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wọn—wá sí orílẹ́-èdè Australia láìní ẹnikẹ́ni láti d'ara dé àyàfi ara wọn, wọ́n lúgọ pọ̀, ní ìgbàgbọ́ pé ààbò ńbẹ nínú ọ̀pọ̀. Nítorínáà, ní gbogbo ìgbà èwe mi, àwọn òbí mi, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò wọn pẹ̀lú ọ̀rẹ́ àti aládùgbò wọn jùmọ̀ k'ẹgbẹ papọ̀ bíi enipé ẹ̀rù ń bà wọ́n nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ bí wọ́n bá d'ásẹ̀ jáde. Eléyìí kìí sìí ṣe nítorí wọn kò le sọ Gẹ̀ẹ́sì o. Àwọn òbí mi ń sọ èdè márùn-ún: Lárúbáwá, Gíríkì, Faransé, Ìtàló àti Gẹ̀ẹ́sì. Wọ́n jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé! Wọ́n mọ bí a ṣe ń ṣe ní àwùjọ ìgbàlódé, ṣùgbọ́n wọ́n yàn láti gbé nínú ayé kótópó tí wọ́n dá fún ara wọn.

L'ọ́pọ̀ ìgbà, àwa Krìstíẹ́nì a máa hùwà bákannáà. À ń dá gbé nínú pádi Krìstíẹ́nì wa, nínú àwùjọ́ Krìstíẹ́nì, láàrin àwọn àkọ́jọpọ̀ ọ̀rẹ́ Krìstíẹ́nì, a sì dúró síbẹ̀. Kódà, a tún ń sápamọ́ síbẹ̀, nínú ẹ̀yà àṣà Krìstíẹ́nì àdábọwọ́ ara wa. À ṣ'ẹ̀dá ohun tí a l'érò pé ó jẹ́ ọ̀run ní ayé, a sì d'áwọ́ kọ́ n'írètí pé ohun gbogbo yíó lọ déédéé títí ìgbà tí a ó kúrò l'ókè eèpẹ̀. Nígbà t'ó jẹ́ pé Jésù ti rí wa, yàn wa àti RÁN WA LỌ SÍNÚ AYÈ láti ní àwọn ọmọ-ẹ̀hìn. A kò lè fi òfin Rẹ̀ tó tóbi jù ṣe àkọ́kọ́ l'áyé wa bíkòṣe pé a kọ̀ jáde kúrò nínú ibi tí a f'orí pamọ́ sí.

Jésù kò gbà wá là kí á ba lè ṣẹ̀dá àṣà ẹ̀yà Krìstíẹ́nì. Láti kọ̀ láti pàdé àwọn ènìyàn tí wọ́n kò rí bíi tiwa, tí kò hùwà bíi tiwa, ronú bíi tiwa, tàbí gbàgbọ́ bíi tiwa. Kò gbà wá là láti f'ara pamọ́ fún ayé, y'ẹra fún ayé, yan ayé l'ódì, bẹ̀rù ayé, kórira ayé, dá ayé l'oni tàbí ṣ'èdájọ́ ayé. Ó dììídì rán wa lọ s'ínú ayé láti... ní àwọn ọmọ-ẹ̀hìn...fún wa láti fẹ̀ràn ayé tó tá àti kí a fẹ́ẹ p'ẹ̀lẹ́sọ̀ àti t'ọkànt'ọkàn.

“Ẹ lọ sí gbogbo ayé kí ẹ sì máa wàásù ìhìnrere fún gbogbo ẹ̀dá.”

Ọ̀rọ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ẹsẹ yìí? LỌ.

Lọ sí gbogbo ayé.

Lọ kí o lọ ní ìfẹ́ àwọn tí ó nù.

Lọ, kí òye àwọn tí ọ nù yé ọ.

Lọ kí o ní ìkáàánú fún àwọn tí ó nù.

Lọ kí o sọ fún àwọn tí o nù nípa Jésù.

Lọ kí o kó ọmọ-ẹ̀hìn jọ.

PRAYER

Baba Ọ̀run, O ṣeun nítorípé O rí mi, O yàn mí, O sì rán mí lọ. Ràn mí lọ́wọ́ láti ní okun àti ìgboyà láti lọ sí ibití O bá ní kí lọ àti láti ṣe ohun tí O pè mí láti ṣe. Àmín.

Fún irú èyí síi, kàn sí www.christinecaine.com/2020study

Àdàkọ láti inú 20/20: A Ríi.A Yàn án.A Rán an lọ l'átọwọ́ Christine Caine. Copyright © 2019 by Christine Caine. Àtúntẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀nda Lifeway Women. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà n'íkàwọ́ọ́.

Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

20/20: Seen. Chosen. Sent. By Christine Caine

Ǹjẹ́ o le fi ojú inú wòó bí yíò ṣe rí kí Ọlọ́run rí ọ lọ́nà tí ó jẹ́ wípé ìwo gan ò lè má ṣe aláìrì àwọn ẹlòmíràn? Ṣé o le fi ojú inú wòó wípé lójoojúmọ́, kí ìgbésí ayé rẹ̀ máa ní ipa tí ó ṣe pàtàkì nípa ìyè ayérayé? Ìfọkànsí ọlọ́jọ́ méje yìí, tí a kọ láti ọwọ́ Christine Caine yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Ọlọ́run ṣe rí o, tí ó yàn ọ́, àti bí Ó ṣe rán ọ láti rí àwọn ẹlòmíràn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wón le rí ara wọn bí Ọlọ́run ṣe rí wọn- pẹ̀lú ìríran 20/20.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christine Caine - A21, Propel, CCM fún ìpèsè ètò yìí. Tó bá fẹ́ mọ̀ sí, lọ sí http://www.christinecaine.com/2020study